Jer 31:1-14
Jer 31:1-14 Bibeli Mimọ (YBCV)
LI àkoko na, li Oluwa wi, li emi o jẹ Ọlọrun gbogbo idile Israeli, nwọn o si jẹ enia mi. Bayi li Oluwa wi, Enia ti o sala lọwọ idà ri ore-ọfẹ li aginju, ani Israeli nigbati emi lọ lati mu u lọ si isimi rẹ̀. Oluwa ti fi ara hàn fun mi lati okere pe, Nitõtọ emi fi ifẹni aiyeraiye fẹ ọ, nitorina ni emi ti ṣe pa ore-ọfẹ mọ fun ọ. Emi o tun ọ kọ́, iwọ o si di kikọ, iwọ wundia Israeli! iwọ o si fi timbreli rẹ ṣe ara rẹ lọṣọ, iwọ o si jade lọ ni ọwọ́-ijo ti awọn ti nyọ̀. Iwọ o gbìn ọgba-ajara sori oke Samaria: awọn àgbẹ yio gbìn i, nwọn o si jẹ ẹ. Nitori ọjọ na ni eyi, ti awọn oluṣọ lori oke Efraimu yio kigbe pe, Ẹ dide, ẹ si jẹ ki a goke lọ si Sioni sọdọ Oluwa, Ọlọrun wa. Nitori bayi li Oluwa wi; ẹ fi ayọ̀ kọrin didùn fun Jakobu, ẹ si ho niti olori awọn orilẹ-ède: ẹ kede! ẹ yìn, ki ẹ si wipe: Oluwa, gbà awọn enia rẹ la, iyokù Israeli! Wò o, emi o mu wọn lati ilẹ ariwa wá, emi o si kó wọn jọ lati àgbegbe ilẹ aiye, afọju ati ayarọ pẹlu wọn, aboyun ati ẹniti nrọbi ṣọkan pọ̀: li ẹgbẹ nlanla ni nwọn o pada sibẹ. Nwọn o wá pẹlu ẹkun, pẹlu adura li emi o si ṣe amọ̀na wọn: emi o mu wọn rìn lẹba odò omi li ọ̀na ganran, nwọn kì yio kọsẹ ninu rẹ̀: nitori emi jẹ baba fun Israeli, Efraimu si li akọbi mi. Ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, ẹnyin orilẹ-ède, ẹ sọ ọ ninu erekuṣu òkere, ki ẹ si wipe, Ẹniti o tú Israeli ka yio kó o jọ, yio si pa a mọ, gẹgẹ bi oluṣọ-agutan agbo-ẹran rẹ̀. Nitori Oluwa ti tú Jakobu silẹ, o si rà a pada li ọwọ awọn ti o li agbara jù u lọ. Njẹ, nwọn o wá, nwọn o si kọrin ni ibi giga Sioni, nwọn o si jumọ lọ sibi ore Oluwa, ani fun alikama, ati fun ọti-waini, ati fun ororo, ati fun ẹgbọrọ agbo-ẹran, ati ọwọ́-ẹran: ọkàn wọn yio si dabi ọgbà ti a bomi rin; nwọn kì yio si kãnu mọ rara. Nigbana ni wundia yio yọ̀ ninu ijó, pẹlu ọdọmọkunrin ati arugbo ṣọkan pọ̀: nitori emi o sọ ọ̀fọ wọn di ayọ̀, emi o si tù wọn ninu, emi o si mu wọn yọ̀ lẹhin ikãnu wọn. Emi o si fi sisanra tẹ ọkàn awọn alufa lọrun, ore mi yio si tẹ awọn enia mi lọrun, li Oluwa wi.
