Joh 13:1-17

Joh 13:1-17 Bibeli Mimọ (YBCV)

NJE ki ajọ irekọja ki o to de, nigbati Jesu mọ̀ pe wakati rẹ̀ de tan, ti on ó ti aiye yi kuro lọ sọdọ Baba, fifẹ ti o fẹ awọn tirẹ̀ ti o wà li aiye, o fẹ wọn titi de opin. Bi nwọn si ti njẹ onjẹ alẹ, ti Èṣu ti fi i si ọkàn Judasi Iskariotu ọmọ Simoni lati fi i hàn; Ti Jesu si ti mọ̀ pe Baba ti fi ohun gbogbo le on lọwọ, ati pe lọdọ Ọlọrun li on ti wá, on si nlọ sọdọ Ọlọrun; O dide ni idi onjẹ alẹ, o si fi agbáda rẹ̀ lelẹ̀ li apakan; nigbati o si mu gèle, o di ara rẹ̀ li àmure. Lẹhinna o bù omi sinu awokòto kan, o si bẹ̀rẹ si ima wẹ̀ ẹsẹ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, o si nfi gèle ti o fi di àmure nù wọn. Nigbana li o de ọdọ Simoni Peteru. On si wi fun u pe, Oluwa, iwọ nwẹ̀ mi li ẹsẹ? Jesu dahùn o si wi fun u pe, Ohun ti emi nṣe iwọ kò mọ̀ nisisiyi; ṣugbọn yio ye ọ nikẹhin. Peteru wi fun u pe, Iwọ kì yio wẹ̀ mi li ẹsẹ lai. Jesu da a lohùn pe, Bi emi kò bá wẹ̀ ọ, iwọ kò ni ìpin lọdọ mi. Simoni Peteru wi fun u pe, Oluwa, kì iṣe ẹsẹ mi nikan, ṣugbọn ati ọwọ́ ati ori mi pẹlu. Jesu wi fun u pe, Ẹniti a ti wẹ̀ kò tun fẹ ju ki a ṣan ẹsẹ rẹ̀, ṣugbọn o mọ́ nibi gbogbo: ẹnyin si mọ́, ṣugbọn kì iṣe gbogbo nyin. Nitoriti o mọ̀ ẹniti yio fi on hàn; nitorina li o ṣe wipe, Kì iṣe gbogbo nyin li o mọ́. Nitorina lẹhin ti o wẹ̀ ẹsẹ wọn tan, ti o si ti mu agbáda rẹ̀, ti o tún joko, o wi fun wọn pe, Ẹnyin mọ̀ ohun ti mo ṣe si nyin? Ẹnyin npè mi li Olukọni ati Oluwa: ẹnyin wi rere; bẹ̃ni mo jẹ. Njẹ bi emi ti iṣe Oluwa ati Olukọni nyin ba wẹ̀ ẹsẹ nyin, o tọ́ ki ẹnyin pẹlu si mã wẹ̀ ẹsẹ ara nyin. Nitori mo ti fi apẹ̃rẹ fun nyin, ki ẹnyin ki o le mã ṣe gẹgẹ bi mo ti ṣe si nyin. Lòtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ọmọ-ọdọ kò tobi jù oluwa rẹ̀ lọ; bẹ̃ni ẹniti a rán kò tobi jù ẹniti o rán a lọ. Bi ẹnyin ba mọ̀ nkan wọnyi, alabukun-fun ni nyin, bi ẹnyin ba nṣe wọn.

Joh 13:1-17 Yoruba Bible (YCE)

Nígbà tí àkókò Àjọ̀dún Ìrékọjá ku ọjọ́ kan, Jesu mọ̀ pé àkókò tó, tí òun yóo kúrò láyé yìí lọ sọ́dọ̀ Baba. Fífẹ́ tí ó fẹ́ràn àwọn eniyan rẹ̀ tó wà láyé yìí, ó fẹ́ràn wọn dé òpin. Bí wọ́n ti ń jẹun, Èṣù ti fi sí Judasi ọmọ Simoni Iskariotu lọ́kàn láti fi Jesu lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́. Jesu mọ̀ pé Baba ti fi ohun gbogbo lé òun lọ́wọ́, ati pé ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni òun ti wá, ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni òun sì ń lọ. Ó bá dìde nídìí oúnjẹ, ó bọ́ agbádá rẹ̀ sílẹ̀, ó mú aṣọ ìnura, ó lọ́ ọ mọ́ ìbàdí, ó bu omi sinu àwokòtò kan, ó bẹ̀rẹ̀ sí fọ ẹsẹ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó ń fi aṣọ ìnura tí ó lọ́ mọ́ ìbàdí nù wọ́n lẹ́sẹ̀. Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ Simoni Peteru, Peteru bi í pé, “Oluwa, ìwọ ni o fẹ́ fọ ẹsẹ̀ mi?” Jesu dá a lóhùn pé, “O kò mọ ohun tí mò ń ṣe nisinsinyii; ṣugbọn yóo yé ọ tí ó bá yá.” Peteru dá a lóhùn pé, “O kò ní fọ ẹsẹ̀ mi laelae!” Jesu wí fún un pé, “Bí n kò bá wẹ̀ ọ́, a jẹ́ pé ìwọ kò ní nǹkankan ṣe pẹlu mi.” Simoni Peteru bá sọ fún un pé, “Bí ó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, Oluwa, ẹsẹ̀ mi nìkan kọ́, ati ọwọ́ ati orí mi ni kí o fọ̀ pẹlu.” Jesu wí fún un pé, “Ẹni tí ó bá ti wẹ̀ nílé, tí ó bá jáde, kò sí ohun tí ó kù jù pé kí á fọ ẹsẹ̀ rẹ̀ lọ, gbogbo ara rẹ̀ á wá di mímọ́. Ẹ̀yin mọ́, ṣugbọn kì í ṣe gbogbo yín.” Ó ti mọ ẹni tí yóo fi òun lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́; nítorí náà ni ó ṣe sọ pé, “Kì í ṣe gbogbo yín ni ó mọ́.” Nígbà tí ó ti fọ ẹsẹ̀ wọn tán, ó wọ agbádá rẹ̀, ó bá tún jókòó. Ó wá bi wọ́n pé, “Ǹjẹ́ ẹ mọ ohun tí mo ṣe si yín? Ẹ̀ ń pè mí ní Olùkọ́ni ati Oluwa. Ó dára, nítorí bẹ́ẹ̀ ni mo jẹ́. Bí èmi Oluwa ati Olùkọ́ni yín bá fọ ẹsẹ̀ yín, ó yẹ kí ẹ máa fọ ẹsẹ̀ ẹnìkejì yín. Àpẹẹrẹ ni mo fi fun yín pé, gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe si yín, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ máa ṣe. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé: ẹrú kò ju oluwa rẹ̀ lọ, iranṣẹ kò ju ẹni tí ó rán an níṣẹ́ lọ. Bí ẹ bá mọ nǹkan wọnyi, ẹ óo láyọ̀ bí ẹ bá ń ṣe wọ́n.

