Isa 52

52
Ọlọrun Yóo Gba Jerusalẹmu
1JI! ji! gbe agbara rẹ wọ̀, iwọ Sioni; gbe aṣọ ogo rẹ wọ̀, iwọ Jerusalemu, ilu mimọ́: nitori lati igbayi lọ, alaikọla on alaimọ́ kì yio wọ̀ inu rẹ mọ.
2Gbọ̀n ekuru kuro li ara rẹ, dide, joko, iwọ Jerusalemu: tú ọjá kuro li ọrùn rẹ, iwọ ondè ọmọbinrin Sioni.
3Nitori bayi li Oluwa wi, a ti tà nyin lọfẹ, a o si rà nyin pada laisanwo.
4Nitori bayi li Oluwa Jehofa wi, Awọn enia mi sọkalẹ lọ si Egipti li atijọ lati ṣe atipo nibẹ; ara Assiria si ni wọn lara lainidi.
5Njẹ nisisiyi, Oluwa wipe, Kini mo nṣe nihin, ti a kó awọn enia mi lọ lọfẹ? awọn ti o jọba wọn mu nwọn kigbe, li Oluwa wi; titi lojojumọ li a si nsọ̀rọ odì si orukọ mi.
6Nitorina awọn enia mi yio mọ̀ orukọ mi li ọjọ na: nitori emi li ẹniti nsọrọ: kiyesi i, emi ni.
7Ẹsẹ ẹniti o mu ihinrere wá ti dara to lori awọn oke, ti nkede alafia; ti nmu ihìn rere ohun rere wá, ti nkede igbala; ti o wi fun Sioni pe, Ọlọrun rẹ̀ njọba!
8Awọn alóre rẹ yio gbe ohùn soke; nwọn o jumọ fi ohùn kọrin: nitori nwọn o ri li ojukoju, nigbati Oluwa ba mu Sioni pada.
9Bú si ayọ̀, ẹ jumọ kọrin, ẹnyin ibi ahoro Jerusalemu: nitori Oluwa ti tù awọn enia rẹ̀ ninu, o ti rà Jerusalemu pada.
10Oluwa ti fi apá mimọ́ rẹ̀ hàn li oju gbogbo awọn orilẹ-ède; gbogbo opin aiye yio si ri igbala Ọlọrun wa.
11Ẹ fà sẹhin, é fà sẹhin, é jade kuro lãrin rẹ̀; ẹ má fọwọ kàn ohun aimọ́ kan: ẹ kuro lãrin rẹ̀, ẹ jẹ mimọ́, ẹnyin ti ngbe ohun-èlo Oluwa.
12Nitori ẹ kì yio yara jade, bẹ̃ni ẹ kì yio fi isare lọ; nitori Oluwa yio ṣãju nyin; Ọlọrun Israeli yio si kó nyin jọ.
Iranṣẹ tí Ń Jìyà
13Kiyesi i, iranṣẹ mi yio fi oye bá ni lò; a o gbe e ga, a o si gbe e leke, on o si ga gidigidi.
14Gẹgẹ bi ẹnu rẹ ti yà ọ̀pọlọpọ enia, a bà oju rẹ̀ jẹ ju ti ẹnikẹni lọ, ati irisi rẹ̀ ju ti ọmọ enia lọ.
15Bẹ̃ni yio buwọ́n ọ̀pọlọpọ orilẹ-ède; awọn ọba yio pa ẹnu wọn mọ si i, nitori eyi ti a kò ti sọ fun wọn ni nwọn o ri; ati eyi ti nwọn kò ti gbọ́ ni nwọn o rò.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Isa 52: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa