Isa 42:1-17

Isa 42:1-17 Bibeli Mimọ (YBCV)

WÒ iranṣẹ mi, ẹniti mo gbéro: ayànfẹ mi, ẹniti inu mi dùn si; mo ti fi ẹmi mi fun u: on o mu idajọ wá fun awọn keferi. On kì yio kigbé, bẹ̃ni kì yio gbé ohùn soke, bẹ̃ni kì yio jẹ ki a gbọ́ ohùn rẹ̀ ni igboro. Iyè fifọ́ ni on ki yio ṣẹ, owú ti nrú ẹ̃fin ni on kì yio pa: yio mu idajọ wá si otitọ. Ãrẹ̀ kì yio mú u, a kì yio si daiyà fò o, titi yio fi gbé idajọ kalẹ li aiye, awọn erekùṣu yio duro de ofin rẹ̀. Bayi ni Ọlọrun Oluwa wi, ẹniti o dá ọrun, ti o si nà wọn jade; ẹniti o tẹ̀ aiye, ati ohun ti o ti inu rẹ̀ wá; ẹniti o fi ẽmi fun awọn enia lori rẹ̀, ati ẹmi fun awọn ti o nrin ninu rẹ̀: Emi Oluwa li o ti pè ọ ninu ododo, emi o si di ọwọ́ rẹ mu, emi o si pa ọ mọ, emi o si fi ọ ṣe majẹmu awọn enia, imọlẹ awọn keferi. Lati là oju awọn afọju, lati mu awọn ondè kuro ninu tubu, ati awọn ti o joko li okùnkun kuro ni ile tubu. Emi li Oluwa: eyi ni orukọ mi: ogo mi li emi kì yio fi fun ẹlòmiran, bẹ̃ni emi kì yio fi iyìn mi fun ere gbigbẹ́. Kiyesi i, nkan iṣãju ṣẹ, nkan titun ni emi si nsọ: ki nwọn to hù, mo mu nyin gbọ́ wọn. Ẹ kọ orin titun si Oluwa, iyìn rẹ̀ lati opin aiye, ẹnyin ti nsọkalẹ lọ si okun, ati ohun gbogbo ti mbẹ ninu rẹ̀: erekùṣu, ati awọn ti ngbé inu wọn. Jẹ ki aginjù ati ilu-nla ibẹ gbé ohùn wọn soke, iletò wọnni ti Kedari ngbé: jẹ ki awọn ti ngbé apáta kọrin, jẹ ki wọn hó lati ori oke-nla wá. Jẹ ki wọn fi ogo fun Oluwa, ki wọn si wi iyìn rẹ̀ ninu erekùṣu. Oluwa yio jade bi ọkunrin alagbara, yio rú owú soke bi ologun: yio kigbé, nitõtọ, yio ké ramuramu; yio bori awọn ọta rẹ̀. Lailai ni mo ti dakẹ́: mo ti gbe jẹ, mo ti pa ara mi mọra; nisisiyi emi o ké bi obinrin ti nrọbi; emi o parun, emi o si gbé mì lẹ̃kanna. Emi o sọ oke-nla ati òke-kékèké di ofo, emi o si mú gbogbo ewebẹ̀ wọn gbẹ: emi o sọ odò ṣiṣàn di iyangbẹ́ ilẹ, emi o si mú abàta gbẹ. Emi o si mu awọn afọju bá ọ̀na ti nwọn kò mọ̀ wá; emi o tọ́ wọn ninu ipa ti wọn kò ti mọ̀; emi o sọ okùnkun di imọlẹ niwaju wọn, ati ohun wiwọ́ di titọ. Nkan wọnyi li emi o ṣe fun wọn, emi kì yio si kọ̀ wọn silẹ. A o dá awọn ti o gbẹkẹle ere gbigbẹ́ padà, a o doju tì wọn gidigidi, awọn ti nwi fun ere didà pe, Ẹnyin ni ọlọrun wa.