Joh 13:1-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ǹjẹ́ kí àjọ ìrékọjá tó dé, nígbà tí Jesu mọ̀ pé, wákàtí rẹ̀ dé tan, tí òun ó ti ayé yìí kúrò lọ sọ́dọ̀ Baba, fífẹ́ tí ó fẹ́ àwọn tirẹ̀ tí ó wà ní ayé, ó fẹ́ wọn títí dé òpin. Bí wọ́n sì ti ń jẹ oúnjẹ alẹ́, tí èṣù ti fi í sí ọkàn Judasi Iskariotu ọmọ Simoni láti fi í hàn; Tí Jesu sì ti mọ̀ pé Baba ti fi ohun gbogbo lé òun lọ́wọ́, àti pé lọ́dọ̀ Ọlọ́run ni òun ti wá, òun sì ń lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run; Ó dìde ní ìdí oúnjẹ alẹ́, ó sì fi agbádá rẹ̀ lélẹ̀ ní apá kan; nígbà tí ó sì mú aṣọ ìnura, ó di ara rẹ̀ ní àmùrè. Lẹ́yìn náà, ó bu omi sínú àwokòtò kan, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í máa wẹ ẹsẹ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó sì ń fi aṣọ ìnura tí ó fi di àmùrè nù wọ́n. Nígbà náà ni ó dé ọ̀dọ̀ Simoni Peteru, òun sì wí fún un pé, “Olúwa, ìwọ yóò ha wẹ ẹsẹ̀ mi?” Jesu dá a lóhùn, ó sì wí fún un pé, “Ohun tí èmi ń ṣe ni ìwọ kò mọ̀ nísinsin yìí; ṣùgbọ́n yóò yé ọ ní ìkẹyìn.” Peteru wí fún un pé, “Ìwọ kì yóò wẹ̀ ẹsẹ̀ mi láé.” Jesu sì dalóhùn pé, “Bí èmi kò bá wẹ̀ ọ́, ìwọ kò ní ìpín ní ọ̀dọ̀ mi.” Simoni Peteru wí fún ún pé, “Olúwa, kì í ṣe ẹsẹ̀ mi nìkan, ṣùgbọ́n àti ọwọ́ àti orí mi pẹ̀lú.” Jesu wí fún un pé, “Ẹni tí a wẹ̀ kò tún fẹ́ ju kí a ṣan ẹsẹ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n ó mọ́ níbi gbogbo: ẹ̀yin sì mọ́, ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo yín.” Nítorí tí ó mọ ẹni tí yóò fi òun hàn; nítorí náà ni ó ṣe wí pé, kì í ṣe gbogbo yín ni ó mọ́. Nítorí náà lẹ́yìn tí ó wẹ ẹsẹ̀ wọn tán, tí ó sì ti mú agbádá rẹ̀, tí ó tún jókòó, ó wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin mọ ohun tí mo ṣe sí yín bí? Ẹ̀yin ń pè mí ní ‘Olùkọ́’ àti ‘Olúwa,’ ẹ̀yin wí rere; bẹ́ẹ̀ ni mo jẹ́. Ǹjẹ́ bí èmi tí í ṣe Olúwa àti olùkọ́ yín bá wẹ ẹsẹ̀ yín, ó tọ́ kí ẹ̀yin pẹ̀lú sì máa wẹ ẹsẹ̀ ara yín. Nítorí mo fi àpẹẹrẹ fún yín, kí ẹ̀yin lè máa ṣe gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe sí yín. Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ọmọ ọ̀dọ̀ kò tóbi ju ọ̀gá rẹ̀ lọ, bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí a rán kò tóbi ju ẹni tí ó rán an lọ. Bí ẹ̀yin bá mọ nǹkan wọ̀nyí, alábùkún fún ni yín, bí ẹ̀yin bá ń ṣe wọ́n!