AISAYA 51

51
Ọ̀rọ̀ Ìtùnú fún Jerusalẹmu
1“Ẹ gbọ́ ẹ̀yin tí ẹ̀ ń sáré ìdáǹdè,
ẹ̀yin tí ẹ̀ ń wá OLUWA,
ẹ wo àpáta tí a mú lára rẹ̀, tí a fi gbẹ yín,
ati kòtò ibi tí a ti wà yín jáde.
2Ẹ wo Abrahamu baba yín,
ati Sara tí ó bi yín.
Òun nìkan ni nígbà tí mo pè é,
tí mo súre fún un,
tí mo sì sọ ọ́ di ọpọlọpọ eniyan.
3“OLUWA yóo tu Sioni ninu,
yóo tu gbogbo àwọn tí ó ṣòfò ninu rẹ̀ ninu;
yóo sì sọ aṣálẹ̀ rẹ̀ dàbí Edẹni, ọgbà OLUWA.
Ayọ̀ ati ìdùnnú ni yóo máa wà ninu rẹ̀,
pẹlu orin ọpẹ́ ati orin ayọ̀.
4“Ẹ fetí sí mi, ẹ̀yin eniyan mi,
ẹ tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè,
òfin kan yóo ti ọ̀dọ̀ mi jáde,
ìdájọ́ òdodo mi yóo jẹ́ ìmọ́lẹ̀ fún àwọn eniyan.
5Ìdáǹdè mi súnmọ́ tòsí,
ìgbàlà mi sì ti ń yọ bọ̀.
Èmi ni n óo máa ṣe àkóso àwọn eniyan,
àwọn erékùṣù yóo gbẹ́kẹ̀lé mi,
ìrànlọ́wọ́ mi ni wọn yóo sì máa retí.
6Ẹ gbójú sókè, ẹ wo ojú ọ̀run,
kí ẹ sì wo ayé ní ìsàlẹ̀.
Ọ̀run yóo parẹ́ bí èéfín,
ayé yóo gbó bí aṣọ,
àwọn tí ń gbé inú rẹ̀ yóo sì kú bíi kòkòrò;
ṣugbọn títí lae ni ìgbàlà mi,
ìdáǹdè mi kò sì ní lópin.
7“Ẹ̀yin tí ẹ mọ òdodo, ẹ gbọ́ ohùn mi,
ẹ̀yin tí ẹ fi tọkàntọkàn gba òfin mi,
ẹ má bẹ̀rù ẹ̀gàn àwọn eniyan;
ẹ má sì jẹ́ kí yẹ̀yẹ́ wọn já a yín láyà.
8Ikán yóo jẹ wọ́n bí aṣọ,
kòkòrò yóo jẹ wọ́n bí òwú;
ṣugbọn ìdáǹdè mi yóo wà títí lae,
ìgbàlà mi yóo sì wà láti ìran dé ìran.”
9Jí, jí! Dìde, OLUWA, jí pẹlu agbára;
jí bí ìgbà àtijọ́,
bí o ti ṣe sí ìran wa látijọ́.
Ṣebí ìwọ ni o gé Rahabu wẹ́lẹwẹ̀lẹ,
tí o fi idà gún diragoni?
10Àbí ìwọ kọ́ ni o mú kí omi òkun gbẹ,
omi inú ọ̀gbun ńlá;
tí o sọ ilẹ̀ òkun di ọ̀nà,
kí àwọn tí o rà pada lè kọjá?
11Àwọn tí OLUWA rà pada yóo pada wá,
pẹlu orin ni wọn óo pada wá sí Sioni.
Adé ayọ̀ ni wọn óo dé sórí,
wọn óo láyọ̀, inú wọn yóo dùn;
ìbànújẹ́ ati ẹ̀dùn wọn yóo sì fò lọ.
12“Èmi fúnra mi ni mò ń tù ọ́ ninu,
ta ni ọ́, tí o fi ń bẹ̀rù eniyan tí yóo kú?
Ìwọ ń bẹ̀rù ọmọ eniyan tí a dá, bíi koríko.
13O gbàgbé OLUWA ẹlẹ́dàá rẹ,
tí ó ta ojú ọ̀run bí aṣọ,
tí ó fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀.
O wá ń fi gbogbo ọjọ́ ayé bẹ̀rù ibinu àwọn aninilára,
nítorí wọ́n múra tán láti pa ọ́ run?
Ibinu àwọn aninilára kò ní dé ọ̀dọ̀ rẹ mọ́.
14Láìpẹ́, a óo tú àwọn tí a tẹ̀ lórí ba sílẹ̀.
Wọn kò ní kú, wọn kò ní wọ inú isà òkú,
wọn kò sì ní wá oúnjẹ tì.
15“Nítorí èmi ni OLUWA, Ọlọrun rẹ,
ẹni tí ó rú òkun sókè,
tí ìgbì rẹ̀ fi ń pariwo;
OLUWA àwọn ọmọ ogun ni orúkọ mi.
16Mo ti fi ọ̀rọ̀ mi sí ọ lẹ́nu,
mo ti pa ọ́ mọ́ lábẹ́ òjìji ọwọ́ mi.
Èmi ni mo fi ojú ọ̀run sí ipò rẹ̀,
tí mo fi àwọn ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀,
tí mo sì sọ fún ìlú Sioni pé, ‘Ẹ̀yin ni eniyan mi.’ ”
Òpin Ìjìyà Jerusalẹmu
17Jí, jí! Dìde, ìwọ Jerusalẹmu.#Ifi 14:10; 16:19
Ìwọ tí o ti rí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ibinu OLUWA,
ìwọ tí OLUWA ti fi ibinu jẹ níyà,
tí ojú rẹ wá ń pòòyì.
18Kò sí ẹni tí yóo tọ́ ọ sọ́nà,
ninu gbogbo àwọn ọmọ tí o ti bí,
kò sí ẹni tí yóo fà ọ́ lọ́wọ́,
ninu gbogbo ọmọ tí o tọ́ dàgbà.
19Àjálù meji ló dé bá ọ,
ta ni yóo tù ọ́ ninu:
Ìsọdahoro ati ìparun, ìyàn ati ogun,
ta ni yóo tù ọ́ ninu?
20Àárẹ̀ mú àwọn ọmọ rẹ,
wọ́n sùn káàkiri ní gbogbo òpópó,
bí ìgalà tí ó bọ́ sinu àwọ̀n.
Ibinu OLUWA rọ̀jò lé wọn lórí,
àní ìbáwí Ọlọrun rẹ.
21Nítorí náà, ẹ̀yin tí à ń fi ìyà jẹ, ẹ gbọ́ èyí;
ẹ̀yin tí ẹ ti yó láì tíì mu ọtí,
22Oluwa rẹ, àní OLUWA Ọlọrun rẹ, tí ń bẹ̀bẹ̀ fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan rẹ̀ ní,
“Wò ó! Mo ti gba ife àmutagbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n lọ́wọ́ rẹ,
O kò ní rí ibinu mi mọ́.
23Àwọn tí ń dá ọ lóró ni yóo rí ibinu mi,
àwọn tí ó wí fún ọ pé,
‘Bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀ kí á gba orí rẹ kọjá;’
tí wọ́n sọ ẹ̀yìn rẹ di ilẹ̀ẹ́lẹ̀,
tí wọ́n sọ ọ́ di ojú ọ̀nà wọn, tí wọn óo máa gbà kọjá.”

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

AISAYA 51: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