Joh 15:16-17
Joh 15:16-17 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ki iṣe ẹnyin li o yàn mi, ṣugbọn emi li o yàn nyin, mo si fi nyin sipo, ki ẹnyin ki o le lọ, ki ẹ si so eso, ati ki eso nyin le duro; ki ohunkohun ti ẹ ba bère lọwọ Baba li orukọ mi, ki o le fi i fun nyin. Nkan wọnyi ni mo palaṣẹ fun nyin pe, ki ẹnyin ki o fẹran ara nyin.
Pín
Kà Joh 15Joh 15:16-17 Yoruba Bible (YCE)
Kì í ṣe ẹ̀yin ni ẹ yàn mí. Èmi ni mo yàn yín, tí mo ran yín pé kí ẹ lọ máa so èso tí kò ní bàjẹ́, kí Baba lè fun yín ní ohunkohun tí ẹ bá bèèrè ní orúkọ mi. Àṣẹ yìí ni mo pa fun yín: ẹ fẹ́ràn ara yín.
Pín
Kà Joh 15Joh 15:16-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Kì í ṣe ẹ̀yin ni ó yàn mí, ṣùgbọ́n èmi ni ó yàn yín, mo sì fi yín sípò, kí ẹ̀yin kí ó lè lọ, kí ẹ sì so èso, àti kí èso yín lè dúró; kí ohunkóhun tí ẹ bá béèrè lọ́wọ́ Baba ní orúkọ mi, kí ó lè fi í fún yín. Nǹkan wọ̀nyí ni mo pàṣẹ fún yín pé, kí ẹ̀yin kí ó fẹ́ràn ara yín.
Pín
Kà Joh 15