Isa 54:4-8
Isa 54:4-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
Má bẹ̀ru, nitori oju kì yio tì ọ: bẹ̃ni ki o máṣe dãmu; nitori a ki yio doju tì ọ; nitori iwọ o gbagbe itìju igbà ewe rẹ, iwọ kì yio sì ranti ẹ̀gan iwà-opo rẹ mọ. Nitori Ẹlẹda rẹ li ọkọ rẹ; Oluwa awọn ọmọ-ogun li orukọ rẹ̀; ati Olurapada rẹ Ẹni-Mimọ Israeli; Ọlọrun agbaiye li a o ma pè e. Nitori Oluwa ti pè ọ bi obinrin ti a kọ̀ silẹ, ti a si bà ni inu jẹ, ati bi aya igba ewe nigbati a ti kọ̀ ọ, li Ọlọrun rẹ wi. Ni iṣẹju diẹ ni mo ti kọ̀ ọ silẹ, ṣugbọn li ãnu nla li emi o kó ọ jọ: Ni ṣiṣàn ibinu li emi pa oju mi mọ kuro lara rẹ ni iṣẹju kan! ṣugbọn õre ainipẹkun li emi o fi ṣãnu fun ọ; li Oluwa Olurapada rẹ wí.
Isa 54:4-8 Yoruba Bible (YCE)
Má bẹ̀rù nítorí ojú kò ní tì ọ́, má sì dààmú, nítorí a kì yóo dójú tì ọ́, nítorí o óo gbàgbé ìtìjú ìgbà èwe rẹ, o kò sì ní ranti ẹ̀sín ìgbà tí o jẹ́ opó mọ́. Nítorí Ẹlẹ́dàá rẹ ni ọkọ rẹ, OLUWA àwọn ọmọ ogun ni orúkọ rẹ̀. Ẹni Mímọ́ Israẹli ni Olùràpadà rẹ, Ọlọrun gbogbo ayé ni à ń pè é. Nítorí OLUWA ti pè ọ́, bí iyawo tí ọkọ rẹ̀ kọ̀ sílẹ̀, tí ọkàn rẹ̀ bàjẹ́, àní, bí iyawo àárọ̀ ẹni, tí a kọ̀ sílẹ̀; OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀. Mo kọ̀ ọ́ sílẹ̀ fún ìgbà díẹ̀, ṣugbọn n óo kó ọ jọ pẹlu ọpọlọpọ àánú. Mo fojú mi pamọ́ fún ọ, fún ìgbà díẹ̀ nítorí inú mi ń ru sí ọ, ṣugbọn nítorí ìfẹ́ àìlópin mi, n óo ṣàánú fún ọ. Èmi OLUWA, Olùràpadà rẹ ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
Isa 54:4-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Má ṣe bẹ̀rù, ìtìjú kò ní ṣubú lù ọ́. Má ṣe bẹ̀rù ìdójútì, a kì yóò kàn ọ́ lábùkù. Ìwọ yóò gbàgbé ìtìjú ìgbà èwe e rẹ Ìwọ kì yóò sì rántí ẹ̀gàn ìgba-opo rẹ mọ́. Nítorí Ẹlẹ́dàá rẹ ni ọkọ rẹ OLúWA àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀ Ẹni Mímọ́ Israẹli ni Olùràpadà rẹ; a sì ń pè é ní Ọlọ́run gbogbo ayé. OLúWA yóò pè ọ́ padà àfi bí ẹni pé obìnrin tí a kọ̀sílẹ̀ tí a sì bà lọ́kàn jẹ́ obìnrin tí a fẹ́ ní ọ̀dọ́, tí a sì wá jákulẹ̀” ni OLúWA wí. “Fún ìgbà díẹ̀ ni mo kọ̀ ọ́ sílẹ̀, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ọkàn ìyọ́nú èmi yóò mú ọ padà wá. Ní ríru ìbínú. Mo fi ojú pamọ́ fún ọ fún ìṣẹ́jú kan, ṣùgbọ́n pẹ̀lú àánú àìnípẹ̀kun Èmi yóò ṣíjú àánú wò ọ́,” ni OLúWA Olùdáǹdè rẹ wí.