Isa 46:9-10
Isa 46:9-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹ ranti nkan iṣaju atijọ: nitori emi li Ọlọrun, ko si si ẹlomiran, emi li Ọlọrun, ko si si ẹniti o dabi emi. Ẹniti nsọ opin lati ipilẹṣẹ wá, ati nkan ti kò ti iṣe lati igbãni wá, wipe, Imọ mi yio duro, emi o si ṣe gbogbo ifẹ mi.
Isa 46:9-10 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ ranti àwọn nǹkan ti àtijọ́, nítorí pé èmi ni Ọlọrun, kò sí Ọlọrun mìíràn mọ́. Èmi ni Ọlọrun, kò sí ẹni tí ó dà bí mi. Láti ìbẹ̀rẹ̀ ni èmi tíí sọ ohun tí ó gbẹ̀yìn. Láti ìgbà àtijọ́, ni mo tí ń sọ àwọn nǹkan tí kò ì tíì ṣẹlẹ̀. Èmi a máa sọ pé: ‘Àbá mi yóo ṣẹ, n óo sì mú ìpinnu mi ṣẹ.’
Isa 46:9-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Rántí àwọn nǹkan àtẹ̀yìnwá, àwọn ti àtijọ́-tijọ́; Èmi ni Ọlọ́run, kò sì sí ẹlòmíràn; Èmi ni Ọlọ́run, kò sí ẹlòmíràn bí ì mi. Mo fi òpin hàn láti ìbẹ̀rẹ̀ wá, láti àtètèkọ́ṣe, ohun tí ó sì ń bọ̀ wá. Mo wí pé: Ète mi yóò dúró, àti pé èmi yóò ṣe ohun tí ó wù mí.