Jer 20:14-18
Jer 20:14-18 Bibeli Mimọ (YBCV)
Egbe ni fun ọjọ na ti a bi mi! ọjọ na ti iya mi bi mi, ki o má ri ibukun! Egbe ni fun ọkunrin na ti o mu ihìn tọ̀ baba mi wá, wipe, Ọmọkunrin li a bi fun ọ; o mu u yọ̀. Ki ọkunrin na ki o si dabi ilu wọnni ti Oluwa ti bì ṣubu, li aiyi ọkàn pada, ki o si gbọ́ ẹkun li owurọ, ati ọ̀fọ li ọsangangan. Nitoriti kò pa mi ni inu iya mi, tobẹ̃ ki iya mi di isà mi, ki o loyun mi lailai. Ẽṣe ti emi fi jade kuro ninu iya mi, lati ri irora ati oṣi, ati lati pari ọjọ mi ni itiju?
Jer 20:14-18 Yoruba Bible (YCE)
Ègún ni fún ọjọ́ tí a bí mi, kí ọjọ́ tí ìyá mi bí mi má jẹ́ ọjọ́ ayọ̀. Ègún ni fún ẹni tí ó yọ̀ fún baba mi, tí ó sọ fún un pé, “Iyawo rẹ ti bí ọmọkunrin kan fún ọ, tí ó mú inú rẹ̀ dùn.” Kí olúwarẹ̀ dàbí àwọn ìlú tí OLUWA parun láìṣàánú wọn. Kí ó gbọ́ igbe lówùúrọ̀, ati ariwo ìdágìrì lọ́sàn-án gangan. Nítorí pé kò pa mí ninu oyún, kí inú ìyá mi lè jẹ́ isà òkú fún mi. Kí n wà ninu oyún ninu ìyá mi títí ayé. Kí ló dé tí wọn bí mi sáyé? Ṣé kí n lè máa fojú rí ìṣẹ́ ati ìbànújẹ́ ni? Kí gbogbo ọjọ́ ayé mi lè kún fún ìtìjú?
Jer 20:14-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ègbé ni fún ọjọ́ tí a bí mi! Kí ọjọ́ tí ìyá mi bí mi má ṣe di ti ìbùkún. Ègbé ni fún ọkùnrin tí ó mú ìròyìn wá fún baba mi, Tí ó mú kí ó yọ̀, tí ó sì sọ wí pé, “A bí ọmọ kan fún ọ—ọmọkùnrin!” Kí ọkùnrin náà dàbí ìlú tí OLúWA gbàkóso lọ́wọ́ rẹ̀ láìkáàánú Kí o sì gbọ́ ariwo ọ̀fọ̀ ní àárọ̀, ariwo ogun ní ọ̀sán. Nítorí kò pa mí nínú, kí ìyá mi sì dàbí títóbi ibojì mi, kí ikùn rẹ̀ sì di títí láé. Èéṣe tí mo jáde nínú ikùn, láti rí wàhálà àti ọ̀fọ̀ àti láti parí ayé mi nínú ìtìjú?