Jer 14:13-14
Jer 14:13-14 Bibeli Mimọ (YBCV)
Emi si wipe, Oluwa Ọlọrun, sa wò o, awọn woli wi fun wọn pe; Ẹnyin kì yio ri idà, bẹ̃li ìyan kì yio de si nyin; ṣugbọn emi o fun nyin ni alafia otitọ ni ibi yi. Nigbana ni Oluwa wi fun mi pe, awọn woli nsọ asọtẹlẹ eke li orukọ mi; emi kò rán wọn, bẹ̃ni emi kò paṣẹ fun wọn, emi kò si sọ̀rọ kan fun wọn, iran eke, afọṣẹ, ati ohun asan, ati ẹ̀tan inu wọn, ni awọn wọnyi sọtẹlẹ fun nyin.
Jer 14:13-14 Yoruba Bible (YCE)
Mo bá dáhùn pé, “Háà! OLUWA Ọlọrun, wò ó! Àwọn wolii ń sọ fún wọn pé, wọn kò ní fojú kan ogun, tabi ìyàn, ati pé, alaafia tòótọ́ ni o óo fún wọn ní ibí yìí.” OLUWA bá sọ fún mi pé, “Àsọtẹ́lẹ̀ irọ́ ni àwọn wolii ń sọ ní orúkọ mi, n kò rán wọn níṣẹ́, n kò fún wọn láṣẹ, n kò tilẹ̀ bá wọn sọ̀rọ̀. Ìran èké ni wọ́n ń rí; iṣẹ́ asán ni wọ́n ń wò. Ohun tí ó wà lọ́kàn wọn ni wọ́n ń sọ.
Jer 14:13-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n mo sọ pé, “Háà! OLúWA Olódùmarè. Àwọn wòlíì ń sọ fún wọn pé, ‘ẹ kò ni rí idà tàbí ìyàn. Dájúdájú èmi ó fún yín ní àlàáfíà tí yóò tọ́jọ́ níbí yìí?’ ” Nígbà náà OLúWA sọ fún mi pé, “àwọn wòlíì ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké ní orúkọ mi. Èmi kò rán wọn, tàbí yàn wọ́n tàbí bá wọn sọ̀rọ̀. Ìran èké ni wọ́n ń rí sí i yín. Àsọtẹ́lẹ̀ èké ni wọ́n ń sọ fún un yín nípa ìran ìrírí, àfọ̀ṣẹ, ìbọ̀rìṣà àti ìtànjẹ ọkàn wọn.