JEREMAYA 9

9
1Orí mi ìbá jẹ́ kìkì omi,
kí ojú mi sì jẹ́ orísun omijé;
tọ̀sán-tòru ni ǹ bá fi máa sọkún,
nítorí àwọn eniyan mi tí ogun ti pa.
2Ìbá ṣe pé mo ní ilé èrò kan ninu aṣálẹ̀,
ǹ bá kó àwọn eniyan mi dà sílẹ̀ níbẹ̀,
ǹ bá sì kúrò lọ́dọ̀ wọn;
nítorí alágbèrè ni gbogbo wọn,
ati àgbájọ àwọn alárèékérekè eniyan.
3Bí ẹni kẹ́ ọrun ni wọ́n kẹ́ ahọ́n wọn,
láti máa fọ́n irọ́ jáde bí ẹni ta ọfà;
dípò òtítọ́ irọ́ ní ń gbilẹ̀ ní ilẹ̀ náà.
OLUWA ní,
“Wọ́n ń tinú ibi bọ́ sinu ibi,
wọn kò sì mọ̀ èmi OLUWA.”
4Kí olukuluku ṣọ́ra lọ́dọ̀ aládùúgbò rẹ̀,
kí ó má sì gbẹ́kẹ̀lé arakunrin rẹ̀ kankan.
Nítorí pé ajinnilẹ́sẹ̀ ni gbogbo arakunrin,
a-fọ̀rọ̀-kẹ́lẹ́-ba-tẹni-jẹ́ sì ni gbogbo aládùúgbò.
5Olukuluku ń tan ọ̀rẹ́ rẹ̀ jẹ,
kò sì sí ẹnìkan tí ń sọ òtítọ́.
Wọ́n ti kọ́ ahọ́n wọn ní irọ́ pípa;
wọ́n dẹ́ṣẹ̀ títí, ó sú wọn,
wọn kò sì ronú àtipàwàdà.
6Ìninilára ń gorí ìninilára,
ẹ̀tàn ń gorí ẹ̀tàn,
OLUWA ní, “Wọ́n kọ̀ wọn kò mọ̀ mí.”
7Nítorí náà, ó ní:
“Wò ó! N óo fọ̀ wọ́n mọ́,
n óo dán wọn wò.
Àbí, kí ni kí n tún ṣe fún àwọn eniyan yìí?
8Ahọ́n wọn dàbí ọfà apanirun,
wọ́n ń sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn.
Olukuluku ń sọ̀rọ̀ alaafia jáde lẹ́nu fún aládùúgbò rẹ̀,
ṣugbọn ète ikú ni ó ń pa sí i ninu ọkàn rẹ̀.
9Ṣé n kò wá ní jẹ wọ́n níyà fún àwọn nǹkan tí wọ́n ṣe wọnyi?
Àbí n kò ní gbẹ̀san ara mi lára irú orílẹ̀-èdè yìí?”
10Mo ní, “Gbé ẹnu sókè kí o sọkún nítorí àwọn òkè ńlá,
sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn nítorí àwọn pápá inú aṣálẹ̀,
nítorí gbogbo wọn ti di ahoro, láìsí ẹnìkan tí yóo la ààrin wọn kọjá.
A kò ní gbọ́ ohùn ẹran ọ̀sìn níbẹ̀.
Ati ẹyẹ, ati ẹranko, gbogbo wọn ti sá lọ.”
11OLUWA ní, “N óo sọ Jerusalẹmu di àlàpà ati ibùgbé ajáko.
N óo sọ àwọn ìlú Juda di ahoro
ẹnikẹ́ni kò ní gbé inú wọn mọ́.
Èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
12Mo bá bèèrè pé, “Ta ni ẹni tí ó gbọ́n, tí òye nǹkan yìí yé? Ta ni OLUWA ti bá sọ̀rọ̀, kí ó kéde rẹ̀? Kí ló dé tí ilẹ̀ náà fi parun, tí ó sì dàbí aṣálẹ̀ tóbẹ́ẹ̀, tí ẹnikẹ́ni kò fi gba ibẹ̀ kọjá?”
13OLUWA bá dáhùn, ó ní, “Nítorí pé wọ́n kọ òfin tí mo gbékalẹ̀ fún wọn sílẹ̀, wọn kò gbọ́ràn sí mi lẹ́nu, wọn kò sì ṣe gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ mi, 14ṣugbọn wọ́n ń fi agídí ṣe ìfẹ́ ọkàn wọn, wọ́n ń bọ àwọn oriṣa Baali, bí àwọn baba wọn ti kọ́ wọn. 15Nítorí náà, n óo fún wọn ní igi tí ó korò jẹ, n óo sì fún wọn ní omi tí ó ní májèlé mu. Èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ni mo sọ bẹ́ẹ̀. 16N óo fọ́n wọn ká sí ààrin àwọn orílẹ̀-èdè tí àwọn ati àwọn baba ńlá wọn kò mọ̀, n óo sì jẹ́ kí àwọn ọ̀tá yọ idà tẹ̀lé wọn títí tí n óo fi pa wọ́n run.”
