Jer 9:7-9
Jer 9:7-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitorina bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, sa wò o, emi o yọ́ wọn, emi o si dán wọn wò, nitori kili emi o ṣe fun ọmọbinrin enia mi. Ahọn wọn dabi ọfa ti a ta, o nsọ ẹ̀tan, ẹnikini nfi ẹnu rẹ̀ sọ alafia fun ẹnikeji rẹ̀, ṣugbọn li ọkàn rẹ̀ o ba dè e. Emi kì yio ha bẹ̀ wọn wò nitori nkan wọnyi? li Oluwa wi, ọkàn mi kì yio ha gbẹsan lara orilẹ-ède bi iru eyi?
Jer 9:7-9 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí náà, ó ní: “Wò ó! N óo fọ̀ wọ́n mọ́, n óo dán wọn wò. Àbí, kí ni kí n tún ṣe fún àwọn eniyan yìí? Ahọ́n wọn dàbí ọfà apanirun, wọ́n ń sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn. Olukuluku ń sọ̀rọ̀ alaafia jáde lẹ́nu fún aládùúgbò rẹ̀, ṣugbọn ète ikú ni ó ń pa sí i ninu ọkàn rẹ̀. Ṣé n kò wá ní jẹ wọ́n níyà fún àwọn nǹkan tí wọ́n ṣe wọnyi? Àbí n kò ní gbẹ̀san ara mi lára irú orílẹ̀-èdè yìí?”
Jer 9:7-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí náà, èyí ni ohun tí OLúWA Ọlọ́run Àwọn ọmọ-ogun wí: “Wò ó, èmi dán wọn wo; nítorí pé kí ni èmi tún le è ṣe? Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn mi? Ahọ́n wọn dàbí ọfà olóró ó ń sọ ẹ̀tàn; oníkálùkù sì ń fi ẹnu rẹ̀ sọ̀rọ̀ àlàáfíà sí aládùúgbò rẹ̀; ní inú ọkàn rẹ̀, ó dẹ tàkúté sílẹ̀. Èmi kì yóò ha fi ìyà jẹ wọ́n nítorí èyí?” ni OLúWA wí. “Èmi kì yóò ha gbẹ̀san ara mi lórí irú orílẹ̀-èdè yìí bí?”