A. Oni 3:1-6
A. Oni 3:1-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
NJẸ wọnyi li awọn orilẹ-ède ti OLUWA fisilẹ, lati ma fi wọn dan Israeli wò, ani iye awọn ti kò mọ̀ gbogbo ogun Kenaani; Nitori idí yi pe, ki iran awọn ọmọ Israeli ki o le mọ̀, lati ma kọ́ wọn li ogun, ani irú awọn ti kò ti mọ̀ ọ niṣaju rí; Awọn ijoye Filistini marun, ati gbogbo awọn Kenaani, ati awọn ara Sidoni, ati awọn Hifi ti ngbé òke Lebanoni, lati òke Baali-hermoni lọ dé atiwọ̀ Hamati. Wọnyi li a o si ma fi dan Israeli wò, lati mọ̀ bi nwọn o fetisi ofin OLUWA, ti o fi fun awọn baba wọn lati ọwọ́ Mose wá. Awọn ọmọ Israeli si joko lãrin awọn ara Kenaani; ati awọn Hitti, ati awọn Amori, ati awọn Perissi, ati awọn Hifi, ati awọn Jebusi: Nwọn si fẹ́ awọn ọmọbinrin wọn li aya, nwọn si fi awọn ọmọbinrin wọn fun awọn ọmọkunrin wọn, nwọn si nsìn awọn oriṣa wọn.
A. Oni 3:1-6 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA fi àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi sílẹ̀ láti fi dán Israẹli wò, pàápàá jùlọ, gbogbo àwọn ọmọ Israẹli tí wọn kò tíì ní ìrírí ogun jíjà ní ilẹ̀ Kenaani. Kí àwọn ọmọ Israẹli lè mọ̀ nípa ogun jíjà, pataki jùlọ, ìṣọ̀wọ́ àwọn tí wọn kò mọ̀ nípa ogun jíjà tẹ́lẹ̀. Àwọn orílẹ̀-èdè tí OLUWA fi sílẹ̀ nìwọ̀nyí: àwọn olú-ìlú Filistini maraarun ati gbogbo ilẹ̀ Kenaani, àwọn ará Sidoni ati àwọn ará Hifi tí wọn ń gbé òkè Lẹbanoni, láti òkè Baali Herimoni títí dé ẹnubodè Hamati. Àwọn ni OLUWA fi dán àwọn ọmọ Israẹli wò, láti wò ó bóyá wọn óo mú àṣẹ tí òun pa fún àwọn baba wọn láti ọwọ́ Mose ṣẹ, tabi wọn kò ní mú un ṣẹ. Nítorí náà, àwọn ọmọ Israẹli ń gbé ààrin àwọn ará Kenaani ati àwọn ará Hiti, àwọn ará Amori ati àwọn ará Perisi, àwọn ará Hifi, ati àwọn ará Jebusi. Àwọn ọmọ Israẹli ń fẹ́mọ lọ́wọ́ àwọn eniyan orílẹ̀-èdè náà, àwọn náà ń fi ọmọ fún wọn; àwọn ọmọ Israẹli sì ń bọ àwọn oriṣa wọn.
A. Oni 3:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àwọn wọ̀nyí ni àwọn orílẹ̀-èdè tí OLúWA fi sílẹ̀ láti dán àwọn ìran tuntun ní Israẹli wò, àwọn ìran tí kò ì tí ì ní ìrírí ogun àwọn ará Kenaani. (Ó ṣe èyí láti fi kọ́ àwọn ìran Israẹli tí kò rí ogun rí níbí a ti ṣe ń jagun): Àwọn ìjòyè ìlú Filistini márààrún, gbogbo àwọn ará Kenaani, àwọn ará Sidoni, àti àwọn ará Hifi tí ń gbé ní àwọn òkè Lebanoni bẹ̀rẹ̀ láti òkè Baali-Hermoni títí dé Lebo-Hamati. A fi àwọn ènìyàn náà sílẹ̀ láti dán àwọn Israẹli wò bóyá wọn yóò gbọ́rọ̀ sí àwọn òfin OLúWA, èyí tí ó ti fi fún àwọn baba wọn láti ipasẹ̀ Mose. Àwọn ọmọ Israẹli gbé láàrín àwọn ará Kenaani, àwọn ará Hiti àwọn ará Amori, àwọn ará Peresi, àwọn ará Hifi àti àwọn ará Jebusi. Dípò kí wọ́n run àwọn ènìyàn wọ̀nyí, Israẹli ń fẹ́ àwọn ọmọbìnrin wọn, wọ́n sì ń fi àwọn ọmọbìnrin Israẹli fún àwọn ará ilẹ̀ náà ní aya, wọ́n sì ń sin àwọn òrìṣà wọn.