Jer 20:7-18
Jer 20:7-18 Bibeli Mimọ (YBCV)
Oluwa, iwọ ti fi ọ̀rọ rọ̀ mi, emi si gba rirọ̀! iwọ li agbara jù mi lọ, o si bori mi; emi di ẹni iyọ-ṣuti-si lojojumọ, gbogbo wọn ni ngàn mi! Nitori lati igba ti mo ti sọ̀rọ, emi kigbe, mo ke, Iwa-agbara, ati iparun, nitori a sọ ọ̀rọ Oluwa di ohun ẹ̀gan ati itiju fun mi lojojumọ. Nitorina mo si wipe, emi kì yio mu ni ranti rẹ̀, emi kì yio si sọ ọ̀rọ li orukọ rẹ̀ mọ́. Ṣugbọn ọ̀rọ rẹ̀ mbẹ bi iná ti njó ninu mi ti a se mọ inu egungun mi, o si rẹ̀ mi lati pa a mọra, emi kò le ṣe e. Nitoriti mo gbọ́ ẹgan ọ̀pọlọpọ, idãmu niha gbogbo, nwọn wipe: fi sùn, awa o si fi sùn. Gbogbo awọn ọrẹ mi, ati gbogbo awọn ẹgbẹ mi wipe: bọya a o tãn jẹ, awa o si ṣẹgun rẹ̀, a o si gbẹsan wa lara rẹ̀. Ṣugbọn Oluwa mbẹ lọdọ mi bi akọni ẹlẹrù, nitorina awọn ti nṣe inunibini si mi yio ṣubu, nwọn kì yio le bori: oju yio tì wọn gidigidi, nitoripe nwọn kì o ṣe rere: a ki yio gbagbe itiju wọn lailai! Oluwa awọn ọmọ-ogun, iwọ ti ndán olododo wò, iwọ si ri inu ati ọkàn, emi o ri ẹsan rẹ lara wọn: nitoriti mo ti fi ọ̀ran mi le ọ lọwọ! Ẹ kọrin si Oluwa, ẹ yìn Oluwa, nitoriti o ti gbà ọkàn talaka kuro lọwọ awọn oluṣe buburu. Egbe ni fun ọjọ na ti a bi mi! ọjọ na ti iya mi bi mi, ki o má ri ibukun! Egbe ni fun ọkunrin na ti o mu ihìn tọ̀ baba mi wá, wipe, Ọmọkunrin li a bi fun ọ; o mu u yọ̀. Ki ọkunrin na ki o si dabi ilu wọnni ti Oluwa ti bì ṣubu, li aiyi ọkàn pada, ki o si gbọ́ ẹkun li owurọ, ati ọ̀fọ li ọsangangan. Nitoriti kò pa mi ni inu iya mi, tobẹ̃ ki iya mi di isà mi, ki o loyun mi lailai. Ẽṣe ti emi fi jade kuro ninu iya mi, lati ri irora ati oṣi, ati lati pari ọjọ mi ni itiju?
Jer 20:7-18 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA, o tàn mí jẹ, mo sì gba ẹ̀tàn; o ní agbára jù mí lọ, o sì borí mi. Mo di ẹni ẹ̀sín láti àárọ̀ títí di alẹ́, gbogbo eniyan ń fi mí ṣe yẹ̀yẹ́. Gbogbo ìgbà tí mo bá ti sọ̀rọ̀, ni mò ń kígbe pé, “Ogun ati ìparun dé!” Nítorí náà, ọ̀rọ̀ OLUWA tí mò ń kéde sọ mí di ẹni yẹ̀yẹ́ tọ̀sán-tòru. Ṣugbọn nígbàkúùgbà tí mo bá wí pé n kò ní dárúkọ rẹ̀ mọ́, bẹ́ẹ̀ ni n kò ní sọ̀rọ̀ ní orúkọ rẹ̀ mọ́, ọ̀rọ̀ rẹ a máa jó mi ninu bí iná, a sì máa ro mí ninu egungun. Mo gbìyànjú títí pé kí n pa á mọ́ra, ṣugbọn kò ṣeéṣe. Nítorí mò ń gbọ́ tí ọpọlọpọ ń sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ pé, “Ìpayà wà lọ́tùn-ún lósì, ẹ lọ fẹjọ́ rẹ̀ sùn. Ẹ jẹ́ kí á fẹjọ́ rẹ̀ sùn.” Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ mi ń wí, tí wọn sì ń retí ìṣubú mi. Wọ́n ń sọ pé, “Bóyá yóo bọ́ sọ́wọ́ ẹlẹ́tàn, ọwọ́ wa yóo sì tẹ̀ ẹ́; a óo sì gbẹ̀san lára rẹ̀.” Ṣugbọn OLUWA wà pẹlu mi bíi jagunjagun tí ó bani lẹ́rù. Nítorí náà àwọn tí wọn ń lépa mi yóo kọsẹ̀, apá wọn kò ní ká mi. Ojú yóo tì wọ́n lọpọlọpọ nítorí wọn kò ní lè borí mi. Ẹ̀sín tí ẹnikẹ́ni kò ní gbàgbé yóo dé bá wọn títí lae. OLUWA àwọn ọmọ ogun, ìwọ tíí dán olódodo wò, ìwọ tí o mọ ọkàn ati èrò eniyan. Gbẹ̀san lára wọn kí n fojú rí i, nítorí ìwọ ni mo fi ọ̀rọ̀ mi lé lọ́wọ́. Ẹ kọrin sí OLUWA, ẹ yin OLUWA. Nítorí pé ó gba ẹ̀mí aláìní sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn aṣebi. Ègún ni fún ọjọ́ tí a bí mi, kí ọjọ́ tí ìyá mi bí mi má jẹ́ ọjọ́ ayọ̀. Ègún ni fún ẹni tí ó yọ̀ fún baba mi, tí ó sọ fún un pé, “Iyawo rẹ ti bí ọmọkunrin kan fún ọ, tí ó mú inú rẹ̀ dùn.” Kí olúwarẹ̀ dàbí àwọn ìlú tí OLUWA parun láìṣàánú wọn. Kí ó gbọ́ igbe lówùúrọ̀, ati ariwo ìdágìrì lọ́sàn-án gangan. Nítorí pé kò pa mí ninu oyún, kí inú ìyá mi lè jẹ́ isà òkú fún mi. Kí n wà ninu oyún ninu ìyá mi títí ayé. Kí ló dé tí wọn bí mi sáyé? Ṣé kí n lè máa fojú rí ìṣẹ́ ati ìbànújẹ́ ni? Kí gbogbo ọjọ́ ayé mi lè kún fún ìtìjú?
Jer 20:7-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
OLúWA, o tàn mí jẹ́, o sì ṣẹ́gun. Mo di ẹni ẹ̀gàn ní gbogbo ọjọ́, gbogbo ènìyàn fi mí ṣẹlẹ́yà. Nígbàkúgbà tí mo bá sọ̀rọ̀, èmi sì kígbe síta èmi á sọ nípa ipá àti ìparun. Nítorí náà, ọ̀rọ̀ OLúWA ti mú àbùkù àti ẹ̀gàn bá mi ni gbogbo ìgbà. Ṣùgbọ́n bí mo bá sọ pé, “Èmi kì yóò dárúkọ rẹ tàbí sọ nípa orúkọ rẹ̀ mọ́, ọ̀rọ̀ rẹ̀ ń bẹ bi iná tí ń jó nínú mi nínú egungun mi Agara dá mi ní inú mi nítòótọ́ èmi kò lè ṣe é. Mo gbọ́ sísọ ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́, ìbẹ̀rù ni ibi gbogbo Fi í sùn! Jẹ́ kí a fi sùn! Gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ mi ń dúró kí èmi ṣubú, wọ́n sì ń sọ pé, Bóyá yóò jẹ́ di títàn, nígbà náà ni àwa yóò borí rẹ̀, àwa yóò sì gba ẹ̀san wa lára rẹ̀.” Ṣùgbọ́n OLúWA ń bẹ pẹ̀lú mi gẹ́gẹ́ bí akọni ẹlẹ́rù. Nítorí náà, àwọn tí ó ń lépa mi yóò kọsẹ̀, wọn kì yóò sì borí. Wọn yóò kùnà, wọn yóò sì gba ìtìjú púpọ̀. Àbùkù wọn kì yóò sì di ohun ìgbàgbé. OLúWA àwọn ọmọ-ogun, ìwọ tí ó ń dán olódodo wò tí o sì ń ṣe àyẹ̀wò ọkàn àti ẹ̀mí fínní fínní, jẹ́ kí èmi kí ó rí ìgbẹ̀san rẹ lórí wọn, nítorí ìwọ ni mo gbé ara mi lé. Kọrin sí OLúWA! Fi ìyìn fún OLúWA! Ó gba ẹ̀mí àwọn aláìní lọ́wọ́ àwọn ẹni búburú. Ègbé ni fún ọjọ́ tí a bí mi! Kí ọjọ́ tí ìyá mi bí mi má ṣe di ti ìbùkún. Ègbé ni fún ọkùnrin tí ó mú ìròyìn wá fún baba mi, Tí ó mú kí ó yọ̀, tí ó sì sọ wí pé, “A bí ọmọ kan fún ọ—ọmọkùnrin!” Kí ọkùnrin náà dàbí ìlú tí OLúWA gbàkóso lọ́wọ́ rẹ̀ láìkáàánú Kí o sì gbọ́ ariwo ọ̀fọ̀ ní àárọ̀, ariwo ogun ní ọ̀sán. Nítorí kò pa mí nínú, kí ìyá mi sì dàbí títóbi ibojì mi, kí ikùn rẹ̀ sì di títí láé. Èéṣe tí mo jáde nínú ikùn, láti rí wàhálà àti ọ̀fọ̀ àti láti parí ayé mi nínú ìtìjú?