A. Oni 16:4-22

A. Oni 16:4-22 Bibeli Mimọ (YBCV)

O si ṣe lẹhin eyinì, o si fẹ́ obinrin kan li afonifoji Soreki, a si ma pè orukọ rẹ̀ ni Delila. Awọn ijoye Filistini tọ̀ ọ wá, nwọn si wi fun u pe, Tàn a, ki o si mọ̀ ibiti agbara nla rẹ̀ gbé wà, ati bi awa o ti ṣe le bori rẹ̀, ki awa ki o le dè e lati jẹ ẹ niyà: olukuluku wa yio si fun ọ ni ẹdẹgbẹfa owo fadakà. Delila si wi fun Samsoni pe, Emi bẹ̀ ọ, wi fun mi, nibo li agbara nla rẹ gbé wà, ati kili a le fi dè ọ lati jẹ ọ niyà. Samsoni si wi fun u pe, Bi a ba fi okùn tutù meje ti a kò ságbẹ dè mi, nigbana li emi o di alailera, emi o si dabi ọkunrin miran. Nigbana li awọn ijoye Filistini mú okùn tutù meje tọ̀ ọ wá ti a kò ságbẹ, o si fi okùn wọnni dè e. Obinrin na si ní awọn kan, ti nwọn lumọ́ ninu yará. On si wi fun u pe, Awọn Filistini dé, Samsoni. On si já okùn na, gẹgẹ bi owú ti ijá nigbati o ba kan iná. Bẹ̃li a kò mọ̀ agbara rẹ̀. Delila si wi fun Samsoni pe, Kiyesi i, iwọ tàn mi jẹ, o si purọ́ fun mi: wi fun mi, emi bẹ̀ ọ, kili a le fi dè ọ. On si wi fun u pe, Bi nwọn ba le fi okùn titun ti a kò ti lò rí dè mi le koko, nigbana li emi o di alailera, emi o si dabi ọkunrin miran. Bẹ̃ni Delila mú okùn titun, o si fi dè e, o si wi fun u pe, Awọn Filistini dé, Samsoni. Awọn ti o lumọ́ dè e wà ninu yará. On si já wọn kuro li apa rẹ̀ bi owu. Delila si wi fun Samsoni pe, Titi di isisiyi iwọ ntàn mi ni, iwọ si npurọ́ fun mi: sọ fun mi, kili a le fi dè ọ. On si wi fun u pe, Bi iwọ ba wun ìdi irun meje ti o wà li ori mi. On si fi ẽkàn dè e, o si wi fun u pe, Awọn Filistini dé, Samsoni. O si jí kuro li oju orun rẹ̀, o si fà ẽkàn ìti na pẹlu ihunṣọ rẹ̀ lọ. On si wi fun u pe, Iwọ ha ti ṣe wipe, Emi fẹ́ ọ, nigbati ọkàn rẹ kò ṣedede pẹlu mi? iwọ ti tàn mi ni ìgba mẹta yi, iwọ kò si sọ ibiti agbara nla rẹ gbé wà fun mi. O si ṣe, nigbati o fi ọ̀rọ rẹ̀ rọ̀ ọ li ojojumọ́, ti o si ṣe e laisimi, tobẹ̃ ti sũru fi tan ọkàn rẹ̀ dé ikú. Li on si sọ gbogbo eyiti o wà li ọkàn rẹ̀ fun u, o si wi fun u pe, Abẹ kò kàn ori mi rí; nitoripe Nasiri Ọlọrun li emi iṣe lati inu iya mi wá: bi a ba fá ori mi, nigbana li agbara mi yio lọ kuro lọdọ mi, emi o si di alailera, emi o si dabi ọkunrin miran. Nigbati Delila ri pe, o sọ gbogbo ọkàn rẹ̀ fun u, o si ranṣẹ pè awọn ijoye Filistini, wipe, Ẹ gòke wá lẹ̃kan yi, nitoriti o sọ gbogbo ọkàn rẹ̀ fun mi. Nigbana li awọn ijoye Filistini wá sọdọ rẹ̀, nwọn si mú owo li ọwọ́ wọn. O si mú ki o sùn li ẽkun rẹ̀; o si pè ọkunrin kan, o si mu ki o fá ìdi irun mejeje ori rẹ̀; on si bẹ̀rẹsi pọ́n ọ loju, agbara rẹ̀ si ti lọ kuro lọdọ rẹ̀. On si wipe, Awọn Filistini dé, Samsoni. O si jí kuro li oju õrun rẹ̀, o si wipe, Emi o jade lọ bi ìgba iṣaju, ki emi ki o si gbọ̀n ara mi. On kò si mọ̀ pe OLUWA ti kuro lọdọ on. Awọn Filistini sì mú u, nwọn si yọ ọ li oju mejeji; nwọn si mú u sọkalẹ wá si Gasa, nwọn si fi ṣẹkẹṣẹkẹ̀ idẹ dè e: on si nlọ-ọlọ ni ile-tubu. Ṣugbọn irun ori rẹ̀ bẹ̀rẹsi hù lẹhin igbati a ti fá a tán.