Isa 42:1-17 Yoruba Bible (YCE)

OLUWA ní, “Wo iranṣẹ mi, ẹni tí mo gbéró, àyànfẹ́ mi, ẹni tí inú mi dùn sí. Mo ti jẹ́ kí ẹ̀mí mi bà lé e, yóo máa dá ẹjọ́ ẹ̀tọ́ fún àwọn orílẹ̀-èdè. Kò ní kígbe, kò sì ní pariwo, kò ní jẹ́ kí á gbọ́ ohùn rẹ̀ ní ìta gbangba. Kò ní ṣẹ́ ọ̀pá ìyè tí ó tẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò ní pa iná fìtílà tí ń jò bẹ́lúbẹ́lú, yóo fi òtítọ́ dá ẹjọ́. Kò ní kùnà, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn rẹ̀ kò ní rẹ̀wẹ̀sì, títí yóo fi fìdí ìdájọ́ òdodo múlẹ̀ láyé. Àwọn erékùṣù ń retí òfin rẹ̀.” Ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA Ọlọrun sọ; ẹni tí ó dá ojú ọ̀run tí ó sì ta á bí aṣọ, tí ó tẹ ayé, ati àwọn ohun tí ń hù jáde láti inú rẹ̀; ẹni tí ó fi èémí sinu àwọn eniyan tí ń gbé orí ilẹ̀; tí ó sì fi ẹ̀mí fún àwọn tí ó ń rìn lórí rẹ̀. Ó ní, “Èmi ni OLUWA, mo ti pè ọ́ ninu òdodo, mo ti di ọwọ́ rẹ mú, mo sì pa ọ́ mọ́. Mo ti fi ọ́ ṣe majẹmu fún aráyé, mo sì fi ọ́ ṣe ìmọ́lẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè; kí o lè la ojú àwọn afọ́jú, kí o lè yọ àwọn ẹlẹ́wọ̀n kúrò ni àhámọ́, kí o lè yọ àwọn tí ó jókòó ninu òkùnkùn kúrò ní ọgbà ẹ̀wọ̀n. “Èmi ni OLUWA, bẹ́ẹ̀ ni orúkọ mi; n kò ní fi ògo mi fún ẹlòmíràn, n kò sì ní fi ìyìn mi fún ère. Wò ó! Àwọn nǹkan àtijọ́ ti kọjá, àwọn nǹkan tuntun ni mò ń kéde nisinsinyii. Kí wọn tó yọjú jáde rárá, ni mo ti sọ fún ọ nípa wọn.” Ẹ kọ orin tuntun sí OLUWA; ẹ kọ orin ìyìn rẹ̀ láti òpin ayé. Ẹ̀yin èrò inú ọkọ̀ lójú agbami òkun, ati gbogbo ohun tí ó wà ninu omi òkun; ati àwọn erékùṣù ati àwọn tí ń gbé inú wọn. Kí aṣálẹ̀ ati àwọn ìlú inú rẹ̀ kọ orin ìyìn sókè, ati àwọn abúlé agbègbè Kedari; kí àwọn ará ìlú Sela kọrin ayọ̀, kí wọn máa kọrin lórí àwọn òkè. Kí wọn fi ògo fún OLUWA, kí wọn kéde ìyìn rẹ̀ ní àwọn erékùṣù. OLUWA yọ jáde lọ bí alágbára ọkunrin, ó ru ibinu rẹ̀ sókè bí ọkunrin ogun, ó kígbe, ó sì bú ramúramù. Ó fihàn pé alágbára ni òun níwájú àwọn ọ̀tá rẹ̀. OLUWA ní: “Ó ti pẹ́ tí mo ti dákẹ́ jẹ́ẹ́, mo dákẹ́ jẹ́ẹ́, mo mára dúró. Ṣugbọn nisinsinyii, n óo kígbe, bí obinrin tí ń rọbí lọ́wọ́. N óo máa mí túpetúpe, n óo máa mí hẹlẹhẹlẹ. N óo sọ àwọn òkè gíga ati àwọn kéékèèké di ilẹ̀, n óo mú kí gbogbo ewéko orí wọn gbẹ; n óo sọ àwọn odò di erékùṣù, n óo sì mú kí àwọn adágún omi gbẹ. “N óo darí àwọn afọ́jú, n óo mú wọn gba ọ̀nà tí wọn kò mọ̀ rí, n óo tọ́ wọn sọ́nà, ní ọ̀nà tí wọn kò mọ̀ rí. N óo sọ òkùnkùn di ìmọ́lẹ̀ níwájú wọn, n óo sì sọ àwọn ibi tí ó rí pálapàla di títẹ́jú. N óo ṣe àwọn nǹkan, n kò sì ní kọ̀ wọ́n sílẹ̀. A óo ká àwọn tí ó gbójú lé ère lọ́wọ́ kò, ojú yóo sì tì wọ́n patapata àwọn tí ń wí fún ère gbígbẹ́ pé: ‘Ẹ̀yin ni Ọlọrun wa.’ ”

