Isa 53:10-11
Isa 53:10-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn o wu Oluwa lati pa a lara; o ti fi i sinu ibanujẹ; nigbati iwọ o fi ẹmi rẹ̀ ṣẹbọ fun ẹ̀ṣẹ: yio ri iru-ọmọ rẹ̀, yio mu ọjọ rẹ̀ gùn, ifẹ Oluwa yio ṣẹ li ọwọ́ rẹ̀. Yio ri ninu eso lãlã ọkàn rẹ̀, yio si tẹ́ ẹ li ọrùn: nipa imọ̀ rẹ̀ ni iranṣẹ mi olododo yio da ọ̀pọlọpọ lare; nitori yio rù aiṣedede wọn wọnni.
Isa 53:10-11 Yoruba Bible (YCE)
Sibẹsibẹ, ó wu OLUWA láti pa á lára, ó sì fi í sinu ìbànújẹ́, nígbà tí ó fi ara rẹ̀ rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀; yóo fojú rí ọmọ rẹ̀, ọjọ́ rẹ̀ yóo sì gùn. Ìfẹ́ OLUWA yóo ṣẹ lọ́wọ́ rẹ̀. Yóo rí èrè àníyàn ọkàn rẹ̀, yóo sì tẹ́ ẹ lọ́rùn; nípa ìmọ̀ rẹ̀ ni iranṣẹ mi, olódodo, yóo dá ọpọlọpọ eniyan láre, yóo sì ru ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
Isa 53:10-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Síbẹ̀, ó wu OLúWA láti pa á lára àti láti mú kí ó jìyà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé OLúWA fi ayé rẹ̀ fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, Òun yóò rí àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ àti ọjọ́ ayé rẹ̀ yóò pẹ́ títí, àti ète OLúWA ni yóò gbèrú ní ọwọ́ rẹ̀. Lẹ́yìn ìpọ́njú ẹ̀mí rẹ̀, òun yóò rí ìmọ́lẹ̀, ààyè yóò sì tẹ́ ẹ lọ́rùn; nípa ìmọ̀ rẹ̀ ìránṣẹ́ mi olódodo yóò dá ọ̀pọ̀lọpọ̀ láre, Òun ni yóò sì ru àìṣedéédéé wọn.