Joh 16:1-33

Joh 16:1-33 Bibeli Mimọ (YBCV)

NKAN wọnyi ni mo ti sọ fun nyin, ki a má ba mu nyin kọsẹ̀. Nwọn o yọ nyin kuro ninu sinagogu: ani, akokò mbọ̀, ti ẹnikẹni ti o ba pa nyin, yio rò pe on nṣe ìsin fun Ọlọrun. Nkan wọnyi ni nwọn o si ṣe, nitoriti nwọn kò mọ̀ Baba, nwọn kò si mọ̀ mi. Ṣugbọn nkan wọnyi ni mo ti sọ fun nyin, pe nigbati wakati wọn ba de, ki ẹ le ranti wọn pe mo ti wi fun nyin. Ṣugbọn emi ko sọ nkan wọnyi fun nyin lati ipilẹṣẹ wá, nitoriti mo wà pẹlu nyin. Ṣugbọn nisisiyi emi nlọ sọdọ ẹniti o rán mi; kò si si ẹnikan ninu nyin ti o bi mi lẽre pe, Nibo ni iwọ nlọ? Ṣugbọn nitori mo sọ nkan wọnyi fun nyin, ibinujẹ kún ọkàn nyin. Ṣugbọn otitọ li emi nsọ fun nyin; anfani ni yio jẹ fun nyin bi emi ba lọ: nitori bi emi kò ba lọ, Olutunu kì yio tọ̀ nyin wá: ṣugbọn bi mo ba lọ, emi o rán a si nyin. Nigbati on ba si de, yio fi òye yé araiye niti ẹ̀ṣẹ, ati niti ododo, ati niti idajọ: Niti ẹ̀ṣẹ, nitoriti nwọn kò gbà mi gbọ́; Niti ododo, nitoriti emi nlọ sọdọ Baba, ẹnyin kò si ri mi mọ́; Niti idajọ, nitoriti a ti ṣe idajọ alade aiye yi. Mo ni ohun pipọ lati sọ fun nyin pẹlu, ṣugbọn ẹ kò le gbà wọn nisisiyi. Ṣugbọn nigbati on, ani Ẹmí otitọ ni ba de, yio tọ́ nyin si ọ̀na otitọ gbogbo; nitori kì yio sọ̀ ti ara rẹ̀; ṣugbọn ohunkohun ti o ba gbọ́, on ni yio ma sọ: yio si sọ ohun ti mbọ̀ fun nyin. On o ma yìn mi logo: nitoriti yio gbà ninu ti emi, yio si ma sọ ọ fun nyin. Ohun gbogbo ti Baba ni temi ni: nitori eyi ni mo ṣe wipe, on ó gbà ninu temi, yio si sọ ọ fun nyin. Nigba diẹ, ẹnyin kì o si ri mi: ati nigba diẹ ẹ̀wẹ, ẹ ó si ri mi, nitoriti emi nlọ sọdọ Baba. Nitorina omiran ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ mba ara wọn sọ pe, Kili eyi ti o nwi fun wa yi, Nigba diẹ, ẹnyin kì o si ri mi: ati nigba diẹ ẹ̀wẹ, ẹnyin o si ri mi: ati, Nitoriti emi nlọ sọdọ Baba? Nitorina nwọn wipe, Kili eyi ti o wi yi, Nigba diẹ? awa kò mọ̀ ohun ti o wi. Jesu sá ti mọ̀ pe, nwọn nfẹ lati bi on lẽre, o si wi fun wọn pe, Ẹnyin mbi ara nyin lẽre niti eyi ti mo wipe, Nigba diẹ, ẹnyin kì o si ri mi: ati nigba diẹ ẹ̀wẹ, ẹnyin o si ri mi? Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin pe, Ẹnyin o ma sọkun ẹ o si ma pohùnrere ẹkún, ṣugbọn awọn araiye yio ma yọ̀: inu nyin yio si bajẹ, ṣugbọn ibinujẹ nyin li yio si di ayọ̀. Nigbati obinrin bá nrọbi, a ni ibinujẹ, nitoriti wakati rẹ̀ de: ṣugbọn nigbati o ba ti bí ọmọ na tan, on kì si iranti irora na mọ́, fun ayọ̀ nitori a bí enia si aiye. Nitorina ẹnyin ni ibinujẹ nisisiyi: ṣugbọn emi o tún ri nyin, ọkàn nyin yio si yọ̀, kò si si ẹniti yio gbà ayọ̀ nyin lọwọ nyin. Ati ni ijọ na ẹnyin kì o bi mi lẽre ohunkohun. Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ohunkohun ti ẹnyin ba bère lọwọ Baba li orukọ mi, on o fifun nyin. Titi di isisiyi ẹ kò ti ibère ohunkohun li orukọ mi: ẹ bère, ẹ o si ri gbà, ki ayọ̀ nyin ki o le kún. Nkan wọnyi ni mo ti fi owe sọ fun nyin: ṣugbọn akokò de, nigbati emi kì yio fi owe ba nyin sọrọ mọ́, ṣugbọn emi o sọ ti Baba fun nyin gbangba. Li ọjọ na ẹnyin o bère li orukọ mi: emi kò si wi fun nyin pe, emi o bère lọwọ Baba fun nyin: Nitoriti Baba tikararẹ̀ fẹran nyin, nitoriti ẹnyin ti fẹràn mi, ẹ si ti gbagbọ́ pe, lọdọ Ọlọrun li emi ti jade wá. Mo ti ọdọ Baba jade wá, mo si wá si aiye: ẹ̀wẹ, mo fi aiye silẹ, mo si nlọ sọdọ Baba. Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wi fun u pe, Wo o, nigbayi ni iwọ nsọ̀rọ̀ gbangba, iwọ kò si sọ ohunkohun li owe. Nigbayi li awa mọ̀ pe, iwọ mọ̀ ohun gbogbo, iwọ kò ni ki a bi ọ lẽre: nipa eyi li awa gbagbọ́ pe, lọdọ Ọlọrun ni iwọ ti jade wá. Jesu da wọn lohùn pe, Ẹnyin gbagbọ́ wayi? Kiyesi i, wakati mbọ̀, ani o de tan nisisiyi, ti a o fọ́n nyin ká kiri, olukuluku si ile rẹ̀; ẹ ó si fi emi nikan silẹ: ṣugbọn kì yio si ṣe emi nikan, nitoriti Baba mbẹ pẹlu mi. Nkan wọnyi ni mo ti sọ fun nyin tẹlẹ̀, ki ẹnyin ki o le ni alafia ninu mi. Ninu aiye, ẹnyin o ni ipọnju; ṣugbọn ẹ tújuka; mo ti ṣẹgun aiye.

Joh 16:1-33 Yoruba Bible (YCE)

“Mo sọ gbogbo nǹkan yìí fun yín kí igbagbọ yín má baà yẹ̀. Wọn yóo le yín jáde kúrò ninu ilé ìpàdé wọn. Èyí nìkan kọ́, àkókò ń bọ̀ tí ó jẹ́ pé ẹni tí ó bá ṣe ikú pa yín yóo rò pé òun ń ṣe iṣẹ́ ìsìn sí Ọlọrun ni. Wọn yóo ṣe nǹkan wọnyi nítorí wọn kò mọ Baba, wọn kò sì mọ̀ mí. Ṣugbọn mo ti sọ gbogbo nǹkan wọnyi fun yín, kí ẹ lè ranti pé mo ti sọ fun yín tẹ́lẹ̀, nígbà tí ó bá yá, tí wọn bá ń ṣe é si yín. “N kò sọ àwọn nǹkan wọnyi fun yín láti ìbẹ̀rẹ̀ nítorí mo wà lọ́dọ̀ yín. Ṣugbọn nisinsinyii mò ń lọ sọ́dọ̀ ẹni tí ó rán mi níṣẹ́. Ẹnìkankan ninu yín kò wí pé, ‘Níbo ni ò ń lọ?’ Ṣugbọn ìbànújẹ́ kún ọkàn yín nítorí mo ti sọ nǹkan wọnyi fun yín. Sibẹ òtítọ́ ni mo sọ fun yín. Ó sàn fun yín pé kí n lọ. Nítorí bí n kò bá lọ, Alátìlẹ́yìn tí mo wí kò ní wá sọ́dọ̀ yín. Ṣugbọn bí mo bá lọ, n óo rán an si yín. Nígbà tí ó bá dé, yóo fi han aráyé pé wọ́n ti ṣìnà ninu èrò wọn nípa ẹ̀ṣẹ̀, ati nípa òdodo, ati nípa ìdájọ́ Ọlọrun. Wọ́n ti ṣìnà ninu èrò wọn nípa ẹ̀ṣẹ̀ nítorí pé wọn kò gbà mí gbọ́. Wọ́n ṣìnà ní ti òdodo nítorí mò ń lọ sọ́dọ̀ Baba, ẹ kò sì ní rí mi mọ́. Wọ́n ṣìnà ní ti ìdájọ́ nítorí pé Ọlọrun ti dá aláṣẹ ayé yìí lẹ́bi. “Ọ̀rọ̀ tí mo tún fẹ́ ba yín sọ pọ̀, ṣugbọn ọkàn yin kò lè gbà á ní àkókò yìí. Ṣugbọn nígbà tí Ẹ̀mí òtítọ́ tí mo wí bá dé, yóo tọ yín sí ọ̀nà òtítọ́ gbogbo. Nítorí kò ní sọ ọ̀rọ̀ ti ara rẹ̀; gbogbo ohun tí ó bá gbọ́ ni yóo sọ. Yóo sọ àwọn ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ fun yín. Yóo fi ògo mi hàn nítorí láti