Jer 31:1-14 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA ní, “Àkókò ń bọ̀ tí n óo jẹ́ Ọlọrun gbogbo ìdílé Israẹli, tí àwọn náà yóo sì jẹ́ eniyan mi. Àwọn tí wọ́n bọ́ lọ́wọ́ idà, rí àánú OLUWA ninu aṣálẹ̀; nígbà tí Israẹli ń wá ìsinmi, OLUWA yọ sí wọn láti òkèèrè. Ìfẹ́ àìlópin ni mo ní sí ọ, nítorí náà n kò ní yé máa fi òtítọ́ bá ọ lò. N óo tún yín gbé dìde, ẹ óo sì di ọ̀tun, ẹ̀yin ọmọ Israẹli. Ẹ óo tún fi aro lu ìlù ayọ̀, ẹ óo sì jó ijó ìdùnnú. Ẹ óo tún ṣe ọgbà àjàrà sórí òkè Samaria; àwọn tí wọ́n gbin àjàrà ni yóo sì gbádùn èso orí rẹ̀. Nítorí pé ọjọ́ kan ń bọ̀, tí àwọn aṣọ́nà yóo pè yín láti orí òkè Efuraimu pé, ‘Ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí á lọ sí òkè Sioni, sí ọ̀dọ̀ OLUWA Ọlọrun wa.’ ” OLUWA ní, “Ẹ kọ orin sókè pẹlu ìdùnnú fún Jakọbu, kí ẹ sì hó fún olórí àwọn orílẹ̀-èdè, ẹ kéde, ẹ kọ orin ìyìn, kí ẹ sì wí pé, ‘OLUWA ti gba àwọn eniyan rẹ̀ là àní, àwọn eniyan Israẹli yòókù.’ Ẹ wò ó! N óo kó wọn wá láti ilẹ̀ àríwá, n óo kó wọn jọ láti òpin ayé. Àwọn afọ́jú ati arọ yóo wà láàrin wọn, ati aboyún ati àwọn tí wọn ń rọbí lọ́wọ́. Ogunlọ́gọ̀ eniyan ni àwọn tí yóo pada wá síbí. Tẹkúntẹkún ni wọn yóo wá, tàánútàánú ni n óo sì fi darí wọn pada. N óo mú kí wọn rìn ní etí odò tí ń ṣàn, lójú ọ̀nà tààrà, níbi tí wọn kò ti ní fẹsẹ̀ kọ; nítorí pé baba ni mo jẹ́ fún Israẹli, àkọ́bí mi sì ni Efuraimu.” OLUWA ní, “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ èmi OLUWA, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè, kí ẹ sì kéde rẹ̀ ní èbúté lókèèrè réré; ẹ sọ pé, ‘Ẹni tí ó fọ́n Israẹli ká ni yóo kó wọn jọ, yóo sì máa tọ́jú wọn, bí olùṣọ́-aguntan tíí tọ́jú agbo aguntan rẹ̀.’ Nítorí OLUWA yóo ra ilé Jakọbu pada, yóo rà wọ́n pada lọ́wọ́ ẹni tí ó lágbára jù wọ́n lọ. Wọn yóo wá kọrin lórí òkè Sioni, wọn óo sì yọ̀ lórí nǹkan ọ̀pọ̀ oore tí OLUWA yóo ṣe fún wọn: Wọ́n óo yọ̀ nítorí oore ọkà ati waini ati òróró, ati aguntan ati ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù; ayé wọn óo dàbí ọgbà tí à ń bomi rin, wọn kò ní dààmú mọ́. Àwọn ọdọmọbinrin óo máa jó ijó ayọ̀ nígbà náà, àwọn ọdọmọkunrin ati àwọn àgbààgbà, yóo sì máa ṣe àríyá. N óo sọ ọ̀fọ̀ wọn di ayọ̀, n óo tù wọ́n ninu, n óo sì fún wọn ní ayọ̀ dípò ìbànújẹ́ wọn. N óo fún àwọn alufaa ní ọpọlọpọ oúnjẹ, n óo sì fi oore mi tẹ́ àwọn eniyan mi lọ́rùn. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
