Jer 31:33-34
Jer 31:33-34 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn eyi ni majẹmu ti emi o ba ile Israeli da; Lẹhin ọjọ wọnni, li Oluwa wi, emi o fi ofin mi si inu wọn, emi o si kọ ọ si aiya wọn; emi o si jẹ Ọlọrun wọn, awọn o si jẹ enia mi. Nwọn kì yio si kọni mọ ẹnikini ẹnikeji rẹ̀, ati ẹ̀gbọn, aburo rẹ̀ wipe, Mọ̀ Oluwa: nitoripe gbogbo nwọn ni yio mọ̀ mi, lati ẹni-kekere wọn de ẹni-nla wọn, li Oluwa wi; nitori emi o dari aiṣedede wọn ji, emi kì o si ranti ẹ̀ṣẹ wọn mọ.
Jer 31:33-34 Yoruba Bible (YCE)
Ṣugbọn majẹmu tí n óo bá ilé Israẹli dá nígbà tó bá yá nìyí: N óo fi òfin mi sí inú wọn, n óo sì kọ wọ́n sí ọkàn wọn. N óo máa jẹ́ Ọlọrun wọn, wọn yóo sì máa jẹ́ eniyan mi. Ẹnikẹ́ni kò ní máa kọ́ aládùúgbò rẹ̀ tabi arakunrin rẹ̀ bí a ti í mọ èmi OLUWA mọ́, gbogbo wọn ni wọn yóo mọ̀ mí ati àwọn mẹ̀kúnnù ati àwọn eniyan pataki pataki. N óo dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n, n kò sì ní ranti àìdára wọn mọ́. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
Jer 31:33-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Èyí ni májẹ̀mú tí èmi yóò bá ilé Israẹli dá lẹ́yìn ìgbà náà,” ni OLúWA wí pé: “Èmi yóò fi òfin mi sí ọkàn wọn, èmi ó sì kọ ọ́ sí àyà wọn. Èmi ó jẹ́ OLúWA wọn; àwọn ó sì jẹ́ ènìyàn mi. Kò ní sí pé ọkùnrin kan ń kọ́ àwọn ará ilé rẹ̀ tàbí ọkùnrin ń kọ́ arákùnrin rẹ̀ pé, ‘Ẹ mọ OLúWA,’ nítorí gbogbo wọn ni yóò mọ̀ mí láti ẹni kékeré wọn títí dé ẹni ńlá,” ni OLúWA wí. “Nítorí èmi ó dárí àìṣedéédéé wọn jì, èmi kò sì ní rántí ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́.”