Jer 33:14-17
Jer 33:14-17 Bibeli Mimọ (YBCV)
Wò o, ọjọ mbọ, li Oluwa wi, ti emi o mu ohun rere na, ti emi ti leri fun ilẹ Israeli ati fun ile Juda, ṣẹ. Li ọjọ wọnni, ati li akoko na, emi o jẹ ki Ẹka ododo ki o hu soke fun Dafidi; ẹniti yio si ṣe idajọ ati ododo ni ilẹ na. Li ọjọ wọnni li a o gbà Juda la, Jerusalemu yio si ma gbe li ailewu: orukọ yi li a o ma pè e: OLUWA ODODO WA. Nitori bayi li Oluwa wi; A kì o fẹ ọkunrin kan kù lọdọ Dafidi lati joko lori itẹ́ ile Israeli lailai.
Jer 33:14-17 Yoruba Bible (YCE)
Ó ní, “Àkókò ń bọ̀, tí n óo mú ìlérí tí mo ṣe fún ilé Israẹli ati ilé Juda ṣẹ. Nígbà tó bá yá, tí àkókò bá tó, n óo mú kí ẹ̀ka òdodo kan ó sọ jáde ní ilé Dafidi, yóo máa ṣe ìdájọ́ ẹ̀tọ́ ati ti òdodo ní ilẹ̀ náà. A óo gba Juda là, Jerusalẹmu yóo sì wà ní àìléwu, orúkọ tí a óo wá máa pè é ni ‘OLÚWA ni Òdodo wa.’ ” Nítorí OLUWA ní kò ní sí ìgbà kan, tí kò ní jẹ́ pé ọkunrin kan ní ilé Dafidi ni yóo máa jẹ́ ọba ní ilẹ̀ Israẹli
Jer 33:14-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“ ‘Àwọn ọjọ́ náà ń bọ̀,’ ni OLúWA wí, ‘tí èmi ó mú ìlérí rere tí mo ṣe fún ilé Israẹli àti ilé Juda ṣẹ. “ ‘Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì àti ní àkókò náà, Èmi ó gbé olódodo dìde láti ẹ̀ka Dafidi. Yóò ṣe ìdájọ́ àti ohun tí ó tọ́ ní ilẹ̀ náà. Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, Juda yóò di ẹni ìgbàlà. Jerusalẹmu yóò sì máa gbé láìséwu Orúkọ yìí ni a ó máa pè é OLúWA wa olódodo.’ Nítorí báyìí ni OLúWA wí: ‘Dafidi kò ní kùnà láti rí ọkùnrin tí yóò jókòó lórí ìtẹ́ ní ilé Israẹli.