Jer 31:1-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Nígbà náà, Èmi yóò jẹ́ Ọlọ́run fún gbogbo ìdílé ìran Israẹli, àwọn náà yóò sì jẹ́ ènìyàn mi,” ni OLúWA wí. Èyí ni ohun tí OLúWA wí: “Àwọn ènìyàn tí ó sá àsálà lọ́wọ́ idà yóò rí ojúrere OLúWA ní aṣálẹ̀, Èmi yóò sì fi ìsinmi fún Israẹli.” OLúWA ti fi ara rẹ̀ hàn wá ní ìgbà kan rí, ó wí pé: “Èmi ti nífẹ̀ẹ́ yín pẹ̀lú ìfẹ́ àìlópin; mo ti fi ìfẹ́ ńlá fà yín, Èmi yóò tún gbé e yín sókè, àní a ó tún gbé e yín ró ìwọ wúńdíá ilẹ̀ Israẹli. Àní ẹ ó tún tún ohun èlò orin yín gbé, ẹ ó sì jáde síta pẹ̀lú ijó àti ayọ̀. Ẹ ó tún gbin ọgbà àjàrà ní orí òkè Samaria; àwọn àgbẹ̀ yóò sì máa gbádùn èso oko wọn. Ọjọ́ kan máa wà tí àwọn olùṣọ́ yóò kígbe jáde lórí òkè Efraimu wí pé, ‘Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a gòkè lọ sí Sioni, ní ọ̀dọ̀ OLúWA Ọlọ́run wa.’ ” Èyí ni ọ̀rọ̀ tí OLúWA sọ wí pé: “Ẹ fi ayọ̀ kọrin sí Jakọbu; ẹ hó sí olórí àwọn orílẹ̀-èdè gbogbo. Jẹ́ kí wọ́n gbọ́ ìyìn rẹ kí o sì wí pé, ‘OLúWA, gba àwọn ènìyàn rẹ là; àwọn tí ó ṣẹ́kù ní Israẹli.’ Wò ó, Èmi yóò mú wọn wá láti ilẹ̀ àríwá; èmi yóò kó gbogbo wọn jọ láti òpin ayé. Lára wọn ni yóò jẹ́ afọ́jú àti arọ, aboyún àti obìnrin tí ń rọbí, ọ̀pọ̀ ènìyàn yóò wá. Wọn yóò wá pẹ̀lú ẹkún, wọn yóò gbàdúrà bí Èmi yóò ṣe mú wọn padà. Èmi yóò jẹ́ atọ́nà fún wọn ní ẹ̀bá odò omi; ní ọ̀nà tí ó tẹ́jú tí wọn kì yóò le ṣubú, nítorí èmi ni baba Israẹli, Efraimu sì ni àkọ́bí ọkùnrin mi. “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ OLúWA ẹ̀yin orílẹ̀-èdè ẹ kéde rẹ̀ ní erékùṣù jíjìn; ‘Ẹni tí ó bá tú Israẹli ká yóò kójọ, yóò sì ṣọ́ agbo rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́-àgùntàn.’ Nítorí OLúWA ti tú Jakọbu sílẹ̀, o sì rà á padà ní ọwọ́ àwọn tí ó lágbára jù ú lọ Wọn yóò wá, wọn ó sì hó ìhó ayọ̀ lórí òkè Sioni; wọn yóò yọ ayọ̀ níbi oore OLúWA. Àlìkámà ni, ọtí wáìnì tuntun àti òróró ọ̀dọ́-àgùntàn àti ọ̀dọ́ ọ̀wọ́ ẹran. Wọn ó dàbí ọgbà àjàrà tí a bomirin, ìkorò kò ní bá wọn mọ́. Àwọn wúńdíá yóò jó, wọn ó sì kún fún ayọ̀, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ọkùnrin àti obìnrin. Èmi yóò sọ ọ̀fọ̀ wọn di ayọ̀, dípò ìkorò èmi yóò tù wọ́n nínú. Èmi ó sì fún wọn ní ayọ̀. Èmi ó tẹ́ àwọn àlùfáà lọ́rùn pẹ̀lú ọ̀pọ̀; àwọn ènìyàn mi yóò sì kún fún oore mi,” ni OLúWA wí.