Isa 54:1-17

Isa 54:1-17 Bibeli Mimọ (YBCV)

KỌRIN, iwọ àgan, ti kò bi ri; bú si orin, si ké rara, iwọ ti kò rọbi ri; nitori awọn ọmọ ẹni-alahoro pọ̀ ju awọn ọmọ ẹniti a gbe ni iyawo: li Oluwa wi. Sọ ibi agọ rẹ di gbigbõro, si jẹ ki wọn nà aṣọ tita ibugbe rẹ̀ jade: máṣe dási, sọ okùn rẹ di gigùn, ki o si mu ẽkàn rẹ le. Nitori iwọ o ya si apa ọtún ati si apa osì, iru-ọmọ rẹ yio si jogun awọn keferi: nwọn o si mu ki awọn ilu ahoro wọnni di ibi gbigbe. Má bẹ̀ru, nitori oju kì yio tì ọ: bẹ̃ni ki o máṣe dãmu; nitori a ki yio doju tì ọ; nitori iwọ o gbagbe itìju igbà ewe rẹ, iwọ kì yio sì ranti ẹ̀gan iwà-opo rẹ mọ. Nitori Ẹlẹda rẹ li ọkọ rẹ; Oluwa awọn ọmọ-ogun li orukọ rẹ̀; ati Olurapada rẹ Ẹni-Mimọ Israeli; Ọlọrun agbaiye li a o ma pè e. Nitori Oluwa ti pè ọ bi obinrin ti a kọ̀ silẹ, ti a si bà ni inu jẹ, ati bi aya igba ewe nigbati a ti kọ̀ ọ, li Ọlọrun rẹ wi. Ni iṣẹju diẹ ni mo ti kọ̀ ọ silẹ, ṣugbọn li ãnu nla li emi o kó ọ jọ: Ni ṣiṣàn ibinu li emi pa oju mi mọ kuro lara rẹ ni iṣẹju kan! ṣugbọn õre ainipẹkun li emi o fi ṣãnu fun ọ; li Oluwa Olurapada rẹ wí. Nitori bi awọn omi Noa li eyi ri si mi, nitori gẹgẹ bi mo ti bura pe omi Noa kì yio bò aiye mọ, bẹ̃ni mo si ti bura pe emi kì yio binu si ọ, bẹ̃ni emi kì yio ba ọ wi. Nitori awọn oke-nla yio ṣi lọ, a o si ṣi awọn oke kékèké ni idi, ṣugbọn ore mi kì yio fi ọ silẹ, bẹ̃ni emi kì yio ṣi majẹmu alafia mi ni ipò: li Oluwa wi, ti o ṣãnu fun ọ. Iwọ ẹniti a npọ́n loju, ti a si nfi ijì gbákiri, ti a kò si tù ninu, wò o, emi o fi tìrõ tẹ́ okuta rẹ, emi o si fi safire fi ipilẹ rẹ le ilẹ. Emi o fi rubi ṣe ṣonṣo-ile rẹ, emi o si fi okuta didán ṣe àsẹ rẹ; emi o si fi awọn okuta àṣayan ṣe agbègbe rẹ. A o si kọ́ gbogbo awọn ọmọ rẹ lati ọdọ Oluwa wá; alafia awọn ọmọ rẹ yio si pọ̀. Ninu ododo li a o fi idi rẹ mulẹ: iwọ o jina si inira; nitori iwọ kì yio bẹ̀ru: ati si ifoiya, nitori kì yio sunmọ ọ. Kiye si i, ni kikojọ nwọn o kó ara wọn jọ, ṣugbọn ki iṣe nipasẹ mi; ẹnikẹni ti o ba ditẹ si ọ yio ṣubu nitori rẹ. Kiye si i, emi li ẹniti o ti dá alagbẹ̀dẹ ti nfẹ́ iná ẹyín, ti o si mu ohun-elò jade fun iṣẹ rẹ̀; emi li o si ti dá apanirun lati panirun. Kò si ohun-ijà ti a ṣe si ọ ti yio lè ṣe nkan; ati gbogbo ahọn ti o dide si ọ ni idajọ ni iwọ o da li ẹbi. Eyi ni ogún awọn iranṣẹ Oluwa, lati ọdọ mi ni ododo wọn ti wá, li Oluwa wi.