Àwọn Eniyan Jerusalẹmu kígbe sókè fún ìrànlọ́wọ́
17OLUWA àwọn ọmọ ogun ní:
“Ẹ ronú sí ọ̀rọ̀ yìí kí ẹ pe àwọn obinrin tíí máa ń ṣọ̀fọ̀ wá,
ẹ ranṣẹ pe àwọn obinrin tí wọ́n mọ ẹkún sun dáradára;
18kí wọ́n wá kíá,
kí wọ́n wá máa sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn lé wa lórí,
kí omi sì máa dà lójú wa pòròpòrò.
19Nítorí a gbọ́ tí ẹkún sọ ní Sioni,
wọ́n ń ké pé, ‘A gbé!
Ìtìjú ńlá dé bá wa,
a níláti kó jáde nílé,
nítorí pé àwọn ọ̀tá ti wó ilé wa.’ ”
20Mo ní, “Ẹ̀yin obinrin, ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA wí,
ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀.
Ẹ kọ́ àwọn ọmọ yín obinrin ní ẹkún sísun,
kí ẹ sì kọ́ aládùúgbò yín ní orin arò.
21Nítorí ikú ti dé ojú fèrèsé wa,
ó ti wọ ààfin wa.
Ikú ń pa àwọn ọmọde nígboro,
ati àwọn ọdọmọkunrin ní gbàgede.”
22Sọ wí pé,
“Òkú eniyan yóo sùn lọ nílẹ̀ bí ìgbọ̀nsẹ̀ lórí pápá tí ó tẹ́jú,
ati bíi ìtí ọkà lẹ́yìn àwọn tí wọn ń kórè ọkà,
kò sì ní sí ẹni tí yóo kó wọn jọ. OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.”
23OLUWA ní, “Kí ọlọ́gbọ́n má fọ́nnu nítorí ọgbọ́n rẹ̀,
kí alágbára má fọ́nnu nítorí agbára rẹ̀;
kí ọlọ́rọ̀ má sì fọ́nnu nítorí ọrọ̀ rẹ̀.
24Ṣugbọn ẹni tí ó bá fẹ́ fọ́nnu,
ohun tí ó lè máa fi fọ́nnu ni pé òun ní òye
ati pé òun mọ̀ pé, èmi OLUWA ni OLUWA tí ń ṣe ẹ̀tọ́,
tí sì ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ati òdodo hàn lórí ilẹ̀ ayé;
nítorí pé àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ ni mo ní inú dídùn sí.”#1 Kọr 1:31; 2 Kọr 10:17
25Ó ní, “Ọjọ́ ń bọ̀, tí n óo fìyà jẹ àwọn tí a kọ nílà, ṣugbọn tí wọn ń ṣe bí aláìkọlà, 26àwọn ará Ijipti, àwọn ọmọ Juda, àwọn ará Edomu, ati àwọn ọmọ Amoni àwọn ará Moabu, ati gbogbo àwọn tí ń gbé inú aṣálẹ̀; tí wọn ń fá apá kan irun orí wọn; nítorí pé bí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi kò ṣe kọlà abẹ́, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ ilẹ̀ Israẹli kò kọlà ọkàn.”

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

JEREMAYA 9: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