A. Oni 16:4-22 Yoruba Bible (YCE)

Lẹ́yìn èyí, Samsoni rí obinrin kan tí ó wù ú ní àfonífojì Soreki, ó sì fẹ́ ẹ. Delila ni orúkọ obinrin náà. Àwọn ọba Filistia wá sọ́dọ̀ obinrin yìí, wọ́n ní, “Tan ọkọ rẹ, kí o sì mọ àṣírí agbára rẹ̀, ati ọ̀nà tí a fi lè kápá rẹ̀; kí á lè dì í lókùn kí á sì ṣẹgun rẹ̀. Ẹnìkọ̀ọ̀kan wa yóo sì fún ọ ní ẹẹdẹgbẹfa (1,100) owó fadaka.” Delila bá pe Samsoni, ó ní, “Jọ̀wọ́, sọ àṣírí agbára rẹ fún mi, ati bí eniyan ṣe lè so ọ́ lókùn kí eniyan sì kápá rẹ.” Samsoni dá a lóhùn pé, “Bí wọ́n bá fi awọ tí wọ́n fi ń ṣe ọrun, tí kò tíì gbẹ meje dè mí, yóo rẹ̀ mí, n óo sì dàbí àwọn ọkunrin yòókù.” Àwọn ọba Filistini bá kó awọ tí wọ́n fi ń ṣe ọrun, titun, meje, tí kò tíì gbẹ, fún Delila, ó sì fi so Samsoni. Ó ti fi àwọn eniyan pamọ́ sinu yàrá inú. Ó bá pe Samsoni, ó ní, “Samsoni àwọn ará Filistia dé.” Ṣugbọn Samsoni já awọ ọrun náà bí ìgbà tí iná já fọ́nrán òwú lásán. Wọn kò sì mọ àṣírí agbára rẹ̀. Delila tún wí fún Samsoni pé, “Ò ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà, o sì ń purọ́ fún mi. Jọ̀wọ́ sọ bí eniyan ṣe le dè ọ́ lókùn fún mi.” Ó dá a lóhùn pé, “Tí wọ́n bá fi okùn titun, tí wọn kò tíì lò rí dè mí, yóo rẹ̀ mí, n óo sì dàbí àwọn ọkunrin yòókù.” Delila bá mú okùn titun, ó fi dè é, ó sì wí fún un pé, “Samsoni, àwọn ará Filistia dé!” Àwọn tí wọ́n sápamọ́ sì wà ninu yàrá inú. Ṣugbọn Samsoni fa okùn náà já bí ẹni pé fọ́nrán òwú kan ni. Delila tún wí fún Samsoni pé, “Sibẹsibẹ o ṣì tún ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà, o tún ń purọ́ fún mi. Sọ fún mi bí eniyan ṣe lè gbé ọ dè.” Ó dá a lóhùn pé, “Bí o bá di ìdì irun meje tí ó wà lórí mi, mọ́ igi òfì, tí o sì dì í papọ̀, yóo rẹ̀ mi, n óo sì dàbí àwọn ọkunrin yòókù.” Nítorí náà, nígbà tí ó sùn, Delila mú ìdì irun mejeeje tí ó wà lórí rẹ̀, ó lọ́ ọ mọ́ igi òfì, ó sì fi èèkàn kàn án mọ́lẹ̀, ó bá pè é, ó ní, “Samsoni! Àwọn Filistini dé.” Ṣugbọn nígbà tí ó jí láti ojú oorun rẹ̀, ó fa èèkàn ati igi òfì náà tu. Delila tún sọ fún un pé, “Báwo ni o ṣe lè wí pé o nífẹ̀ẹ́ mí, nígbà tí ọkàn rẹ kò sí lọ́dọ̀ mi. O ti fi mí ṣe ẹlẹ́yà nígbà mẹta, o kò sì sọ àṣírí agbára ńlá rẹ fún mi.” Nígbà tí Delila bẹ̀rẹ̀ sí yọ ọ́ lẹ́nu lemọ́lemọ́, tí ó sì ń rọ̀ ọ́ lojoojumọ, ọ̀rọ̀ náà sú Samsoni patapata. Ó bá tú gbogbo ọkàn rẹ̀ palẹ̀ fún Delila, ó ní, “Ẹnìkan kò fi abẹ kàn mí lórí rí, nítorí pé Nasiri Ọlọrun ni mí láti inú ìyá mi