Isa 65:17-19
Isa 65:17-19 Bibeli Mimọ (YBCV)
Sa wò o, emi o da ọrun titun ati aiye titun: a kì yio si ranti awọn ti iṣaju, bẹ̃ni nwọn kì yio wá si aiya. Ṣugbọn ki ẹnyin ki o yọ̀, ki inu nyin ki o si dùn titi lai ninu eyi ti emi o da: nitori kiyesi i, emi o da Jerusalemu ni inudidùn, ati awọn enia rẹ̀ ni ayọ̀. Emi o si ṣe ariya ni Jerusalemu, emi o si yọ̀ ninu awọn enia mi: a kì yio si tun gbọ́ ohùn ẹkún mọ ninu rẹ̀, tabi ohùn igbe.
Isa 65:17-19 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA ní, “Mo dá ọ̀run tuntun, ati ayé tuntun; a kò ní ranti àwọn ohun àtijọ́ mọ́, tabi kí wọn sọ sí eniyan lọ́kàn. Ṣugbọn ẹ jẹ́ kí inú yín ó máa dùn, kí ẹ sì máa yọ títí lae, ninu ohun tí mo dá. Wò ó! Mo dá Jerusalẹmu ní ìlú aláyọ̀, mo sì dá àwọn eniyan inú rẹ̀ ní onínú dídùn. N óo láyọ̀ ninu Jerusalẹmu, inú mi óo sì máa dùn sí àwọn eniyan mi. A kò ní gbọ́ igbe ẹkún ninu rẹ̀ mọ́, ẹnikẹ́ni kò sì ní sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn ninu rẹ̀ mọ́.
Isa 65:17-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Kíyèsi i, Èmi yóò dá àwọn ọ̀run tuntun àti ayé tuntun A kì yóò rántí ohun àtẹ̀yìnwá mọ́, tàbí kí wọn wá sí ọkàn. Ṣùgbọ́n ẹ yọ̀ kí inú yín dùn títí láé nínú ohun tí èmi yóò dá, nítorí èmi yóò dá Jerusalẹmu láti jẹ́ ohun ìdùnnú àti àwọn ènìyàn rẹ̀, ohun ayọ̀. Èmi yóò ṣe àjọyọ̀ lórí Jerusalẹmu n ó sì ní inú dídùn nínú àwọn ènìyàn mi; ariwo ẹkún àti igbe ni a kì yóò gbọ́ nínú rẹ̀ mọ́.