Isa 48:1-22

Isa 48:1-22 Bibeli Mimọ (YBCV)

GBỌ́ eyi, ẹnyin ile Jakobu, ti a nfi orukọ Israeli pè, ti o si ti inu omi Juda wọnni jade wá, ti o nfi orukọ Oluwa bura, ti o si ndarukọ Ọlọrun Israeli, ṣugbọn ki iṣe li otitọ, tabi li ododo. Nitori nwọn npè ara wọn ni ti ilu mimọ́ nì, nwọn si gbé ara wọn le Ọlọrun Israeli: Oluwa awọn ọmọ-ogun li orukọ rẹ̀. Emi ti sọ nkan ti iṣãju wọnni lati ipilẹṣẹ; nwọn si ti jade lati ẹnu mi lọ, emi si fi wọn hàn; emi ṣe wọn lojijì, nwọn si ti ṣẹ. Nitori emi mọ̀ pe olori-lile ni iwọ, ọrùn rẹ jẹ iṣan irin, iwaju rẹ si jẹ idẹ. Li atetekọṣe ni mo tilẹ ti sọ fun ọ; ki o to de ni emi ti fihàn ọ: ki iwọ má ba wipe, Oriṣa mi li o ṣe wọn, ati ere mi gbigbẹ́, ati ere mi didà li o ti pa wọn li aṣẹ. Iwọ ti gbọ́, wò gbogbo eyi; ẹnyin kì yio ha sọ ọ? Emi ti fi ohun titun hàn ọ lati igba yi lọ, ani nkan ti o pamọ́, iwọ kò si mọ̀ wọn. Nisisiyi li a dá wọn, ki isi ṣe li atetekọṣe; ani ṣaju ọjọ na ti iwọ kò gbọ́ wọn; ki iwọ má ba wipe, Kiyesi i, emi mọ̀ wọn. Lõtọ, iwọ kò gbọ́; lõtọ, iwọ kò mọ̀; lõtọ lati igba na eti rẹ̀ kò ṣi: nitori ti emi mọ̀ pe, iwọ o hùwa arekerekè, gidigidi li a si pè ọ li olurekọja lati inu wá. Nitori orukọ mi emi o mu ibinu mi pẹ, ati nitori iyìn mi, emi o fàsẹhin nitori rẹ, ki emi má ba ké ọ kuro. Wò o, emi ti dà ọ, ṣugbọn ki iṣe bi fadaka; emi ti yan ọ ninu iná ileru wahala. Nitori emi tikalami, ani nitori ti emi tikala mi, li emi o ṣe e, nitori a o ha ṣe bà orukọ mi jẹ? emi kì yio si fi ogo mi fun ẹlomiran. Gbọ́ ti emi, iwọ Jakobu, ati Israeli, ẹni-ipè mi; Emi na ni; emi li ẹni-ikini, ati ẹni-ikẹhin. Ọwọ́ mi pẹlu li o si ti fi ipilẹ aiye sọlẹ, atẹlẹwọ ọ̀tun mi li o si na awọn ọrun: nigbati mo pè wọn, nwọn jumọ dide duro. Gbogbo nyin, ẹ pejọ, ẹ si gbọ́; tani ninu wọn ti o ti sọ nkan wọnyi? Oluwa ti fẹ́ ẹ: yio si ṣe ifẹ rẹ̀ ni Babiloni, apá rẹ̀ yio si wà lara awọn ara Kaldea. Emi, ani emi ti sọ ọ; lõtọ emi ti pè e: emi ti mu u wá, on o si mu ọ̀na rẹ̀ ṣe dẽde. Ẹ sunmọ ọdọ mi, ẹ gbọ́ eyi; lati ipilẹ̀ṣẹ emi kò sọ̀rọ ni ikọ̀kọ; lati igbati o ti wà, nibẹ ni mo wà; ati nisisiyi Oluwa Jehofa, on Ẹmi rẹ̀, li o ti rán mi. Bayi li Oluwa wi, Olurapada rẹ, Ẹni-Mimọ Israeli: Emi li Oluwa Ọlọrun rẹ, ti o kọ́ ọ fun èrè, ẹniti o tọ́ ọ li ọ̀na ti iwọ iba ma lọ. Ibaṣepe iwọ fi eti si ofin mi! nigbana ni alafia rẹ iba dabi odo, ati ododo rẹ bi ìgbi-omi okun. Iru-ọmọ rẹ pẹlu iba dabi iyanrìn, ati ọmọ-bibi inu rẹ bi tãra rẹ̀; a ki ba ti ke orukọ rẹ̀ kuro, bẹ̃ni a kì ba pa a run kuro niwaju mi. Ẹ jade kuro ni Babiloni, ẹ sá kuro lọdọ awọn ara Kaldea, ẹ fi ohùn orin sọ ọ, wi eyi, sọ ọ jade titi de opin aiye; ẹ wipe, Oluwa ti rà Jakobu iranṣẹ rẹ̀ pada. Ongbẹ kò si gbẹ wọn, nigbati o mu wọn là aginjù wọnni ja; o mu omi ṣàn jade lati inu apata fun wọn, o sán apáta pẹlu, omi si tú jade. Alafia kò si fun awọn enia buburu, li Oluwa wi.