wá. Bí wọ́n bá fá irun mi, agbára mi yóo fi mí sílẹ̀, yóo rẹ̀ mí n óo sì dàbí àwọn ọkunrin yòókù.” Nígbà tí Delila rí i pé ó ti tú gbogbo ọkàn rẹ̀ palẹ̀ fún òun, ó ranṣẹ pe àwọn ọba Filistini, ó ní, “Ẹ tún wá lẹ́ẹ̀kan sí i, nítorí pé ó ti sọ gbogbo inú rẹ̀ fún mi.” Àwọn ọba Filistini maraarun bá wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n mú owó náà lọ́wọ́. Delila mú kí Samsoni sùn lórí ẹsẹ̀ rẹ̀, ó bá pe ọkunrin kan pé kí ó fá ìdì irun mejeeje tí ó wà ní orí Samsoni. Ó bá bẹ̀rẹ̀ sí jẹ ẹ́ níyà, agbára rẹ̀ sì fi í sílẹ̀. Ó wí fún un pé, “Samsoni! Àwọn ará Filistia ti dé.” Samsoni bá jí láti ojú oorun, ó ní, “N óo lọ bí mo ti máa ń ṣe tẹ́lẹ̀, n óo sì gba ara mi lọ́wọ́ wọn.” Kò mọ̀ pé OLUWA ti fi òun sílẹ̀. Àwọn Filistini bá kì í mọ́lẹ̀, wọ́n yọ ojú rẹ̀, wọ́n mú un wá sí ìlú Gasa, wọ́n sì fi ẹ̀wọ̀n idẹ dè é. Wọ́n ní kí ó máa lọ àgbàdo ninu ilé ẹ̀wọ̀n. Ṣugbọn irun orí rẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ sí kún lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti fá a.

A. Oni 16:4-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, ó sì ní ìfẹ́ obìnrin kan ní Àfonífojì Soreki, orúkọ ẹni tí í ṣe Dẹlila. Àwọn ìjòyè Filistini sì lọ bá obìnrin náà, wọ́n sọ fún un wí pé, “Bí ìwọ bá le tàn án kí òun sì fi àṣírí agbára rẹ̀ hàn ọ́, àti bí àwa ó ti lè borí rẹ̀, kí àwa sì dè é kí àwa sì ṣẹ́gun rẹ̀. Ẹnìkọ̀ọ̀kan nínú wa yóò sì fún ọ ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀fà fàdákà.” Torí náà Dẹlila sọ fún Samsoni pé, “Sọ àṣírí agbára ńlá rẹ fún mi àti bí wọ́n ti le dè ọ́, àti bí wọ́n ṣe lè borí rẹ.” Samsoni dá a lóhùn wí pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá fi okùn tútù méje tí ẹnìkan kò sá gbẹ dè mí, èmi yóò di aláìlágbára bí i gbogbo àwọn ọkùnrin yòókù.” Àwọn olóyè Filistini sì mú okùn tútù méje tí ẹnikẹ́ni kò sá gbẹ wá fún Dẹlila òun sì fi wọ́n dè é. Nígbà tí àwọn ènìyàn tí sápamọ́ sínú yàrá, òun pè pé, “Samsoni àwọn Filistini ti dé láti mú ọ.” Ṣùgbọ́n òun já àwọn okùn náà bí òwú ti í já nígbà tí ó bá wà lẹ́bàá iná. Torí náà wọn kò mọ àṣírí agbára rẹ̀. Dẹlila sì sọ fún Samsoni pé, ìwọ ti tàn mí; o sì purọ́ fún mi. Wá báyìí kí o sì sọ bí a ti ṣe le dè ọ́. Òun dáhùn pé, “Bí wọ́n bá lè fi okùn tuntun tí ẹnikẹ́ni kò tí ì lò rí dì mí dáradára, èmi yóò di aláìlágbára, èmi yóò sì dàbí àwọn ọkùnrin yòókù.” Dẹlila sì mú àwọn okùn tuntun, ó fi wọ́n dì