ọ̀dọ̀ mi ni yóo ti gba àwọn ohun tí yóo sọ fun yín. Tèmi ni ohun gbogbo tí Baba ní. Ìdí nìyí ti mo ṣe sọ pé ohun tí ó bá gbà láti ọ̀dọ̀ mi ni yóo sọ fun yín. “Láìpẹ́ ẹ kò ní rí mi mọ́. Lẹ́yìn náà, láìpẹ́ ẹ óo sì tún rí mi.” Àwọn kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí sọ láàrin ara wọn pé, “Kí ni ìtumọ̀ ohun tí ó wí fún wa yìí, ‘Láìpẹ́ ẹ kò ní rí mi mọ́. Lẹ́yìn náà, láìpẹ́ ẹ óo sì tún rí mi?’ Kí tún ni ìtumọ̀, ‘Nítorí mò ń lọ sọ́dọ̀ Baba?’ ” Wọ́n tún ń sọ pé, “Kí ni ìtumọ̀ ‘Láìpẹ́’ tí ó ń wí yìí? Ohun tí ó ń sọ kò yé wa.” Jesu mọ̀ pé wọ́n ń fẹ́ bi òun léèrè ọ̀rọ̀ yìí. Ó wá wí fún wọn pé, “Nítorí èyí ni ẹ ṣe ń bá ara yín jiyàn, nítorí mo sọ pé, ‘Laìpẹ́ ẹ kò ní rí mi mọ́,’ ati pé, ‘Lẹ́yìn náà, láìpẹ́ ẹ óo tún rí mi?’ Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé ẹ óo sunkún, ẹ óo ṣọ̀fọ̀, ṣugbọn inú aráyé yóo dùn. Ẹ óo dààmú ṣugbọn ìdààmú yín yóo di ayọ̀. Nígbà tí aboyún bá ń rọbí, ó gbọdọ̀ jẹ ìrora, nítorí àkókò ìkúnlẹ̀ rẹ̀ tó. Ṣugbọn nígbà tí ó bà bímọ tán, kò ní ranti gbogbo ìrora rẹ̀ mọ́, nítorí ayọ̀ pé ó bí ọmọ kan sinu ayé. Bákan náà ni: inú yín bàjẹ́ nisinsinyii, ṣugbọn n óo tún ri yín, inú yín yóo wá dùn, ẹnikẹ́ni kò ní lè mú ayọ̀ yín kúrò lọ́kàn yín. “Ní ọjọ́ náà, ẹ kò ní bi mí léèrè ohunkohun. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé ohunkohun tí ẹ bá bèèrè lọ́dọ̀ Baba ní orúkọ mi, yóo fun yín. Ẹ kò ì tíì bèèrè ohunkohun ní orúkọ mi títí di ìsinsìnyìí. Ẹ bèèrè, ẹ óo sì rí gbà, kí ẹ lè ní ayọ̀ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. “Bí òwe bí òwe ni mo ti ń sọ àwọn nǹkan yìí fun yín. Ṣugbọn àkókò ń bọ̀ nígbà tí n kò ní fi òwe ba yín sọ̀rọ̀ mọ́, kedere ni n óo máa sọ̀rọ̀ nípa Baba fun yín nígbà náà. Ní ọjọ́ náà, ẹ óo bèèrè nǹkan ní orúkọ mi, n kò ní wí fun yín pé èmi yóo ba yín bẹ Baba. Nítorí Baba fúnrarẹ̀ fẹ́ràn yín nítorí pé ẹ̀yin náà fẹ́ràn mi, ẹ ti gbàgbọ́ pé láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni mo ti wá. Mo wá láti ọ̀dọ̀ Baba, mo jáde wá sinu ayé, n óo tún fi ayé sílẹ̀ láti lọ sọ́dọ̀ Baba.” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ pé, “Kedere ni ò ń sọ̀rọ̀ nisinsinyii, o kò sọ̀rọ̀ lówe lówe mọ́. A wá mọ̀ wàyí pé o mọ ohun gbogbo, kò ṣẹ̀ṣẹ̀ di ìgbà tí eniyan bá bi ọ́ kí o tó dáhùn ọ̀rọ̀. Nítorí náà, a gbàgbọ́ pé láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni o ti wá.” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ wá gbàgbọ́ nisinsinyii? Àkókò ń bọ̀, ó tilẹ̀ ti dé, nígbà tí ẹ óo túká, tí olukuluku yín yóo lọ sí ilé rẹ̀, tí ẹ óo fi èmi nìkan sílẹ̀. Ṣugbọn kò ní jẹ́ èmi nìkan nítorí Baba wà pẹlu mi. Mo ti sọ nǹkan wọnyi fun yín kí ẹ lè ní alaafia nípa wíwà ninu mi. Ẹ óo ní ìpọ́njú ninu ayé, ṣugbọn ẹ ṣe ara gírí, mo ti ṣẹgun ayé.”

