ÀWỌN ADÁJỌ́ 11:34-40

ÀWỌN ADÁJỌ́ 11:34-40 YCE

Jẹfuta bá pada sí ilẹ̀ rẹ̀ nì Misipa, bí ó ti ń wọ̀lú bọ̀, ọmọ rẹ̀ obinrin wá pàdé rẹ̀ pẹlu ìlù ati ijó, ọmọbinrin yìí sì ni ọmọ kan ṣoṣo tí ó bí. Bí ó ti rí i, ó fa aṣọ rẹ̀ ya ó ní, “Ha! Ọmọ mi, ìwọ ni o kó mi sinu ìbànújẹ́ yìí? Ó ṣe wá jẹ́ pé ọ̀rọ̀ tìrẹ ni yóo kó ìbànújẹ́ bá mi? Nítorí pé mo ti jẹ́jẹ̀ẹ́ níwájú OLUWA n kò sì gbọdọ̀ má mú un ṣẹ.” Ọmọbinrin náà dá baba rẹ̀ lóhùn pé, “Baba mi, bí o bá ti jẹ́jẹ̀ẹ́ kan níwájú OLUWA, ṣe sí mi gẹ́gẹ́ bí ẹ̀jẹ́ rẹ níwọ̀n ìgbà tí OLUWA ti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti gbẹ̀san lára àwọn ará Amoni, tí í ṣe ọ̀tá rẹ.” Ó bá bẹ baba rẹ̀, ó ní, “Kinní kan ni mo fẹ́ kí o ṣe fún mi, fi mí sílẹ̀ fún oṣù meji, kí èmi ati àwọn ẹlẹgbẹ́ mi lọ sí orí òkè kí á máa káàkiri, kí á sì máa sọkún, nítorí pé mo níláti kú láì mọ ọkunrin.” Baba rẹ̀ bá ní kí ó máa lọ fún oṣù meji. Òun ati àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ bá lọ sí orí òkè, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọkún, nítorí pé ó níláti kú, láì mọ ọkunrin. Lẹ́yìn oṣù meji, ó pada sọ́dọ̀ baba rẹ̀, baba rẹ̀ sì ṣe bí ó ti jẹ́jẹ̀ẹ́ pé òun yóo ṣe, ọmọbinrin náà kò mọ ọkunrin rí rárá. Ó sì di àṣà ní ilẹ̀ Israẹli, pé kí àwọn ọmọbinrin Israẹli máa lọ láti ṣọ̀fọ̀ ọmọbinrin Jẹfuta, ará Gileadi fún ọjọ́ mẹrin lọdọọdun.