A. Oni 16:23-31

A. Oni 16:23-31 Bibeli Mimọ (YBCV)

Nigbana ni awọn ijoye Filistini kó ara wọn jọ lati ru ẹbọ nla kan si Dagoni oriṣa wọn, ati lati yọ̀: nitoriti nwọn wipe, Oriṣa wa fi Samsoni ọtá wa lé wa lọwọ. Nigbati awọn enia si ri i, nwọn fi iyin fun oriṣa wọn: nitoriti nwọn wipe, Oriṣa wa fi ọtá wa lé wa lọwọ, ẹniti npa ilẹ wa run, ti o si pa ọ̀pọlọpọ enia ninu wa. O si ṣe, nigbati inu wọn dùn, ni nwọn wipe, Ẹ pè Samsoni, ki o wa ṣiré fun wa. Nwọn si pè Samsoni lati inu ile-itubu wá; o si ṣiré niwaju wọn: nwọn si mu u duro lãrin ọwọ̀n meji. Samsoni si wi fun ọmọkunrin ti o di ọwọ́ rẹ̀ mú pe, Jẹ ki emi ki o fọwọbà awọn ọwọ̀n ti ile joko lé, ki emi ki o le faratì wọn. Njẹ ile na kún fun ọkunrin ati obinrin; gbogbo awọn ijoye Filistini si wà nibẹ̀; awọn ti o si wà lori orule, ati ọkunrin ati obinrin, o to ìwọn ẹgbẹdogun enia, ti nworan Samsoni nigbati o nṣiré. Samsoni si kepè OLUWA, o si wipe, Oluwa ỌLỌRUN, emi bẹ̀ ọ, ranti mi, ki o si jọ̃ fun mi li agbara lẹ̃kanṣoṣo yi, Ọlọrun, ki emi ki o le gbẹsan lẹ̃kan lara awọn Filistini nitori oju mi mejeji. Samsoni si dì ọwọ̀n ãrin mejeji na mú lori eyiti ile na joko, o si faratì wọn, o fi ọwọ́ ọtún rẹ̀ mú kan, o si fi ọwọ́ òsi rẹ̀ mú ekeji. Samsoni si wipe, Jẹ ki nkú pẹlu awọn Filistini. O si fi gbogbo agbara rẹ̀ bẹ̀rẹ; ile na si wó lù awọn ijoye wọnni, ati gbogbo enia ti o wà ninu rẹ̀. Bẹ̃li awọn okú ti o pa ni ikú rẹ̀, pọjù awọn ti o pa li ãyè rẹ̀ lọ. Nigbana li awọn arakunrin rẹ̀ ati gbogbo idile baba rẹ̀ sọkalẹ wá, nwọn si gbé e gòke, nwọn si sin i lãrin Sora on Eṣtaolu ni ibojì Manoa baba rẹ̀. O si ṣe idajọ Israeli li ogún ọdún.

A. Oni 16:23-31 Yoruba Bible (YCE)

Ní ọjọ́ kan, àwọn ọba Filistini kó ara wọn jọ láti rú ẹbọ ńlá kan sí Dagoni, oriṣa wọn, ati láti ṣe àríyá pé oriṣa wọn ni ó fi Samsoni ọ̀tá wọn lé wọn lọ́wọ́. Nígbà tí àwọn eniyan rí i, wọ́n yin oriṣa wọn; wọ́n ní, “Oriṣa wa ti fi ọ̀tá wa lé wa lọ́wọ́, ẹni tí ó sọ ilẹ̀ wa di ahoro tí ó sì pa ọpọlọpọ ninu wa.” Nígbà tí inú wọn dùn, wọ́n ní, “Ẹ pe Samsoni náà wá, kí ó wá dá wa lára yá.” Wọ́n pe Samsoni jáde láti inú ilé ẹ̀wọ̀n, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí dá wọn lára yá. Wọ́n mú un lọ sí ààrin òpó mejeeji pé kí ó dúró níbẹ̀. Samsoni bá bẹ ọdọmọkunrin tí ó mú un lọ́wọ́, ó ní, “Jẹ́ kí n fi ọwọ́ kan àwọn òpó tí gbogbo ilé yìí gbé ara lé kí n lè fara tì wọ́n.” Ilé náà kún fún ọpọlọpọ eniyan, lọkunrin ati lobinrin; gbogbo àwọn ọba ilẹ̀ Filistini ni wọ́n wà níbẹ̀. Lórí òrùlé nìkan, àwọn tí wọ́n wà níbẹ̀ tó ẹgbẹẹdogun (3,000) eniyan, lọkunrin ati lobinrin tí wọn ń wo Samsoni níbi tí ó ti ń dá wọn lára yá. Samsoni bá ké pe OLUWA, ó ní, “OLUWA Ọlọrun, jọ̀wọ́, ranti mi, kí o sì fún mi lágbára lẹ́ẹ̀kan péré sí i, jọ̀wọ́ Ọlọrun mi, kí n lè gbẹ̀san lára àwọn Filistini fún ọ̀kan ninu ojú mi mejeeji.” Samsoni bá gbá àwọn òpó mejeeji tí ó wà láàrin, tí ilé náà gbára lé mú, ó gbé ọwọ́ ọ̀tún lé ọ̀kan, ó gbé ọwọ́ òsì lé ekeji, ó sì fi gbogbo agbára rẹ̀ tì wọ́n. Ó wí pé, “Jẹ́ kí èmi náà kú pẹlu àwọn ará Filistia.” Ó bá bẹ̀rẹ̀ pẹlu gbogbo agbára rẹ̀. Ilé náà sì wó lu gbogbo àwọn ọba Filistini ati gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà ninu rẹ̀. Nítorí náà, iye eniyan tí ó pa nígbà tí òun náà yóo fi kú, ju àwọn tí ó pa nígbà tí ó wà láàyè lọ. Àwọn arakunrin rẹ̀, ati gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀ bá wá gbé òkú rẹ̀, wọ́n lọ sin ín sáàrin Sora ati Eṣitaolu ninu ibojì Manoa, baba rẹ̀. Ogún ọdún ni ó fi ṣe aṣiwaju ní Israẹli.

