Isa 53:7-9
Isa 53:7-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
A jẹ ẹ ni iyà, a si pọ́n ọ loju, ṣugbọn on kò yà ẹnu rẹ̀: a mu u wá bi ọdọ-agutan fun pipa, ati bi agutan ti o yadi niwaju olurẹ́run rẹ̀, bẹ̃ni kò yà ẹnu rẹ̀. A mu u jade lati ibi ihamọ on idajọ: tani o si sọ iran rẹ̀? nitori a ti ke e kuro ni ilẹ alãye: nitori irekọja awọn enia mi li a ṣe lù u. O si ṣe ibojì rẹ̀ pẹlu awọn enia buburu, ati pẹlu ọlọrọ̀ ni ikú rẹ̀; nitori kò hù iwà-ipa, bẹ̃ni kò si arekereke li ẹnu rẹ̀.
Isa 53:7-9 Yoruba Bible (YCE)
Wọ́n ni í lára, wọ́n pọ́n ọn lójú, sibẹsibẹ kò lanu sọ̀rọ̀, wọ́n fà á lọ bí ọ̀dọ́ aguntan tí wọn ń lọ pa, ati bí aguntan tíí yadi níwájú àwọn tí ń rẹ́ irun rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò lanu sọ̀rọ̀. Wọ́n mú un lọ tipátipá, lẹ́yìn tí wọ́n ti dá a lẹ́jọ́, ta ni ninu ìran rẹ̀ tí ó ṣe akiyesi pé wọ́n ti pa á run lórí ilẹ̀ alààyè, ati pé nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan mi, ni wọ́n ṣe nà án? Wọ́n tẹ́ ẹ sí ibojì, pẹlu àwọn eniyan burúkú, wọ́n sì sin ín pẹlu ọlọ́rọ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò ṣe ẹnikẹ́ni níbi, kò sì sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn.
Isa 53:7-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
A jẹ ẹ́ ní yà, a sì pọ́n ọn lójú, síbẹ̀ kò ya ẹnu rẹ̀; a mú un wá gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́-àgùntàn sọ́dọ̀ alápatà, àti gẹ́gẹ́ bí àgùntàn tí ó dákẹ́ níwájú olùrẹ́run rẹ̀, síbẹ̀ kò ya ẹnu rẹ̀. Pẹ̀lú ìpọ́nlójú àti ìdánilẹ́jọ́ ni a mú un jáde lọ, ta ni ó sì le sọ nípa ìrànlọ́wọ́ rẹ̀? Nítorí a ké e kúrò ní ilẹ̀ àwọn alààyè; nítorí àìṣedéédéé àwọn ènìyàn mi ni a ṣe lù ú. A fún un ní ibojì pẹ̀lú àwọn ìkà, àti pẹ̀lú àwọn ọlọ́rọ̀ ní ikú rẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò hùwà jàgídíjàgan kan, tàbí kí a rí ẹ̀tàn kan ní ẹnu rẹ̀.