Jer 20:7-13

Jer 20:7-13 Yoruba Bible (YCE)

OLUWA, o tàn mí jẹ, mo sì gba ẹ̀tàn; o ní agbára jù mí lọ, o sì borí mi. Mo di ẹni ẹ̀sín láti àárọ̀ títí di alẹ́, gbogbo eniyan ń fi mí ṣe yẹ̀yẹ́. Gbogbo ìgbà tí mo bá ti sọ̀rọ̀, ni mò ń kígbe pé, “Ogun ati ìparun dé!” Nítorí náà, ọ̀rọ̀ OLUWA tí mò ń kéde sọ mí di ẹni yẹ̀yẹ́ tọ̀sán-tòru. Ṣugbọn nígbàkúùgbà tí mo bá wí pé n kò ní dárúkọ rẹ̀ mọ́, bẹ́ẹ̀ ni n kò ní sọ̀rọ̀ ní orúkọ rẹ̀ mọ́, ọ̀rọ̀ rẹ a máa jó mi ninu bí iná, a sì máa ro mí ninu egungun. Mo gbìyànjú títí pé kí n pa á mọ́ra, ṣugbọn kò ṣeéṣe. Nítorí mò ń gbọ́ tí ọpọlọpọ ń sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ pé, “Ìpayà wà lọ́tùn-ún lósì, ẹ lọ fẹjọ́ rẹ̀ sùn. Ẹ jẹ́ kí á fẹjọ́ rẹ̀ sùn.” Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ mi ń wí, tí wọn sì ń retí ìṣubú mi. Wọ́n ń sọ pé, “Bóyá yóo bọ́ sọ́wọ́ ẹlẹ́tàn, ọwọ́ wa yóo sì tẹ̀ ẹ́; a óo sì gbẹ̀san lára rẹ̀.” Ṣugbọn OLUWA wà pẹlu mi bíi jagunjagun tí ó bani lẹ́rù. Nítorí náà àwọn tí wọn ń lépa mi yóo kọsẹ̀, apá wọn kò ní ká mi. Ojú yóo tì wọ́n lọpọlọpọ nítorí wọn kò ní lè borí mi. Ẹ̀sín tí ẹnikẹ́ni kò ní gbàgbé yóo dé bá wọn títí lae. OLUWA àwọn ọmọ ogun, ìwọ tíí dán olódodo wò, ìwọ tí o mọ ọkàn ati èrò eniyan. Gbẹ̀san lára wọn kí n fojú rí i, nítorí ìwọ ni mo fi ọ̀rọ̀ mi lé lọ́wọ́. Ẹ kọrin sí OLUWA, ẹ yin OLUWA. Nítorí pé ó gba ẹ̀mí aláìní sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn aṣebi.

Jer 20:7-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

OLúWA, o tàn mí jẹ́, o sì ṣẹ́gun. Mo di ẹni ẹ̀gàn ní gbogbo ọjọ́, gbogbo ènìyàn fi mí ṣẹlẹ́yà. Nígbàkúgbà tí mo bá sọ̀rọ̀, èmi sì kígbe síta èmi á sọ nípa ipá àti ìparun. Nítorí náà, ọ̀rọ̀ OLúWA ti mú àbùkù àti ẹ̀gàn bá mi ni gbogbo ìgbà. Ṣùgbọ́n bí mo bá sọ pé, “Èmi kì yóò dárúkọ rẹ tàbí sọ nípa orúkọ rẹ̀ mọ́, ọ̀rọ̀ rẹ̀ ń bẹ bi iná tí ń jó nínú mi nínú egungun mi Agara dá mi ní inú mi nítòótọ́ èmi kò lè ṣe é. Mo gbọ́ sísọ ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́, ìbẹ̀rù ni ibi gbogbo Fi í sùn! Jẹ́ kí a fi sùn! Gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ mi ń dúró kí èmi ṣubú, wọ́n sì ń sọ pé, Bóyá yóò jẹ́ di títàn, nígbà náà ni àwa yóò borí rẹ̀, àwa yóò sì gba ẹ̀san wa lára rẹ̀.” Ṣùgbọ́n OLúWA ń bẹ pẹ̀lú mi gẹ́gẹ́ bí akọni ẹlẹ́rù. Nítorí náà, àwọn tí ó ń lépa mi yóò kọsẹ̀, wọn kì yóò sì borí. Wọn yóò kùnà, wọn yóò sì gba ìtìjú púpọ̀. Àbùkù wọn kì yóò sì di ohun ìgbàgbé. OLúWA àwọn ọmọ-ogun, ìwọ tí ó ń dán olódodo wò tí o sì ń ṣe àyẹ̀wò ọkàn àti ẹ̀mí fínní fínní, jẹ́ kí èmi kí ó rí ìgbẹ̀san rẹ lórí wọn, nítorí ìwọ ni mo gbé ara mi lé. Kọrin sí OLúWA! Fi ìyìn fún OLúWA! Ó gba ẹ̀mí àwọn aláìní lọ́wọ́ àwọn ẹni búburú.