Isa 48:1-22 Yoruba Bible (YCE)

Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ẹ̀yin ará ilé Jakọbu, ẹ̀yin tí à ń fi orúkọ Israẹli pè, ọmọ bíbí inú Juda, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń forúkọ OLUWA búra, tí ẹ jẹ́wọ́ Ọlọrun Israẹli, ṣugbọn tí kì í ṣe pẹlu òdodo tabi òtítọ́. Ẹ̀ ń pe ara yín ní ará ìlú mímọ́, ẹ fẹ̀yìn ti Ọlọrun Israẹli, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ OLUWA àwọn ọmọ ogun. OLUWA ní, “Láti ìgbà àtijọ́ ni mo ti kéde, àwọn nǹkan tí yóo ṣẹlẹ̀, èmi ni mo sọ wọ́n jáde, tí mo sì fi wọ́n hàn. Lójijì mo ṣe wọ́n, nǹkan tí mo sọ sì ṣẹ. Nítorí mo mọ̀ pé alágídí ni yín, olóríkunkun sì ni yín pẹlu. Mo ti sọ fun yín láti ọjọ́ pípẹ́: kí wọn tó ṣẹlẹ̀, mo ti kéde wọn fun yín, kí ẹ má baà sọ pé, ‘oriṣa wa ni ó ṣe wọ́n, àwọn ère wa ni ó pàṣẹ pé kí wọn ṣẹlẹ̀.’ “Ẹ ti fetí ara yín gbọ́, nítorí náà, ẹ wo gbogbo èyí, ṣé ẹ kò ní kéde rẹ̀? Láti àkókò yìí lọ, n óo mú kí ẹ máa gbọ́ nǹkan tuntun, àwọn nǹkan tí ó farapamọ́ tí ẹ kò mọ̀. Kò tíì pẹ́ tí a dá wọn, ẹ kò gbọ́ nípa wọn rí, àfi òní. Kí ẹ má baà wí pé: Wò ó, a mọ̀ wọ́n. Ẹ kò gbọ́ ọ rí, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò mọ̀ ọ́n tẹ́lẹ̀. Ọjọ́ ti pẹ́ tí a ti di yín létí, nítorí mo mọ̀ pé ẹ óo hùwà àgàbàgebè, ọlọ̀tẹ̀ ni orúkọ tí mo mọ̀ yín mọ̀, láti ìgbà tí ẹ ti jáde ninu oyún. “Mo dáwọ́ ibinu mi dúró ná, nítorí orúkọ mi, nítorí ìyìn mi ni mo ṣe dá a dúró fun yín, kí n má baà pa yín run. Mo ti fọ̀ ọ́ mọ́, ṣugbọn kì í ṣe bí a tií fọ fadaka, mo dán yín wò ninu iná ìpọ́njú. Nítorí tèmi, àní nítorí tèmi ni mo ṣe ṣe bẹ́ẹ̀. Nítorí kí ni ìdí rẹ̀ tí orúkọ mi yóo ṣe díbàjẹ́, n kò ní gbé ògo mi fún ẹlòmíràn. “Tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ mi ìwọ Jakọbu, ìwọ Israẹli, ẹni tí mo pè, Èmi ni ẹni ìbẹ̀rẹ̀, èmi sì ni ẹni òpin. Ọwọ́ mi ni mo fi fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀, ọwọ́ ọ̀tún mi ni mo fi ta awọsanma sójú ọ̀run. Nígbà tí mo pè wọ́n, gbogbo wọn jọ yọ síta. “Gbogbo yín, ẹ péjọ, kí ẹ gbọ́, èwo ninu wọn ni ó kéde nǹkan wọnyi? OLUWA fẹ́ràn rẹ̀, yóo mú ìfẹ́ inú rẹ̀ ṣẹ lórí Babiloni, yóo sì gbógun ti àwọn ará Kalidea. Èmi, àní èmi pàápàá ni mo sọ̀rọ̀, tí mo pè é, èmi ni mo mú un wá, yóo