Isa 54:1-17 Yoruba Bible (YCE)

Máa kọrin! Ìwọ àgàn tí kò bímọ. Máa kọrin sókè, ìwọ tí kò rọbí rí. Nítorí ọmọ ẹni tí ọkọ ṣátì pọ̀, ju ọmọ ẹni tí ń gbé ilé ọkọ lọ, OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀. Fẹ ààyè àgọ́ rẹ sẹ́yìn, sì jẹ́ kí aṣọ tí ó ta sórí ibùgbé rẹ gbòòrò sí i, má ṣẹ́wọ́ kù. Na okùn àgọ́ rẹ kí ó gùn, kí o sì kan èèkàn rẹ̀ mọ́lẹ̀ kí ó lágbára. Nítorí o óo tàn kálẹ̀, sí apá ọ̀tún ati apá òsì, àwọn ọmọ rẹ yóo gba ìtẹ́ àwọn orílẹ̀-èdè, wọn óo sì máa gbé àwọn ìlú tí ó ti di ahoro. Má bẹ̀rù nítorí ojú kò ní tì ọ́, má sì dààmú, nítorí a kì yóo dójú tì ọ́, nítorí o óo gbàgbé ìtìjú ìgbà èwe rẹ, o kò sì ní ranti ẹ̀sín ìgbà tí o jẹ́ opó mọ́. Nítorí Ẹlẹ́dàá rẹ ni ọkọ rẹ, OLUWA àwọn ọmọ ogun ni orúkọ rẹ̀. Ẹni Mímọ́ Israẹli ni Olùràpadà rẹ, Ọlọrun gbogbo ayé ni à ń pè é. Nítorí OLUWA ti pè ọ́, bí iyawo tí ọkọ rẹ̀ kọ̀ sílẹ̀, tí ọkàn rẹ̀ bàjẹ́, àní, bí iyawo àárọ̀ ẹni, tí a kọ̀ sílẹ̀; OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀. Mo kọ̀ ọ́ sílẹ̀ fún ìgbà díẹ̀, ṣugbọn n óo kó ọ jọ pẹlu ọpọlọpọ àánú. Mo fojú mi pamọ́ fún ọ, fún ìgbà díẹ̀ nítorí inú mi ń ru sí ọ, ṣugbọn nítorí ìfẹ́ àìlópin mi, n óo ṣàánú fún ọ. Èmi OLUWA, Olùràpadà rẹ ni mo sọ bẹ́ẹ̀. Bí ìgbà ayé Noa ni Ọ̀rọ̀ yìí rí sí mi: mo búra nígbà náà, pé omi Noa kò ní bo ayé mọ́lẹ̀ mọ́. Bẹ́ẹ̀ náà ni mo búra nisinsinyii, pé n kò ní bínú sí ọ mọ́, pé n kò ní bá ọ wí mọ́. Bí àwọn òkè ńlá tilẹ̀ ṣí kúrò, tí a sì ṣí àwọn òkè kéékèèké nídìí, ṣugbọn ìfẹ́ mi tí kì í yẹ̀, kò ní yẹ̀ lára rẹ, majẹmu alaafia mi tí mo bá ọ dá kò ní yẹ̀. Èmi OLUWA tí mo ṣàánú fún ọ ni mo sọ bẹ́ẹ̀. OLUWA ní: “Jerusalẹmu, ìwọ ẹni tí a pọ́n lójú, tí hílàhílo bá, tí a kò sì tù ninu, òkúta tí a fi oríṣìíríṣìí ọ̀dà kùn ni n óo fi kọ́ ọ, òkúta safire ni n óo sì fi ṣe ìpìlẹ̀ rẹ. Òkúta Agate ni n óo fi ṣe ṣóńṣó ilé rẹ, òkúta dídán ni n óo fi ṣe ẹnu ọ̀nà ibodè rẹ, àwọn òkúta olówó iyebíye ni n óo fi mọ odi rẹ. “Gbogbo àwọn ọmọ rẹ ọkunrin, ni OLUWA yóo kọ́ wọn yóo sì ṣe ọpọlọpọ àṣeyọrí. A óo fìdí rẹ múlẹ̀, ninu òdodo, o óo jìnnà sí ìnira, nítorí náà ẹ̀rù kò ní bà ọ́. O óo jìnnà sí ìpayà, nítorí kò ní súnmọ́ ọ. Bí ẹnìkan bá dojú ìjà kọ ọ́, kìí ṣe èmi ni mo rán an, ẹnikẹ́ni tó bá gbéjà kò ọ́, yóo ṣubú nítorí rẹ.” OLUWA ní, “Wò ó! Èmi ni mo dá alágbẹ̀dẹ, tí ó fi ẹwìrì fẹ́ná, tí ó sì rọ àwọn ohun ìjà, fún ìlò rẹ̀, èmi náà ni mo dá apanirun, pé kí ó máa panirun. Kò sí ohun ìjà tí a ṣe láti fi bá ọ jà tí yóo lágbára lórí rẹ. Gbogbo ẹni tí ó bá bá ọ rojọ́ nílé ẹjọ́, ni o óo jàre wọn. Èyí ni ìpín àwọn iranṣẹ OLUWA, ati ìdáláre wọn lọ́dọ̀ mi. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Isa 54:1-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