í. Nígbà tí àwọn ọkùnrin Filistini ti fi ara pamọ́ sínú yàrá, òun kígbe sí i pé, “Samsoni àwọn Filistini dé láti mú ọ,” òun sì já okùn náà kúrò ní ọwọ́ rẹ̀ bí òwú. Dẹlila sì tún sọ fún Samsoni pé, “Títí di ìsinsin yìí ìwọ sì ń tún tàn mí, o sì tún purọ́ fún mi. Sọ fún mi ọ̀nà tí wọ́n fi le dè ọ́.” Samsoni dá a lóhùn pé, “Bí ìwọ bá hun ìdí irun méjèèje tí ó wà ní orí mi pẹ̀lú okùn, tí ó sì le dáradára kí o sì fi ẹ̀mú mú un mọ́lẹ̀, èmi yóò di aláìlágbára bí àwọn ọkùnrin yòókù.” Nígbà tí òun ti sùn, Dẹlila hun àwọn ìdí irun méjèèje tí ó wà ní orí rẹ̀, ó sì fi ìhunṣọ dè wọ́n. Ó sì tún pè é pé, “Samsoni àwọn Filistini dé láti mú ọ.” Òun sì jí ní ojú oorun, ó sì fa ìdè ìhunṣọ náà tu pẹ̀lú ohun gbogbo tí wọ́n fi kàn án mọ́lẹ̀. Dẹlila sì sọ fún un pé, “Èéṣe tí ìwọ fi wí pé, ‘Èmi fẹ́ràn rẹ,’ nígbà tí ìwọ kò fi ọkàn tán mi. Èyí ni ìgbà kẹta tí ìwọ ti tàn mí jẹ, tí ìwọ kò sì sọ àṣírí ibi tí agbára ńlá rẹ gbé wà fún mi.” Ó sì ṣe nígbà tí ó fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ rọ̀ ọ́ ní ojoojúmọ́ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ rẹ̀ títí dé bi pé ó sú dé òpin ẹ̀mí rẹ̀. Òun sì sọ ohun gbogbo tí ó wà ní ọkàn rẹ̀ fún un. Ó ní, “Abẹ kò tí ì kan orí mi rí, nítorí pé Nasiri, ẹni ìyàsọ́tọ̀ fún Ọlọ́run ni mo jẹ́ láti ìgbà ìbí mi wá. Bí a bá fá irun orí mi, agbára mi yóò fi mí sílẹ̀, èmi yóò sì di aláìlágbára bí àwọn ọkùnrin yòókù.” Nígbà tí Dẹlila rí i pé ó ti sọ ohun gbogbo fún òun tan, Dẹlila ránṣẹ́ sí àwọn ìjòyè Filistini pé, “Ẹ wá lẹ́ẹ̀kan sí i, ó ti sọ ohun gbogbo fún mi.” Torí náà àwọn olóyè Filistini padà, wọ́n sì mú owó ìpinnu náà lọ́wọ́. Òun sì mú kí Samsoni sùn lórí itan rẹ̀, òun sì pe ọkùnrin kan láti fá àwọn ìdì irun orí rẹ̀ méjèèje, òun sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹ́gun rẹ̀. Agbára rẹ̀ sì fi í sílẹ̀ lọ. Òun pè é wí pé, “Samsoni àwọn Filistini dé láti mú ọ.” Òun jí ní ojú oorun rẹ̀, ó sì sọ pé, “Èmi yóò jáde lọ bí í ti àtẹ̀yìnwá, kí èmi sì gba ara mi, kí n di òmìnira” Ṣùgbọ́n òun kò mọ̀ pé OLúWA ti fi òun sílẹ̀. Nígbà náà ni àwọn Filistini mú un, wọ́n yọ ojú rẹ̀ méjèèjì wọ́n sì mú un lọ sí Gasa. Wọ́n fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ idẹ dè é, wọ́n sì fi sí ibi iṣẹ́ ọlọ lílọ̀ nínú ilé túbú. Ṣùgbọ́n irun orí rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í tún hù lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti fá a.