AISAYA 56

56
Gbogbo Orílẹ̀-Èdè ni yóo Wà lára Àwọn Eniyan Ọlọrun
1OLUWA ní: “Ẹ máa dá ẹjọ́ ẹ̀tọ́,
kí ẹ sì máa ṣe òdodo;
nítorí ìgbàlà mi yóo dé láìpẹ́,
ẹ óo sì rí ìdáǹdè mi.
2Ayọ̀ ń bẹ fún gbogbo ẹni tí ó bá ń ṣe bẹ́ẹ̀,
ati fún ẹni tí ó bá ń tẹ̀lé e,
tí ó ń ṣọ́ra, tí kò rú òfin ọjọ́ ìsinmi,
tí kò sì fi ọwọ́ rẹ̀ ṣe nǹkan burúkú.”
3Kí àjèjì tí ó faramọ́ OLUWA má sọ pé,
“Dájúdájú OLUWA yóo yà mí kúrò láàrin àwọn eniyan rẹ̀.”
Kí ìwẹ̀fà má sì sọ pé,
“Wò ó! Mo dàbí igi gbígbẹ.”
4Nítorí OLUWA ní,
“Bí ìwẹ̀fà kan bá pa ọjọ́ ìsinmi mi mọ́,
tí ó bá ṣe ohun tí mo fẹ́,
tí ó sì di majẹmu mi mú gbọningbọnin,
5n óo fún wọn ní ipò láàrin àgbàlá mi,
ati ìrántí tí ó dára, ju ọmọkunrin ati ọmọbinrin lọ.
Orúkọ tí kò ní parẹ́ laelae, ni n óo fún wọn.
6“Àwọn àjèjì tí ó bá darapọ̀ mọ́ OLUWA, tí wọn ń sìn ín,
tí wọn fẹ́ràn rẹ̀, tí wọn sì ń ṣe iranṣẹ rẹ̀,
gbogbo àwọn tí ó bá pa ọjọ́ ìsinmi mọ́, tí kò sọ ọ́ di ohun ìríra,
tí ó sì di majẹmu mi mú gbọningbọnin,
7n óo mú wọn wá sí orí òkè mímọ́ mi,
n óo jẹ́ kí inú wọn máa dùn ninu ilé adura mi.
Ọrẹ sísun ati ẹbọ wọn, yóo jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà lórí pẹpẹ mi;
nítorí ilé adura fún gbogbo eniyan, ni a óo máa pe ilé mi.”
8OLUWA Ọlọrun tí ń kó àwọn tí ogun túká ní Israẹli jọ sọ pé,
“N óo tún kó àwọn mìíràn jọ,
kún àwọn tí mo ti kọ́ kó jọ.”
A ti Dá Àwọn Olórí Israẹli lẹ́bi
9Gbogbo ẹ̀yin orílẹ̀-èdè láti òkèèrè, ẹ máa bọ̀,
gbogbo yín ẹ máa bọ̀ bí ẹranko inú ìgbẹ́, ẹ wá jẹ àjẹrun.
10Afọ́jú ni àwọn aṣọ́de Israẹli
gbogbo wọn kò mọ nǹkankan.
Ajá tí ó yadi ni wọ́n,
wọn kò lè gbó;
oorun ni wọ́n fẹ́ràn.
Wọn á dùbúlẹ̀, wọn á máa lá àlá.
11Wọ̀bìà ni wọ́n, alájẹkì,
wọn kì í yó.
Àwọn olùdarí wọn pàápàá kò mọ nǹkankan.
Gbogbo wọn ti tẹ̀ sí ọ̀nà ara wọn,
olukuluku wọn ń wá èrè fún ara rẹ̀.
12Wọn á máa sọ pé: “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á mu waini,
ẹ jẹ́ kí á mu ọtí líle ní àmuyó,
bí òní ṣe rí ni ọ̀la yóo rí, yóo dùn tayọ.”

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

AISAYA 56: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