“Kọrin, ìwọ obìnrin àgàn, ìwọ tí kò tí ì bímọ rí; bú sí orin, ẹ hó fún ayọ̀, ẹ̀yin tí kò tí ì rọbí rí; nítorí pé púpọ̀ ni ọmọ àwọn obìnrin ìsọdahoro ju ti ẹni tí ó ní ọkọ,” ni OLúWA wí. Fẹ ibi àgọ́ rẹ lójú sí i, fẹ aṣọ àgọ́ rẹ kí ó gbòòrò sí i, má ṣe dá a dúró; sọ okùn rẹ di gígùn, mú òpó rẹ lágbára sí i. Nítorí ìwọ ó fẹ̀ sọ́tùn àti sí òsì; ìrandíran rẹ yóò jogún àwọn orílẹ̀-èdè, wọn yóò sì dó sí ahoro àwọn ìlú wọn. “Má ṣe bẹ̀rù, ìtìjú kò ní ṣubú lù ọ́. Má ṣe bẹ̀rù ìdójútì, a kì yóò kàn ọ́ lábùkù. Ìwọ yóò gbàgbé ìtìjú ìgbà èwe e rẹ Ìwọ kì yóò sì rántí ẹ̀gàn ìgba-opo rẹ mọ́. Nítorí Ẹlẹ́dàá rẹ ni ọkọ rẹ OLúWA àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀ Ẹni Mímọ́ Israẹli ni Olùràpadà rẹ; a sì ń pè é ní Ọlọ́run gbogbo ayé. OLúWA yóò pè ọ́ padà àfi bí ẹni pé obìnrin tí a kọ̀sílẹ̀ tí a sì bà lọ́kàn jẹ́ obìnrin tí a fẹ́ ní ọ̀dọ́, tí a sì wá jákulẹ̀” ni OLúWA wí. “Fún ìgbà díẹ̀ ni mo kọ̀ ọ́ sílẹ̀, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ọkàn ìyọ́nú èmi yóò mú ọ padà wá. Ní ríru ìbínú. Mo fi ojú pamọ́ fún ọ fún ìṣẹ́jú kan, ṣùgbọ́n pẹ̀lú àánú àìnípẹ̀kun Èmi yóò ṣíjú àánú wò ọ́,” ni OLúWA Olùdáǹdè rẹ wí. “Sí mi, èyí dàbí i àwọn ọjọ́ Noa, nígbà tí mo búra pé àwọn omi Noa kì yóò tún bo ilẹ̀ ayé mọ́. Bẹ́ẹ̀ ni nísinsin yìí mo ti búra láti má ṣe bínú sí ọ, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò bá ọ wí mọ́. Bí a tilẹ̀ mi àwọn òkè ńlá tí a sì ṣí àwọn òkè kékeré nídìí, Síbẹ̀síbẹ̀ ìfẹ́ àìkùnà mi fún ọ kì yóò yẹ̀ láéláé tàbí májẹ̀mú àlàáfíà ni a ó mú kúrò,” ni OLúWA, ẹni tí ó ṣíjú àánú wò ọ́ wí. Ìwọ ìlú tí a pọ́n lójú, tí ìjì ń gbá kiri tí a kò sì tù nínú, Èmi yóò fi òkúta Tikuosi kọ́ ọ àti ìpìlẹ̀ rẹ pẹ̀lú safire. Èmi yóò fi iyùn ṣe odi rẹ, àwọn ẹnu-ọ̀nà ni a ó fi ohun èlò dáradára fún, àti àwọn ògiri rẹ pẹ̀lú òkúta iyebíye. Gbogbo ọ̀dọ́mọkùnrin rẹ ni OLúWA yóò kọ́, àlàáfíà àwọn ọmọ rẹ yóò jẹ́ ńlá àti púpọ̀. Ní òdodo ni a ó fi ìdí rẹ kalẹ̀ ìwà ipá yóò jìnnà sí ọ o kò ní bẹ̀rù ohunkóhun Ìpayà la ó mú kúrò pátápátá; kò ní súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ. Bí ẹnikẹ́ni bá tilẹ̀ bá ọ jà, kò ní jẹ́ láti ọwọ́ mi; ẹnikẹ́ni tí ó bá bá ọ jà ni yóò túúbá fún ọ. “Kíyèsi i, èmi ni ó dá alágbẹ̀dẹ tí ń fẹ́ iná èédú iná tí ó sì ń mú ohun èlò wá tí ó bá iṣẹ́ rẹ mu. Èmi náà sì ni ẹni tí ó dá apanirun láti ṣe iṣẹ́ ibi; Kò sí ohun ìjà tí a ṣe sí ọ tí yóò lè ṣe nǹkan, àti gbogbo ahọ́n tí ó dìde sí ọ ní ìdájọ́ ni ìwọ ó dá ní ẹ̀bi. Èyí ni ogún àwọn ìránṣẹ́ OLúWA, èyí sì ni ìdáláre wọn láti ọ̀dọ̀ mi,” ni OLúWA wí.