Joh 16:1-33 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

“Nǹkan wọ̀nyí ni mo ti sọ fún yín, kí a má ba à mú yín yapa kúrò. Wọ́n ó yọ yín kúrò nínú Sinagọgu: àní, àkókò ń bọ̀, tí ẹnikẹ́ni tí ó bá pa yín, yóò rò pé òun ń ṣe ìsìn fún Ọlọ́run. Nǹkan wọ̀nyí ni wọ́n ó sì ṣe, nítorí tí wọn kò mọ Baba, wọn kò sì mọ̀ mí. Ṣùgbọ́n nǹkan wọ̀nyí ni mo ti sọ fún yín, pé nígbà tí wákàtí wọn bá dé, kí ẹ lè rántí wọn pé mo ti wí fún yín. Ṣùgbọ́n èmi kò sọ nǹkan wọ̀nyí fún yín láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ wá, nítorí tí mo wà pẹ̀lú yín. “Ṣùgbọ́n nísinsin yìí èmi ń lọ sọ́dọ̀ ẹni tí ó rán mi; kò sì sí ẹnìkan nínú yín tí ó bi mí lérè pé, ‘Níbo ni ìwọ ń lọ?’ Ṣùgbọ́n nítorí mo sọ nǹkan wọ̀nyí fún yín, ìbìnújẹ́ kún ọkàn yín. Ṣùgbọ́n òtítọ́ ni èmi ń sọ fún yín; àǹfààní ni yóò jẹ́ fún yín bí èmi bá lọ: nítorí bí èmi kò bá lọ, Olùtùnú kì yóò tọ̀ yín wá; ṣùgbọ́n bí mo bá lọ, èmi ó rán an sí yín. Nígbà tí òun bá sì dé, yóò fi òye yé aráyé ní ti ẹ̀ṣẹ̀, àti ní ti òdodo, àti ní ti ìdájọ́: ní ti ẹ̀ṣẹ̀, nítorí tí wọn kò gbà mí gbọ́; Ní ti òdodo, nítorí tí èmi ń lọ sọ́dọ̀ Baba, ẹ̀yin kò sì mọ̀ mí; Ní ti ìdájọ́, nítorí tí a ti ṣe ìdájọ́ ọmọ-aládé ayé yìí. “Mo ní ohun púpọ̀ láti sọ fún yín pẹ̀lú, ṣùgbọ́n ẹ kò lè gbà wọ́n nísinsin yìí. Ṣùgbọ́n nígbà tí òun, àní Ẹ̀mí òtítọ́ náà bá dé, yóò tọ́ yín sí ọ̀nà òtítọ́ gbogbo; nítorí kì yóò sọ ti ara rẹ̀; ṣùgbọ́n ohunkóhun tí ó bá gbọ́, òun ni yóò máa sọ: yóò sì sọ ohun tí ń bọ̀ fún yín. Òun ó máa yìn mí lógo: nítorí tí yóò gbà nínú ti èmi, yóò sì máa sọ ọ́ fún yín. Ohun gbogbo tí Baba ní tèmi ni: nítorí èyí ni mo ṣe wí pé, òun ó gba nínú tèmi, yóò sì sọ ọ́ fún yín. “Nígbà díẹ̀, ẹ̀yin kì ó sì rí mi: àti nígbà díẹ̀ si, ẹ ó sì rí mi, nítorí tí èmi ń lọ sọ́dọ̀ Baba.” Nítorí náà díẹ̀ nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ń bá ara wọn sọ pé, “Kín ni èyí tí o wí fún wa yìí, nígbà díẹ̀, ẹ̀yin ó sì rí mi: àti nígbà díẹ̀ ẹ̀wẹ̀, ẹ̀yin kì yóò rí mi: àti, nítorí tí èmi ń lọ sọ́dọ̀ Baba?” Nítorí náà wọ́n wí pé, kín ni, nígbà díẹ̀? Àwa kò mọ̀ ohun tí ó wí. Jesu sá à ti mọ̀ pé, wọ́n ń fẹ́ láti bi òun léèrè, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ń bi ara yín léèrè ní ti èyí tí mo wí pé, nígbà díẹ̀, ẹ̀yin kì yóò sì rí mi: àti nígbà díẹ̀ si, ẹ̀yin ó sì rí mi? Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín pé, ẹ̀yin yóò máa sọkún ẹ ó sì máa pohùnréré ẹkún, ṣùgbọ́n àwọn aráyé yóò máa yọ̀: ṣùgbọ́n, ìbànújẹ́ yín yóò di ayọ̀. Nígbà tí obìnrin bá ń rọbí, a ní ìbìnújẹ́, nítorí tí wákàtí rẹ̀ dé: ṣùgbọ́n nígbà tí ó bá ti bí ọmọ náà tán, òun kì í sì í rántí ìrora náà mọ́, fún ayọ̀ nítorí a bí ènìyàn sí ayé. Nítorí náà ẹ̀yin ní ìbànújẹ́ nísinsin yìí: ṣùgbọ́n èmi ó tún rí yín, ọkàn yín yóò sì yọ̀, kò sì sí ẹni tí yóò gba ayọ̀ yín lọ́wọ́ yín. Àti ní ọjọ́ náà ẹ̀yin kì ó bi mí lérè ohunkóhun. Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ohunkóhun tí ẹ̀yin bá béèrè lọ́wọ́ Baba ní orúkọ mi, òhun ó fi fún yín. Títí di ìsinsin yìí ẹ kò tí ì béèrè ohunkóhun ní orúkọ mi: ẹ béèrè, ẹ ó sì rí gbà, kí ayọ̀ yín kí ó lè kún. “Nǹkan wọ̀nyí ni mo fi òwe sọ fún yín: ṣùgbọ́n àkókò dé, nígbà tí èmi kì yóò fi òwe bá yín sọ̀rọ̀ mọ́, ṣùgbọ́n èmi ó sọ nípa ti Baba fún yín gbangba. Ní ọjọ́ náà, ẹ̀yin ó béèrè ní orúkọ mi: èmi kò sì wí fún yín pé, èmi ó béèrè lọ́wọ́ Baba fún yín: Nítorí tí Baba tìkára rẹ̀ fẹ́ràn yín, nítorí tí ẹ̀yin ti fẹ́ràn mi, ẹ sì ti gbàgbọ́ pé, lọ́dọ̀ Ọlọ́run ni èmi ti jáde wá. Mo ti ọ̀dọ̀ Baba jáde wá, mo sì wá sí ayé: àti nísinsin yìí mo fi ayé sílẹ̀, mo sì lọ sọ́dọ̀ Baba.” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wí fún un pé, “Wò ó, nígbà yìí ni ìwọ ń sọ̀rọ̀ gbangba, ìwọ kò sì sọ ohunkóhun ní òwe. Nígbà yìí ni àwa mọ̀ pé, ìwọ mọ̀ ohun gbogbo, ìwọ kò ní kí a bi ọ́ léèrè: nípa èyí ni àwa gbàgbọ́ pé, lọ́dọ̀ Ọlọ́run ni ìwọ ti jáde wá.” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin gbàgbọ́ wàyí? Kíyèsi i, wákàtí ń bọ̀, àní ó dé tan nísinsin yìí, tí a ó fọ́n yín ká kiri, olúkúlùkù sí ilé rẹ̀; ẹ ó sì fi èmi nìkan sílẹ̀: ṣùgbọ́n kì yóò sì ṣe èmi nìkan, nítorí tí Baba ń bẹ pẹ̀lú mi. “Nǹkan wọ̀nyí ni mo ti sọ fún yín tẹ́lẹ̀, kí ẹ̀yin kí ó lè ní àlàáfíà nínú mi. Nínú ayé, ẹ̀yin ó ní ìpọ́njú; ṣùgbọ́n ẹ tújúká; mo ti ṣẹ́gun ayé.”