Isa 51:10-11
Isa 51:10-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
Iwọ kọ́ ha gbẹ okun, omi ibu nla wọnni? ti o ti sọ ibú okun di ọ̀na fun awọn ẹni ìrapada lati gbà kọja? Nitorina awọn ẹni-ìrapada Oluwa yio pada, nwọn o si wá si Sioni ti awọn ti orin; ayọ̀ ainipẹkun yio si wà li ori wọn: nwọn o ri inudidùn ati ayọ̀ gbà; ikãnu ati ọ̀fọ yio fò lọ.
Isa 51:10-11 Yoruba Bible (YCE)
Àbí ìwọ kọ́ ni o mú kí omi òkun gbẹ, omi inú ọ̀gbun ńlá; tí o sọ ilẹ̀ òkun di ọ̀nà, kí àwọn tí o rà pada lè kọjá? Àwọn tí OLUWA rà pada yóo pada wá, pẹlu orin ni wọn óo pada wá sí Sioni. Adé ayọ̀ ni wọn óo dé sórí, wọn óo láyọ̀, inú wọn yóo dùn; ìbànújẹ́ ati ẹ̀dùn wọn yóo sì fò lọ.
Isa 51:10-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ìwọ kọ́ ni ó gbẹ omi Òkun bí àti àwọn omi inú ọ̀gbun, Tí o sì ṣe ọ̀nà nínú ìsàlẹ̀ Òkun tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ẹni ìràpadà yóò fi le là á kọjá? Àwọn ẹni ìràpadà OLúWA yóò padà wá. Wọn yóò wọ Sioni wá pẹ̀lú orin kíkọ; ayọ̀ ayérayé ni yóò sì bo orí wọn. Ayọ̀ àti inú dídùn yóò sì bà lé wọn ìbànújẹ́ àti ìtìjú yóò sì sá kúrò.