Joh 16

16
1 NKAN wọnyi ni mo ti sọ fun nyin, ki a má ba mu nyin kọsẹ̀.
2 Nwọn o yọ nyin kuro ninu sinagogu: ani, akokò mbọ̀, ti ẹnikẹni ti o ba pa nyin, yio rò pe on nṣe ìsin fun Ọlọrun.
3 Nkan wọnyi ni nwọn o si ṣe, nitoriti nwọn kò mọ̀ Baba, nwọn kò si mọ̀ mi.
4 Ṣugbọn nkan wọnyi ni mo ti sọ fun nyin, pe nigbati wakati wọn ba de, ki ẹ le ranti wọn pe mo ti wi fun nyin. Ṣugbọn emi ko sọ nkan wọnyi fun nyin lati ipilẹṣẹ wá, nitoriti mo wà pẹlu nyin.
Iṣẹ́ Ẹ̀mí Mímọ́
5 Ṣugbọn nisisiyi emi nlọ sọdọ ẹniti o rán mi; kò si si ẹnikan ninu nyin ti o bi mi lẽre pe, Nibo ni iwọ nlọ?
6 Ṣugbọn nitori mo sọ nkan wọnyi fun nyin, ibinujẹ kún ọkàn nyin.
7 Ṣugbọn otitọ li emi nsọ fun nyin; anfani ni yio jẹ fun nyin bi emi ba lọ: nitori bi emi kò ba lọ, Olutunu kì yio tọ̀ nyin wá: ṣugbọn bi mo ba lọ, emi o rán a si nyin.
8 Nigbati on ba si de, yio fi òye yé araiye niti ẹ̀ṣẹ, ati niti ododo, ati niti idajọ:
9 Niti ẹ̀ṣẹ, nitoriti nwọn kò gbà mi gbọ́;
10 Niti ododo, nitoriti emi nlọ sọdọ Baba, ẹnyin kò si ri mi mọ́;
11 Niti idajọ, nitoriti a ti ṣe idajọ alade aiye yi.
12 Mo ni ohun pipọ lati sọ fun nyin pẹlu, ṣugbọn ẹ kò le gbà wọn nisisiyi.
13 Ṣugbọn nigbati on, ani Ẹmí otitọ ni ba de, yio tọ́ nyin si ọ̀na otitọ gbogbo; nitori kì yio sọ̀ ti ara rẹ̀; ṣugbọn ohunkohun ti o ba gbọ́, on ni yio ma sọ: yio si sọ ohun ti mbọ̀ fun nyin.
14 On o ma yìn mi logo: nitoriti yio gbà ninu ti emi, yio si ma sọ ọ fun nyin.
15 Ohun gbogbo ti Baba ni temi ni: nitori eyi ni mo ṣe wipe, on ó gbà ninu temi, yio si sọ ọ fun nyin.
Ìbànújẹ́ Yóo Di Ayọ̀
16 Nigba diẹ, ẹnyin kì o si ri mi: ati nigba diẹ ẹ̀wẹ, ẹ ó si ri mi, nitoriti emi nlọ sọdọ Baba.
17Nitorina omiran ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ mba ara wọn sọ pe, Kili eyi ti o nwi fun wa yi, Nigba diẹ, ẹnyin kì o si ri mi: ati nigba diẹ ẹ̀wẹ, ẹnyin o si ri mi: ati, Nitoriti emi nlọ sọdọ Baba?
18Nitorina nwọn wipe, Kili eyi ti o wi yi, Nigba diẹ? awa kò mọ̀ ohun ti o wi.
19Jesu sá ti mọ̀ pe, nwọn nfẹ lati bi on lẽre, o si wi fun wọn pe, Ẹnyin mbi ara nyin lẽre niti eyi ti mo wipe, Nigba diẹ, ẹnyin kì o si ri mi: ati nigba diẹ ẹ̀wẹ, ẹnyin o si ri mi?
20 Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin pe, Ẹnyin o ma sọkun ẹ o si ma pohùnrere ẹkún, ṣugbọn awọn araiye yio ma yọ̀: inu nyin yio si bajẹ, ṣugbọn ibinujẹ nyin li yio si di ayọ̀.
21 Nigbati obinrin bá nrọbi, a ni ibinujẹ, nitoriti wakati rẹ̀ de: ṣugbọn nigbati o ba ti bí ọmọ na tan, on kì si iranti irora na mọ́, fun ayọ̀ nitori a bí enia si aiye.
22 Nitorina ẹnyin ni ibinujẹ nisisiyi: ṣugbọn emi o tún ri nyin, ọkàn nyin yio si yọ̀, kò si si ẹniti yio gbà ayọ̀ nyin lọwọ nyin.
23 Ati ni ijọ na ẹnyin kì o bi mi lẽre ohunkohun. Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ohunkohun ti ẹnyin ba bère lọwọ Baba li orukọ mi, on o fifun nyin.
24 Titi di isisiyi ẹ kò ti ibère ohunkohun li orukọ mi: ẹ bère, ẹ o si ri gbà, ki ayọ̀ nyin ki o le kún.
Jesu Ti Ṣẹgun Ayé
25 Nkan wọnyi ni mo ti fi owe sọ fun nyin: ṣugbọn akokò de, nigbati emi kì yio fi owe ba nyin sọrọ mọ́, ṣugbọn emi o sọ ti Baba fun nyin gbangba.
26 Li ọjọ na ẹnyin o bère li orukọ mi: emi kò si wi fun nyin pe, emi o bère lọwọ Baba fun nyin:
27 Nitoriti Baba tikararẹ̀ fẹran nyin, nitoriti ẹnyin ti fẹràn mi, ẹ si ti gbagbọ́ pe, lọdọ Ọlọrun li emi ti jade wá.
28 Mo ti ọdọ Baba jade wá, mo si wá si aiye: ẹ̀wẹ, mo fi aiye silẹ, mo si nlọ sọdọ Baba.
29Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wi fun u pe, Wo o, nigbayi ni iwọ nsọ̀rọ̀ gbangba, iwọ kò si sọ ohunkohun li owe.
30Nigbayi li awa mọ̀ pe, iwọ mọ̀ ohun gbogbo, iwọ kò ni ki a bi ọ lẽre: nipa eyi li awa gbagbọ́ pe, lọdọ Ọlọrun ni iwọ ti jade wá.
31Jesu da wọn lohùn pe, Ẹnyin gbagbọ́ wayi?
32 Kiyesi i, wakati mbọ̀, ani o de tan nisisiyi, ti a o fọ́n nyin ká kiri, olukuluku si ile rẹ̀; ẹ ó si fi emi nikan silẹ: ṣugbọn kì yio si ṣe emi nikan, nitoriti Baba mbẹ pẹlu mi.
33 Nkan wọnyi ni mo ti sọ fun nyin tẹlẹ̀, ki ẹnyin ki o le ni alafia ninu mi. Ninu aiye, ẹnyin o ni ipọnju; ṣugbọn ẹ tújuka; mo ti ṣẹgun aiye.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Joh 16: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa