Jer 31:1-3
Jer 31:1-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
LI àkoko na, li Oluwa wi, li emi o jẹ Ọlọrun gbogbo idile Israeli, nwọn o si jẹ enia mi. Bayi li Oluwa wi, Enia ti o sala lọwọ idà ri ore-ọfẹ li aginju, ani Israeli nigbati emi lọ lati mu u lọ si isimi rẹ̀. Oluwa ti fi ara hàn fun mi lati okere pe, Nitõtọ emi fi ifẹni aiyeraiye fẹ ọ, nitorina ni emi ti ṣe pa ore-ọfẹ mọ fun ọ.
Jer 31:1-3 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA ní, “Àkókò ń bọ̀ tí n óo jẹ́ Ọlọrun gbogbo ìdílé Israẹli, tí àwọn náà yóo sì jẹ́ eniyan mi. Àwọn tí wọ́n bọ́ lọ́wọ́ idà, rí àánú OLUWA ninu aṣálẹ̀; nígbà tí Israẹli ń wá ìsinmi, OLUWA yọ sí wọn láti òkèèrè. Ìfẹ́ àìlópin ni mo ní sí ọ, nítorí náà n kò ní yé máa fi òtítọ́ bá ọ lò.
Jer 31:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Nígbà náà, Èmi yóò jẹ́ Ọlọ́run fún gbogbo ìdílé ìran Israẹli, àwọn náà yóò sì jẹ́ ènìyàn mi,” ni OLúWA wí. Èyí ni ohun tí OLúWA wí: “Àwọn ènìyàn tí ó sá àsálà lọ́wọ́ idà yóò rí ojúrere OLúWA ní aṣálẹ̀, Èmi yóò sì fi ìsinmi fún Israẹli.” OLúWA ti fi ara rẹ̀ hàn wá ní ìgbà kan rí, ó wí pé: “Èmi ti nífẹ̀ẹ́ yín pẹ̀lú ìfẹ́ àìlópin; mo ti fi ìfẹ́ ńlá fà yín