Isa 52:7-10
Isa 52:7-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹsẹ ẹniti o mu ihinrere wá ti dara to lori awọn oke, ti nkede alafia; ti nmu ihìn rere ohun rere wá, ti nkede igbala; ti o wi fun Sioni pe, Ọlọrun rẹ̀ njọba! Awọn alóre rẹ yio gbe ohùn soke; nwọn o jumọ fi ohùn kọrin: nitori nwọn o ri li ojukoju, nigbati Oluwa ba mu Sioni pada. Bú si ayọ̀, ẹ jumọ kọrin, ẹnyin ibi ahoro Jerusalemu: nitori Oluwa ti tù awọn enia rẹ̀ ninu, o ti rà Jerusalemu pada. Oluwa ti fi apá mimọ́ rẹ̀ hàn li oju gbogbo awọn orilẹ-ède; gbogbo opin aiye yio si ri igbala Ọlọrun wa.
Isa 52:7-10 Yoruba Bible (YCE)
Ẹsẹ̀ ẹni tí ń mú ìyìn rere bọ̀ ti dára tó lórí òkè, ẹni tí ń kéde alaafia, tí ń mú ìyìn rere bọ̀, tí sì ń kéde ìgbàlà, tí ń wí fún Sioni pé, “Ọlọrun rẹ jọba.” Gbọ́, àwọn aṣọ́de rẹ gbóhùn sókè, gbogbo wọn jọ ń kọrin ayọ̀, nítorí wọ́n jọ fi ojú ara wọn rí i, tí OLUWA pada dé sí Sioni. Ẹ jọ máa kọrin pọ̀, gbogbo ilẹ̀ Jerusalẹmu tí a sọ di aṣálẹ̀, nítorí OLUWA yóo tu àwọn eniyan rẹ̀ ninu, yóo ra Jerusalẹmu pada. OLUWA yóo lo agbára mímọ́ rẹ̀, lójú àwọn orílẹ̀-èdè, gbogbo eniyan, títí dé òpin ayé, yóo sì rí ìgbàlà Ọlọrun wa.
Isa 52:7-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Báwo ni ó ṣe dára tó lórí òkè ẹsẹ̀ àwọn tí ó mú ìhìnrere ayọ̀ wá, tí wọ́n kéde àlàáfíà, tí ó mú ìhìnrere wá, tí ó kéde ìgbàlà, tí ó sọ fún Sioni pé, “Ọlọ́run rẹ ń jẹ ọba!” Tẹ́tí sílẹ̀! Àwọn olùṣọ́ rẹ gbé ohùn wọn sókè wọ́n kígbe papọ̀ fún ayọ̀. Nígbà tí OLúWA padà sí Sioni, wọn yóò rí i pẹ̀lú ojú u wọn. Ẹ bú sí orin ayọ̀ papọ̀, ẹ̀yin ahoro Jerusalẹmu, nítorí OLúWA ti tu àwọn ènìyàn rẹ̀ nínú, ó sì ti ra Jerusalẹmu padà. OLúWA yóò ṣí apá mímọ́ rẹ̀ sílẹ̀ ní ojú gbogbo orílẹ̀-èdè, àti gbogbo òpin ilẹ̀ ayé yóò rí ìgbàlà Ọlọ́run wa.