Jer 9:23-24
Jer 9:23-24 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bayi li Oluwa wi, ki ọlọgbọ́n ki o má ṣogo nitori ọgbọ́n rẹ̀, bẹ̃ni ki alagbara ki o má ṣogo nitori agbara rẹ̀, ki ọlọrọ̀ ki o má ṣogo nitori ọrọ̀ rẹ̀. Ṣugbọn ki ẹnikẹni ti yio ba ma ṣogo, ki o ṣe e ninu eyi pe: on ni oye, on si mọ̀ mi; pe, Emi li Oluwa ti nṣe ãnu ati idajọ ati ododo li aiye: nitori inu mi dùn ninu ohun wọnyi, li Oluwa wi.
Jer 9:23-24 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA ní, “Kí ọlọ́gbọ́n má fọ́nnu nítorí ọgbọ́n rẹ̀, kí alágbára má fọ́nnu nítorí agbára rẹ̀; kí ọlọ́rọ̀ má sì fọ́nnu nítorí ọrọ̀ rẹ̀. Ṣugbọn ẹni tí ó bá fẹ́ fọ́nnu, ohun tí ó lè máa fi fọ́nnu ni pé òun ní òye ati pé òun mọ̀ pé, èmi OLUWA ni OLUWA tí ń ṣe ẹ̀tọ́, tí sì ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ati òdodo hàn lórí ilẹ̀ ayé; nítorí pé àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ ni mo ní inú dídùn sí.”
Jer 9:23-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Èyí ni ohun tí OLúWA wí: “Má ṣe jẹ́ kí ọlọ́gbọ́n yangàn nítorí agbára ọgbọ́n rẹ̀, tàbí alágbára nítorí rẹ̀, tàbí ọlọ́rọ̀ nítorí ọrọ̀ rẹ̀. Ẹ jẹ́ kí ẹni tí ń ṣògo nípa èyí nì wí pé òun ní òye, òun sì mọ̀ mí wí pé, èmi ni OLúWA tí ń ṣe òtítọ́ ìdájọ́ àti òdodo ní ayé nínú èyí ni mo ní inú dídùn sí,” OLúWA wí.