A. Oni 11:34-40

A. Oni 11:34-40 Yoruba Bible (YCE)

Jẹfuta bá pada sí ilẹ̀ rẹ̀ nì Misipa, bí ó ti ń wọ̀lú bọ̀, ọmọ rẹ̀ obinrin wá pàdé rẹ̀ pẹlu ìlù ati ijó, ọmọbinrin yìí sì ni ọmọ kan ṣoṣo tí ó bí. Bí ó ti rí i, ó fa aṣọ rẹ̀ ya ó ní, “Ha! Ọmọ mi, ìwọ ni o kó mi sinu ìbànújẹ́ yìí? Ó ṣe wá jẹ́ pé ọ̀rọ̀ tìrẹ ni yóo kó ìbànújẹ́ bá mi? Nítorí pé mo ti jẹ́jẹ̀ẹ́ níwájú OLUWA n kò sì gbọdọ̀ má mú un ṣẹ.” Ọmọbinrin náà dá baba rẹ̀ lóhùn pé, “Baba mi, bí o bá ti jẹ́jẹ̀ẹ́ kan níwájú OLUWA, ṣe sí mi gẹ́gẹ́ bí ẹ̀jẹ́ rẹ níwọ̀n ìgbà tí OLUWA ti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti gbẹ̀san lára àwọn ará Amoni, tí í ṣe ọ̀tá rẹ.” Ó bá bẹ baba rẹ̀, ó ní, “Kinní kan ni mo fẹ́ kí o ṣe fún mi, fi mí sílẹ̀ fún oṣù meji, kí èmi ati àwọn ẹlẹgbẹ́ mi lọ sí orí òkè kí á máa káàkiri, kí á sì máa sọkún, nítorí pé mo níláti kú láì mọ ọkunrin.” Baba rẹ̀ bá ní kí ó máa lọ fún oṣù meji. Òun ati àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ bá lọ sí orí òkè, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọkún, nítorí pé ó níláti kú, láì mọ ọkunrin. Lẹ́yìn oṣù meji, ó pada sọ́dọ̀ baba rẹ̀, baba rẹ̀ sì ṣe bí ó ti jẹ́jẹ̀ẹ́ pé òun yóo ṣe, ọmọbinrin náà kò mọ ọkunrin rí rárá. Ó sì di àṣà ní ilẹ̀ Israẹli, pé kí àwọn ọmọbinrin Israẹli máa lọ láti ṣọ̀fọ̀ ọmọbinrin Jẹfuta, ará Gileadi fún ọjọ́ mẹrin lọdọọdun.

A. Oni 11:34-40 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nígbà tí Jefta padà sí ilé rẹ̀ ní Mispa, wò ó, ọmọ rẹ̀ obìnrin ń jáde bọ̀ wá pàdé rẹ̀ pẹ̀lú timbrili àti ijó. Òun ni ọmọ kan ṣoṣo tí ó ní: kò ní ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin mìíràn yàtọ̀ sí òun nìkan. Ní ìgbà tí ó rí i ó fa aṣọ rẹ̀ ya ní ìbànújẹ́, ó sì ké wí pé, “Háà! Ọ̀dọ́mọbìnrin mi, ìwọ fún mi ní ìbànújẹ́ ọkàn ìwọ sì rẹ̀ mí sílẹ̀ gidigidi, nítorí pé èmi ti ya ẹnu mi sí OLúWA ní ẹ̀jẹ́, èmi kò sì le sẹ́ ẹ̀jẹ́ mi.” Ọmọ náà sì dáhùn pé, “Baba mi bí ìwọ bá ti jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún OLúWA, ṣe sí mi gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ, ní báyìí tí OLúWA ti gba ẹ̀san fún ọ lára àwọn ọ̀tá rẹ, àwọn ará Ammoni. Ṣùgbọ́n yọ̀ǹda ìbéèrè kan yìí fún mi, gbà mí láààyè oṣù méjì láti rìn ká orí àwọn òkè, kí n sọkún pẹ̀lú àwọn ẹlẹgbẹ́ mi torí mo jẹ́ wúńdíá tí n kò sì ní lè ṣe ìgbéyàwó.” Jefta dá lóhùn pé, “Ìwọ lè lọ.” Ó sì gbà á láààyè láti lọ fún oṣù méjì. Òun àti àwọn ọmọbìnrin yòókù lọ sí orí àwọn òkè, wọ́n sọkún nítorí pé kì yóò lè ṣe ìgbéyàwó. Lẹ́yìn oṣù méjì náà, ó padà tọ baba rẹ̀ wá òun sì ṣe sí i bí ẹ̀jẹ́ tí ó ti jẹ́. Ọmọ náà sì jẹ́ wúńdíá tí kò mọ ọkùnrin rí. Èyí sì bẹ̀rẹ̀ àṣà kan ní Israẹli wí pé ní ọjọ́ mẹ́rin láàrín ọdún àwọn obìnrin Israẹli a máa lọ láti ṣọ̀fọ̀ àti ṣe ìrántí ọmọbìnrin Jefta ti Gileadi.