sì ṣe àṣeyege ninu àdáwọ́lé rẹ̀. Ẹ súnmọ́ mi, kí ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, láti ìbẹ̀rẹ̀ wá, n kò sọ̀rọ̀ ní àṣírí, láti ìgbà tí ọ̀rọ̀ náà ti ṣe ni mo ti wà níbẹ̀.” Nisinsinyii, OLUWA, Ọlọrun, ati Ẹ̀mí rẹ̀ ti rán mi. OLUWA, Olùràpadà rẹ, Ẹni Mímọ́ Israẹli, ní, “Èmi ni OLUWA Ọlọrun rẹ, tí ń kọ́ ọ ní ohun tí yóo ṣe ọ́ ní anfaani, tí ń darí rẹ, sí ọ̀nà tí ó yẹ kí o gbà. “Ìbá jẹ́ pé o ti fetí sí òfin mi, alaafia rẹ ìbá máa ṣàn bí odò, òdodo rẹ ìbá lágbára bi ìgbì omi òkun. Àwọn ọmọ rẹ ìbá pọ̀ bí iyanrìn, arọmọdọmọ rẹ ìbá pọ̀ bí erùpẹ̀ ilẹ̀ tí kò lóǹkà. Orúkọ wọn kì bá tí parẹ́ títí ayé, bẹ́ẹ̀ ni kì bá tí parun lae níwájú mi.” Ẹ jáde kúrò ní Babiloni, ẹ sá kúrò ní Kalidea, ẹ sọ ọ́ pẹlu ayọ̀, ẹ kéde rẹ̀, ẹ máa ròyìn rẹ̀ lọ títí dè òpin ayé, pé “OLUWA ti ra Jakọbu iranṣẹ rẹ̀ pada.” Òùngbẹ kò gbẹ wọ́n, nígbà tí ó mú wọn la inú aṣálẹ̀ kọjá, ó tú omi jáde fún wọn láti inú àpáta, ó la àpáta, omi sì tú jáde. OLUWA sọ pé, “Kò sí alaafia fún àwọn eniyan burúkú.”

Isa 48:1-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

“Tẹ́tí sí èyí, ìwọ ilé e Jakọbu, ìwọ tí a ń pè pẹ̀lú orúkọ Israẹli tí o sì wá láti ẹ̀ka Juda, ìwọ tí ò ń búra ní orúkọ OLúWA tí o sì ń pe Ọlọ́run Israẹli ṣùgbọ́n kì í ṣe ní òtítọ́ àti òdodo Ìwọ tí ò ń pe ara rẹ ní ọmọ ìlú mímọ́ n nì tí o sì gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run Israẹli— OLúWA àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀: Èmi sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn nǹkan ti tẹ́lẹ̀ lọ́jọ́ tó ti pẹ́, ẹnu mi ló ti kéde wọn, mo sì sọ wọ́n di mí mọ̀; Lẹ́yìn náà lójijì mo gbé ìgbésẹ̀, wọ́n sì wá sí ìmúṣẹ. Nítorí mo mọ bí ẹ ti jẹ́ olórí kunkun tó; àwọn iṣan ọrùn un yín irin ni wọ́n; iwájú yín idẹ ni Nítorí náà mo ti sọ nǹkan wọ̀nyí fún ọ ní ọjọ́ tí ó ti pẹ́; kí wọn ó tó ṣẹlẹ̀ mo ti kéde wọn fún un yín tó bẹ́ẹ̀ tí ìwọ kò fi lè sọ pé, ‘Àwọn ère mi ló ṣe wọ́n; àwọn ère igi àti òrìṣà irin ló fọwọ́sí i.’ Ìwọ ti gbọ́ àwọn nǹkan wọ̀nyí; wo gbogbo wọn Ǹjẹ́ o kò nígbà wọ́n bí? “Láti ìsinsin yìí lọ, Èmi yóò máa sọ fún ọ nípa nǹkan tuntun, àwọn nǹkan tí ó fi ara sin tí ìwọ kò mọ̀. A dá wọn ní àkókò yìí kì í ṣe láti ìgbà pípẹ́ ìwọ kò tí ì gbọ́ nípa wọn títí di òní. Nítorí náà, ìwọ kò lè sọ pé, ‘Bẹ́ẹ̀ ni, mo mọ̀ nípa wọn.’ Ìwọ a ha ti gbọ́ tàbí ó ti yé ọ bí láti ìgbà àtijọ́ etí kò ti di yíyà. Ǹjẹ́ mo mọ̀ bí o ti jẹ́ alárékérekè tó; a ń pè ọ́ ní ọlọ̀tẹ̀ láti ìgbà ìbí rẹ. Nítorí orúkọ ara mi, mo dáwọ́ ìbínú mi dúró; nítorí ìyìn ara mi, mo fà á sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ rẹ, kí a má ba à ké ọ kúrò. Wò ó, èmi ti tún ọ ṣe, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe bí i fàdákà; Èmi ti dán ọ wò nínú ìléru ìpọ́njú. Nítorí orúkọ mi, nítorí orúkọ mi, mo ṣe èyí Báwo ni mo ṣe lè jẹ́ kí a ba orúkọ mi jẹ́. Èmi kì yóò fi ògo mi fún ẹlòmíràn. “Tẹ́tí sí mi, ìwọ Jakọbu Israẹli ẹni tí mo pè: Èmi ni ẹni náà; Èmi ni ẹni àkọ́kọ́ àti ẹni ìgbẹ̀yìn. Ọwọ́ mi pàápàá ni ó fi àwọn ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀, àti ọwọ́ ọ̀tún mi ni ó tẹ àwọn ọ̀run; nígbà tí mo pè wọ́n, gbogbo wọn dìde sókè papọ̀. “Gbogbo yín, ẹ péjọ kí ẹ sì gbọ́: Ta nínú wọn ni ó ti sọ nǹkan wọ̀nyí. OLúWA ti fẹ́ ẹ, yóò sì ṣe ìfẹ́ rẹ̀ ní Babiloni, apá rẹ̀ ni yóò sì wà ní ará àwọn ará Kaldea. Èmi, àní Èmi ló ti sọ̀rọ̀; bẹ́ẹ̀ ni, mo ti pè é. Èmi yóò mú un wá, òun yóò sì ṣe àṣeyọrí nínú ìrìnàjò rẹ̀. “Ẹ súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi kí ẹ sì dẹtí sí èyí: “Láti ìgbà ìkéde àkọ́kọ́ èmi kò sọ̀rọ̀ ní ìkọ̀kọ̀; ní àsìkò tí ó sì ṣẹlẹ̀, Èmi wà níbẹ̀.” Àti ní àkókò yìí, OLúWA Olódùmarè ni ó ti rán mi, pẹ̀lú ẹ̀mí rẹ̀. Èyí ni ohun tí OLúWA wí Olùdáǹdè rẹ, Ẹni Mímọ́ Israẹli: “Èmi ni OLúWA Ọlọ́run rẹ, tí ó kọ́ ọ ní ohun tí ó dára fún ọ, tí ó tọ́ ọ ṣọ́nà tí ó yẹ kí o máa rìn. Bí ó bá ṣe pé ìwọ bá ti tẹ́tí sílẹ̀ sí àṣẹ mi, àlàáfíà rẹ kì bá ti dàbí ì ti odò, àti òdodo rẹ bí ìgbì Òkun. Àwọn ọmọ rẹ ìbá ti dàbí iyanrìn, àwọn ọmọ yín bí i hóró ọkà tí a kò lè kà tán; orúkọ wọn ni a kì yóò ké kúrò tàbí kí a pa wọ́n run níwájú mi.” Fi Babeli sílẹ̀, sá fún àwọn ará Babeli, ṣe ìfilọ̀ èyí pẹ̀lú ariwo ayọ̀ kí o sì kéde rẹ̀. Rán an jáde lọ sí òpin ilẹ̀ ayé; wí pé, “OLúWA ti dá ìránṣẹ́ rẹ̀ Jakọbu nídè.” Òrùngbẹ kò gbẹ wọ́n nígbà tí ó kó wọn kọjá nínú aginjù; ó jẹ́ kí omi ó sàn fún wọn láti inú àpáta; ó fọ́ àpáta omi sì tú jáde. “Kò sí àlàáfíà,” ni OLúWA wí, “Fún àwọn ìkà.”