Jer 29:10-12
Jer 29:10-12 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitori bayi li Oluwa wi pe, Lẹhin ti ãdọrin ọdun ba pari ni Babeli, li emi o bẹ̀ nyin wò, emi o si mu ọ̀rọ rere mi ṣẹ si nyin, ni mimu nyin pada si ibi yi. Nitori emi mọ̀ ìro ti mo rò si nyin, li Oluwa wi, ani ìro alafia, kì si iṣe fun ibi, lati fun nyin ni ìgba ikẹhin ati ireti. Ẹnyin o si kepe mi, ẹ o si lọ, ẹ o si gbadura si mi, emi o si tẹti si nyin.
Jer 29:10-12 Yoruba Bible (YCE)
“Nígbà tí aadọrin ọdún Babiloni bá pé, n óo mójú tó ọ̀rọ̀ yín, n óo mú ìlérí mi ṣẹ fun yín, n óo sì ko yín pada sí ibí yìí. Nítorí pé mo mọ èrò tí mò ń gbà si yín, èrò alaafia ni, kì í ṣe èrò ibi. N óo mú kí ọjọ́ ọ̀la dára fun yín, n óo sì fun yín ní ìrètí. Ẹ óo ké pè mí, ẹ óo gbadura sí mi, n óo sì gbọ́ adura yín.
Jer 29:10-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Báyìí ni OLúWA wí: “Nígbà tí ẹ bá lo àádọ́rin ọdún pé ní Babeli, èmi yóò tọ̀ yín wá láti ṣe àmúṣẹ ìlérí ńlá mi fún un yín, àní láti kó o yín padà sí Jerusalẹmu. Nítorí mo mọ èrò tí mo rò sí yín,” ni OLúWA wí, “àní èrò àlàáfíà, kì í sì ṣe fún ibi, èrò láti fún un yín ní ìgbà ìkẹyìn àti ìrètí ọjọ́ iwájú. Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò ké pè mí, tí ẹ̀yin yóò sì gbàdúrà sí mi, tí èmi yóò sì gbọ́ àdúrà yín.