Joh 13:36-37
Joh 13:36-37 Bibeli Mimọ (YBCV)
Simoni Peteru wi fun u pe, Oluwa, nibo ni iwọ nlọ? Jesu da a lohùn pe, Nibiti emi nlọ, iwọ ki ó le tọ̀ mi nisisiyi; ṣugbọn iwọ yio tọ̀ mi nikẹhin. Peteru wi fun u pe, Oluwa, ẽṣe ti emi ko fi le tọ̀ ọ nisisiyi? Emi o fi ẹmí mi lelẹ nitori rẹ.
Joh 13:36-37 Yoruba Bible (YCE)
Simoni Peteru bi í pé, “Oluwa, níbo ni ò ń lọ?” Jesu dá a lóhùn pé, “Níbi tí mò ń lọ, ìwọ kò lè tẹ̀lé mi nisinsinyii, ṣugbọn nígbà tí ó bá yá, ìwọ óo tẹ̀lé mi.” Peteru bi í pé, “Oluwa, kí ló dé tí n kò lè tẹ̀lé ọ nisinsinyii? Mo ṣetán láti kú nítorí rẹ.”
Joh 13:36-37 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Simoni Peteru wí fún un pé, “Olúwa, níbo ni ìwọ ń lọ?” Jesu dá a lóhùn pé, “Níbi tí èmi ń lọ, ìwọ kì yóò lè tẹ̀lé mí nísinsin yìí; ṣùgbọ́n ìwọ yóò tọ̀ mí lẹ́yìn ní ìkẹyìn.” Peteru wí fún un pé, “Olúwa èéṣe tí èmi kò fi le tọ̀ ọ́ lẹ́hìn nísinsin yìí? Èmi ó fi ẹ̀mí mi lélẹ̀ nítorí rẹ.”