Isa 48:9-11
Isa 48:9-11 Yoruba Bible (YCE)
“Mo dáwọ́ ibinu mi dúró ná, nítorí orúkọ mi, nítorí ìyìn mi ni mo ṣe dá a dúró fun yín, kí n má baà pa yín run. Mo ti fọ̀ ọ́ mọ́, ṣugbọn kì í ṣe bí a tií fọ fadaka, mo dán yín wò ninu iná ìpọ́njú. Nítorí tèmi, àní nítorí tèmi ni mo ṣe ṣe bẹ́ẹ̀. Nítorí kí ni ìdí rẹ̀ tí orúkọ mi yóo ṣe díbàjẹ́, n kò ní gbé ògo mi fún ẹlòmíràn.
Isa 48:9-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí orúkọ ara mi, mo dáwọ́ ìbínú mi dúró; nítorí ìyìn ara mi, mo fà á sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ rẹ, kí a má ba à ké ọ kúrò. Wò ó, èmi ti tún ọ ṣe, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe bí i fàdákà; Èmi ti dán ọ wò nínú ìléru ìpọ́njú. Nítorí orúkọ mi, nítorí orúkọ mi, mo ṣe èyí Báwo ni mo ṣe lè jẹ́ kí a ba orúkọ mi jẹ́. Èmi kì yóò fi ògo mi fún ẹlòmíràn.
Isa 48:9-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitori orukọ mi emi o mu ibinu mi pẹ, ati nitori iyìn mi, emi o fàsẹhin nitori rẹ, ki emi má ba ké ọ kuro. Wò o, emi ti dà ọ, ṣugbọn ki iṣe bi fadaka; emi ti yan ọ ninu iná ileru wahala. Nitori emi tikalami, ani nitori ti emi tikala mi, li emi o ṣe e, nitori a o ha ṣe bà orukọ mi jẹ? emi kì yio si fi ogo mi fun ẹlomiran.