Joh 16:5-7
Joh 16:5-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Ṣùgbọ́n nísinsin yìí èmi ń lọ sọ́dọ̀ ẹni tí ó rán mi; kò sì sí ẹnìkan nínú yín tí ó bi mí lérè pé, ‘Níbo ni ìwọ ń lọ?’ Ṣùgbọ́n nítorí mo sọ nǹkan wọ̀nyí fún yín, ìbìnújẹ́ kún ọkàn yín. Ṣùgbọ́n òtítọ́ ni èmi ń sọ fún yín; àǹfààní ni yóò jẹ́ fún yín bí èmi bá lọ: nítorí bí èmi kò bá lọ, Olùtùnú kì yóò tọ̀ yín wá; ṣùgbọ́n bí mo bá lọ, èmi ó rán an sí yín.
Joh 16:5-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn nisisiyi emi nlọ sọdọ ẹniti o rán mi; kò si si ẹnikan ninu nyin ti o bi mi lẽre pe, Nibo ni iwọ nlọ? Ṣugbọn nitori mo sọ nkan wọnyi fun nyin, ibinujẹ kún ọkàn nyin. Ṣugbọn otitọ li emi nsọ fun nyin; anfani ni yio jẹ fun nyin bi emi ba lọ: nitori bi emi kò ba lọ, Olutunu kì yio tọ̀ nyin wá: ṣugbọn bi mo ba lọ, emi o rán a si nyin.
Joh 16:5-7 Yoruba Bible (YCE)
Ṣugbọn nisinsinyii mò ń lọ sọ́dọ̀ ẹni tí ó rán mi níṣẹ́. Ẹnìkankan ninu yín kò wí pé, ‘Níbo ni ò ń lọ?’ Ṣugbọn ìbànújẹ́ kún ọkàn yín nítorí mo ti sọ nǹkan wọnyi fun yín. Sibẹ òtítọ́ ni mo sọ fun yín. Ó sàn fun yín pé kí n lọ. Nítorí bí n kò bá lọ, Alátìlẹ́yìn tí mo wí kò ní wá sọ́dọ̀ yín. Ṣugbọn bí mo bá lọ, n óo rán an si yín.