Isa 56:6-7
Isa 56:6-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ati awọn ọmọ alejò ti nwọn dà ara pọ̀ mọ Oluwa, lati sìn i, ati lati fẹ orukọ Oluwa, lati jẹ iranṣẹ rẹ̀, olukuluku ẹniti o pa ọjọ isimi mọ laisọ ọ di aimọ́, ti o si di majẹmu mi mu; Awọn li emi o si mu wá si oke-nla mimọ́ mi, emi o si mu inu wọn dùn, ninu ile adua mi: ẹbọ sisun wọn, ati irubọ wọn, yio jẹ itẹwọgba lori pẹpẹ mi; nitori ile adua li a o ma pe ile mi fun gbogbo enia.
Isa 56:6-7 Yoruba Bible (YCE)
“Àwọn àjèjì tí ó bá darapọ̀ mọ́ OLUWA, tí wọn ń sìn ín, tí wọn fẹ́ràn rẹ̀, tí wọn sì ń ṣe iranṣẹ rẹ̀, gbogbo àwọn tí ó bá pa ọjọ́ ìsinmi mọ́, tí kò sọ ọ́ di ohun ìríra, tí ó sì di majẹmu mi mú gbọningbọnin, n óo mú wọn wá sí orí òkè mímọ́ mi, n óo jẹ́ kí inú wọn máa dùn ninu ilé adura mi. Ọrẹ sísun ati ẹbọ wọn, yóo jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà lórí pẹpẹ mi; nítorí ilé adura fún gbogbo eniyan, ni a óo máa pe ilé mi.”
Isa 56:6-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àti àwọn àjèjì tí ó so ara wọn mọ́ OLúWA láti sìn ín, láti fẹ́ orúkọ OLúWA àti láti foríbalẹ̀ fún un gbogbo àwọn tí ń pa ọjọ́ ìsinmi mọ́ láì bà á jẹ́ àti tí wọ́n sì di májẹ̀mú mi mú ṣinṣin— àwọn wọ̀nyí ni èmi yóò mú wá òkè mímọ́ mi, èmi ó sì fún wọn ní ayọ̀ nínú ilé àdúrà mi. Ẹbọ sísun wọn àti ìrúbọ wọn, ni a ó tẹ́wọ́gbà lórí i pẹpẹ mi; nítorí a ó máa pe ilé mi ní ilé àdúrà fún gbogbo orílẹ̀-èdè.”