Isa 56:1-8

Isa 56:1-8 Bibeli Mimọ (YBCV)

BAYI li Oluwa wi, Ẹ pa idajọ mọ, ẹ si ṣe ododo: nitori igbala mi fẹrẹ idé, ati ododo mi lati fi hàn. Alabukun ni fun ọkunrin na ti o ṣe eyi, ati fun ọmọ enia ti o dì i mu: ti o pa ọjọ isimi mọ laisọ ọ di aimọ́; ti o si pa ọwọ́ rẹ̀ mọ kuro ni ṣiṣe ibi. Ti kò si jẹ ki ọmọ alejò ti o ti dà ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ Oluwa sọ, wipe; Oluwa ti yà mi kuro ninu awọn enia rẹ̀ patapata: bẹ̃ni kò jẹ ki ìwẹ̀fà wipe, Wò o, igi gbigbẹ ni mi. Nitori bayi li Oluwa wi fun awọn ìwẹfa ti nwọn pa ọjọ isimi mi mọ, ti nwọn si yàn eyi ti o wù mi, ti nwọn si di majẹmu mi mu; Pe, emi o fi ipò kan fun wọn ni ile mi, ati ninu odi mi, ati orukọ ti o dara jù ti awọn ọmọkunrin ati ọmọ-obinrin lọ: emi o fi orukọ ainipẹkun fun wọn, ti a kì yio ke kuro. Ati awọn ọmọ alejò ti nwọn dà ara pọ̀ mọ Oluwa, lati sìn i, ati lati fẹ orukọ Oluwa, lati jẹ iranṣẹ rẹ̀, olukuluku ẹniti o pa ọjọ isimi mọ laisọ ọ di aimọ́, ti o si di majẹmu mi mu; Awọn li emi o si mu wá si oke-nla mimọ́ mi, emi o si mu inu wọn dùn, ninu ile adua mi: ẹbọ sisun wọn, ati irubọ wọn, yio jẹ itẹwọgba lori pẹpẹ mi; nitori ile adua li a o ma pe ile mi fun gbogbo enia. Oluwa Jehofah, ẹniti o ṣà àtanu Israeli jọ wipe, Emi o ṣà awọn ẹlomiran jọ sọdọ rẹ̀, pẹlu awọn ti a ti ṣà jọ sọdọ rẹ̀.

Isa 56:1-8 Yoruba Bible (YCE)

OLUWA ní: “Ẹ máa dá ẹjọ́ ẹ̀tọ́, kí ẹ sì máa ṣe òdodo; nítorí ìgbàlà mi yóo dé láìpẹ́, ẹ óo sì rí ìdáǹdè mi. Ayọ̀ ń bẹ fún gbogbo ẹni tí ó bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ati fún ẹni tí ó bá ń tẹ̀lé e, tí ó ń ṣọ́ra, tí kò rú òfin ọjọ́ ìsinmi, tí kò sì fi ọwọ́ rẹ̀ ṣe nǹkan burúkú.” Kí àjèjì tí ó faramọ́ OLUWA má sọ pé, “Dájúdájú OLUWA yóo yà mí kúrò láàrin àwọn eniyan rẹ̀.” Kí ìwẹ̀fà má sì sọ pé, “Wò ó! Mo dàbí igi gbígbẹ.” Nítorí OLUWA ní, “Bí ìwẹ̀fà kan bá pa ọjọ́ ìsinmi mi mọ́, tí ó bá ṣe ohun tí mo fẹ́, tí ó sì di majẹmu mi mú gbọningbọnin, n óo fún wọn ní ipò láàrin àgbàlá mi, ati ìrántí tí ó dára, ju ọmọkunrin ati ọmọbinrin lọ. Orúkọ tí kò ní parẹ́ laelae, ni n óo fún wọn. “Àwọn àjèjì tí ó bá darapọ̀ mọ́ OLUWA, tí wọn ń sìn ín, tí wọn fẹ́ràn rẹ̀, tí wọn sì ń ṣe iranṣẹ rẹ̀, gbogbo àwọn tí ó bá pa ọjọ́ ìsinmi mọ́, tí kò sọ ọ́ di ohun ìríra, tí ó sì di majẹmu mi mú gbọningbọnin, n óo mú wọn wá sí orí òkè mímọ́ mi, n óo jẹ́ kí inú wọn máa dùn ninu ilé adura mi. Ọrẹ sísun ati ẹbọ wọn, yóo jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà lórí pẹpẹ mi; nítorí ilé adura fún gbogbo eniyan, ni a óo máa pe ilé mi.” OLUWA Ọlọrun tí ń kó àwọn tí ogun túká ní Israẹli jọ sọ pé, “N óo tún kó àwọn mìíràn jọ, kún àwọn tí mo ti kọ́ kó jọ.”

Isa 56:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Èyí ni ohun ti OLúWA sọ: “Ẹ pa ìdájọ́ mọ́ ẹ sì ṣe ohun tí ó tọ̀nà, nítorí ìgbàlà mi súnmọ́ tòsí àti òdodo mi ni a ó fihàn láìpẹ́ jọjọ. Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí ó ṣe èyí, àti fún ọmọ ènìyàn tí ó dìímú ṣinṣin, tí ó pa ọjọ́ ìsinmi mọ́ láì bà á jẹ́, tí ó sì pa ọwọ́ rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ibi ṣíṣe.” Má ṣe jẹ́ kí àjèjì kan tí ó ti di ara rẹ̀ mọ́ OLúWA sọ wí pé, “OLúWA yóò yà mí sọ́tọ̀ kúrò nínú àwọn ènìyàn rẹ̀.” Àti kí ìwẹ̀fà kan ṣe àròyé pé, “Igi gbígbẹ lásán ni mí.” Nítorí pé báyìí ni OLúWA wí: “Sí àwọn ìwẹ̀fà yìí tí ó pa ọjọ́ ìsinmi mi mọ́, tí wọ́n yan ohun tí ó dùn mọ́ mi tí wọ́n sì di májẹ̀mú mi mú ṣinṣin fún wọn ni Èmi yóò fún nínú tẹmpili àti àgbàlá rẹ̀ ìrántí kan àti orúkọ kan tí ó sàn ju àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin Èmi yóò fún wọn ní orúkọ ayérayé tí a kì yóò ké kúrò. Àti àwọn àjèjì tí ó so ara wọn mọ́ OLúWA láti sìn ín, láti fẹ́ orúkọ OLúWA àti láti foríbalẹ̀ fún un gbogbo àwọn tí ń pa ọjọ́ ìsinmi mọ́ láì bà á jẹ́ àti tí wọ́n sì di májẹ̀mú mi mú ṣinṣin— àwọn wọ̀nyí ni èmi yóò mú wá òkè mímọ́ mi, èmi ó sì fún wọn ní ayọ̀ nínú ilé àdúrà mi. Ẹbọ sísun wọn àti ìrúbọ wọn, ni a ó tẹ́wọ́gbà lórí i pẹpẹ mi; nítorí a ó máa pe ilé mi ní ilé àdúrà fún gbogbo orílẹ̀-èdè.” OLúWA Olódùmarè sọ wí pé— ẹni tí ó kó àwọn àtìpó Israẹli jọ: “Èmi yóò kó àwọn mìíràn jọ pẹ̀lú wọn yàtọ̀ sí àwọn tí a ti kójọ.”