Isa 42:1-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

“Ìránṣẹ́ mi nìyìí, ẹni tí mo gbéró, àyànfẹ́ mi nínú ẹni tí mo láyọ̀; Èmi yóò fi Ẹ̀mí mi sínú rẹ̀ òun yóò sì mú ìdájọ́ wá sórí àwọn orílẹ̀-èdè. Òun kì yóò pariwo tàbí kígbe sókè, tàbí kí ó gbóhùn rẹ̀ sókè ní òpópónà. Koríko odò títẹ̀ kan ni òun kì yóò fọ́, àti òwú-fìtílà tí ń jó tan an lọ lòun kì yóò fẹ́ pa. Ní òdodo ni yóò mú ìdájọ́ wá; òun kì yóò kọsẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni kò ní rẹ̀wẹ̀sì títí tí yóò fi fi ìdájọ́ múlẹ̀ ní ayé. Nínú òfin rẹ̀ ni àwọn erékùṣù yóò fi ìrètí wọn sí.” Èyí ni ohun tí OLúWA Ọlọ́run wí Ẹni tí ó dá àwọn ọ̀run tí ó sì tẹ́ wọ́n sóde, tí ó tẹ́ ilẹ̀ ayé àti ohun gbogbo tí ó jáde nínú wọn, Ẹni tí ó fún àwọn ènìyàn rẹ̀ ní èémí àti ẹ̀mí fún gbogbo àwọn tí ń rìn nínú rẹ̀: “Èmi, OLúWA, ti pè ọ́ ní òdodo; Èmi yóò di ọwọ́ rẹ mú. Èmi yóò pa ọ́ mọ́, n ó sì ṣe ọ́ láti jẹ́ májẹ̀mú fún àwọn ènìyàn àti ìmọ́lẹ̀ fún àwọn aláìkọlà láti la àwọn ojú tí ó fọ́, láti tú àwọn òǹdè kúrò nínú túbú àti láti tú sílẹ̀ kúrò nínú ẹ̀wọ̀n àwọn tí ó jókòó nínú òkùnkùn. “Èmi ni OLúWA; orúkọ mi nìyìí! Èmi kì yóò fi ògo mi fún ẹlòmíràn tàbí ìyìn mi fún ère òrìṣà. Kíyèsi i, àwọn nǹkan àtijọ́ ti wáyé, àti àwọn nǹkan tuntun ni mo ti wí pé; kí wọn tó hù jáde mo ti kéde rẹ̀ fún ọ.” OLúWA Kọ orin tuntun sí OLúWA ìyìn rẹ̀ láti òpin ilẹ̀ ayé wá, ẹ̀yin tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ sínú Òkun, àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀ ẹ̀yin erékùṣù, àti gbogbo àwọn tí ń gbé inú wọn. Jẹ́ kí aginjù àti àwọn ìlú rẹ̀ kí ó gbé ohùn wọn sókè; jẹ́ kí ibùdó ti àwọn igi Kedari ń gbé máa yọ̀. Jẹ́ kí àwọn ènìyàn Sela kọrin fún ayọ̀; jẹ́ kí wọn pariwo láti orí òkè. Jẹ́ kí wọn fi ògo fún OLúWA àti kí wọn sì kéde ìyìn rẹ̀ ní erékùṣù. OLúWA yóò rìn jáde gẹ́gẹ́ bí i ọkùnrin alágbára, yóò ru owú sókè bí ológun; yóò kígbe nítòótọ́, òun yóò ké igbe ogun, òun yóò sì ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá rẹ̀. “Fún ìgbà pípẹ́ ni mo ti dákẹ́ jẹ́ẹ́, mo ti wà ní ìdákẹ́ jẹ́ẹ́, mo sì kó ara ró. Ṣùgbọ́n ní àkókò yìí, gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí ó ń rọbí, mo sọkún, mo sì ń mí hẹlẹ hẹlẹ. Èmi yóò sọ òkè ńlá àti kékeré di ahoro tí n ó sì gbẹ gbogbo ewéko rẹ̀ dànù; Èmi yóò sọ àwọn odò di erékùṣù n ó sì gbẹ àwọn adágún. Èmi yóò tọ àwọn afọ́jú ní ọ̀nà tí wọn kò tí ì mọ̀, ní ipa ọ̀nà tí ó ṣàjèjì sí wọn ni èmi yóò tọ́ wọn lọ; Èmi yóò sọ òkùnkùn di ìmọ́lẹ̀ níwájú wọn àti ibi pálapàla ni èmi ó sọ di kíkúnná. Àwọn nǹkan tí máa ṣe nìyìí; Èmi kì yóò kọ̀ wọ́n sílẹ̀. Ṣùgbọ́n àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé òrìṣà, tí wọ́n wí fún ère pé, ‘Ẹ̀yin ni Ọlọ́run wa,’ ni a ó dá padà pẹ̀lú ìtìjú.