A. Oni 16:23-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Àwọn ìjòyè, àwọn ará Filistini sì péjọpọ̀ láti ṣe ìrúbọ ńlá sí Dagoni ọlọ́run wọn àti láti ṣe ayẹyẹ wọ́n wí pé, ọlọ́run wa ti fi Samsoni ọ̀tá wa lé wa lọ́wọ́. Nígbà tí àwọn ènìyàn rí Samsoni wọ́n yin ọlọ́run wọn wí pé, “Ọlọ́run wa ti fi ọ̀tá wa lé wa lọ́wọ́. Àní ẹni tí ó ti run ilẹ̀ wa ẹni tí ó ti pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú wa.” Nígbà tí inú wọn dùn gidigidi tí wọ́n ń yọ ayọ̀ ńlá, wọ́n pariwo pé, ẹ mú Samsoni wá kí ó wá dá wa lára yá. Wọ́n sì pe Samsoni jáde láti ọgbà ẹ̀wọ̀n náà, òun sì ń ṣeré fún wọn. Nígbà tí wọ́n mú un dúró láàrín àwọn òpó. Samsoni sọ fún àwọn ìránṣẹ́ tí ó di ọwọ́ rẹ̀ mú pé, “Ẹ fi mí si ibi tí ọwọ́ mi yóò ti le tó àwọn òpó tí ó gbé tẹmpili dúró mú, kí èmi lè fẹ̀yìn tì wọ́n.” Ní àsìkò náà, tẹmpili yìí kún fún àwọn ọkùnrin àti obìnrin; gbogbo àwọn ìjòyè Filistini wà níbẹ̀, ní òkè ilé náà, níbi tí ẹgbẹ̀ẹ́dógún (3,000) àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí ń wòran Samsoni bí òun ti ń ṣeré. Nígbà náà ni Samsoni ké pe OLúWA wí pé, “OLúWA Olódùmarè, rántí mi. Háà Ọlọ́run jọ̀wọ́ fi agbára fún mi lẹ́ẹ̀kan yìí sí i, kí èmi lè gbẹ̀san lára àwọn Filistini nítorí àwọn ojú mi méjèèjì.” Samsoni sì na ọwọ́ mú àwọn òpó méjèèjì tí ó wà láàrín gbùngbùn, orí àwọn tí tẹmpili náà dúró lé, ó fi ọwọ́ ọ̀tún mú ọ̀kan àti ọwọ́ òsì mú èkejì, ó fi ara tì wọ́n, Samsoni sì wí pé, “Jẹ́ kí èmi kú pẹ̀lú àwọn Filistini!” Òun sì fi agbára ńlá tì wọ́n, bẹ́ẹ̀ ni ilé náà wó lu àwọn ìjòyè àti gbogbo àwọn tí ó wà nínú rẹ̀. Báyìí ni ó pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ nígbà ikú rẹ̀ ju ìgbà ayé rẹ̀ lọ. Nígbà náà ni àwọn arákùnrin rẹ̀ àti gbogbo ìdílé baba rẹ̀ ní àpapọ̀ gòkè lọ wọ́n sì gbé e, wọ́n gbé e padà wá, wọ́n sì sin ín sí agbede-méjì Sora àti Eṣtaoli, sínú ibojì Manoa baba rẹ̀. Òun ti ṣe àkóso Israẹli ní ogún (20) ọdún.