Jer 29:12-14
Jer 29:12-14 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹnyin o si kepe mi, ẹ o si lọ, ẹ o si gbadura si mi, emi o si tẹti si nyin. Ẹnyin o si ṣafẹri mi, ẹ o si ri mi, nitori ẹ o fi gbogbo ọkàn nyin wá mi. Emi o di ríri fun nyin, li Oluwa wi: emi o si yi igbekun nyin pada kuro, emi o si kó nyin jọ lati gbogbo orilẹ-ède ati lati ibi gbogbo wá, nibiti emi ti lé nyin lọ, li Oluwa wi; emi o si tun mu nyin wá si ibi ti mo ti mu ki a kó nyin ni igbekun lọ.
Jer 29:12-14 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ óo ké pè mí, ẹ óo gbadura sí mi, n óo sì gbọ́ adura yín. Ẹ óo wá mi, ẹ óo sì rí mi, bí ẹ bá fi tọkàntọkàn wá mi. Ẹ óo rí mi, n óo dá ire yín pada, n óo ko yín jọ láti gbogbo orílẹ̀-èdè ati láti gbogbo ibi tí mo ti le yín lọ; n óo sì ko yín pada sí ibi tí mo ti le yín kúrò lọ sí ìgbèkùn. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
Jer 29:12-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò ké pè mí, tí ẹ̀yin yóò sì gbàdúrà sí mi, tí èmi yóò sì gbọ́ àdúrà yín. Ẹ̀yin yóò wá mi, bí ẹ̀yin bá sì fi gbogbo ọkàn yín wá mi: ẹ̀yin yóò rí mi ni OLúWA Ọlọ́run wí. Èmi yóò di rí rí fún yín ni OLúWA wí, Èmi yóò sì mú yín padà kúrò ní ìgbèkùn. Èmi yóò ṣà yín jọ láti gbogbo orílẹ̀-èdè àti ibi gbogbo tí Èmi ti lé yín jáde, ni OLúWA wí. Èmi yóò sì kó yín padà sí ibi tí mo ti mú kí a kó yín ní ìgbèkùn lọ.”