Isa 42:1-17

Isa 42:1-17 YBCV

WÒ iranṣẹ mi, ẹniti mo gbéro: ayànfẹ mi, ẹniti inu mi dùn si; mo ti fi ẹmi mi fun u: on o mu idajọ wá fun awọn keferi. On kì yio kigbé, bẹ̃ni kì yio gbé ohùn soke, bẹ̃ni kì yio jẹ ki a gbọ́ ohùn rẹ̀ ni igboro. Iyè fifọ́ ni on ki yio ṣẹ, owú ti nrú ẹ̃fin ni on kì yio pa: yio mu idajọ wá si otitọ. Ãrẹ̀ kì yio mú u, a kì yio si daiyà fò o, titi yio fi gbé idajọ kalẹ li aiye, awọn erekùṣu yio duro de ofin rẹ̀. Bayi ni Ọlọrun Oluwa wi, ẹniti o dá ọrun, ti o si nà wọn jade; ẹniti o tẹ̀ aiye, ati ohun ti o ti inu rẹ̀ wá; ẹniti o fi ẽmi fun awọn enia lori rẹ̀, ati ẹmi fun awọn ti o nrin ninu rẹ̀: Emi Oluwa li o ti pè ọ ninu ododo, emi o si di ọwọ́ rẹ mu, emi o si pa ọ mọ, emi o si fi ọ ṣe majẹmu awọn enia, imọlẹ awọn keferi. Lati là oju awọn afọju, lati mu awọn ondè kuro ninu tubu, ati awọn ti o joko li okùnkun kuro ni ile tubu. Emi li Oluwa: eyi ni orukọ mi: ogo mi li emi kì yio fi fun ẹlòmiran, bẹ̃ni emi kì yio fi iyìn mi fun ere gbigbẹ́. Kiyesi i, nkan iṣãju ṣẹ, nkan titun ni emi si nsọ: ki nwọn to hù, mo mu nyin gbọ́ wọn. Ẹ kọ orin titun si Oluwa, iyìn rẹ̀ lati opin aiye, ẹnyin ti nsọkalẹ lọ si okun, ati ohun gbogbo ti mbẹ ninu rẹ̀: erekùṣu, ati awọn ti ngbé inu wọn. Jẹ ki aginjù ati ilu-nla ibẹ gbé ohùn wọn soke, iletò wọnni ti Kedari ngbé: jẹ ki awọn ti ngbé apáta kọrin, jẹ ki wọn hó lati ori oke-nla wá. Jẹ ki wọn fi ogo fun Oluwa, ki wọn si wi iyìn rẹ̀ ninu erekùṣu. Oluwa yio jade bi ọkunrin alagbara, yio rú owú soke bi ologun: yio kigbé, nitõtọ, yio ké ramuramu; yio bori awọn ọta rẹ̀. Lailai ni mo ti dakẹ́: mo ti gbe jẹ, mo ti pa ara mi mọra; nisisiyi emi o ké bi obinrin ti nrọbi; emi o parun, emi o si gbé mì lẹ̃kanna. Emi o sọ oke-nla ati òke-kékèké di ofo, emi o si mú gbogbo ewebẹ̀ wọn gbẹ: emi o sọ odò ṣiṣàn di iyangbẹ́ ilẹ, emi o si mú abàta gbẹ. Emi o si mu awọn afọju bá ọ̀na ti nwọn kò mọ̀ wá; emi o tọ́ wọn ninu ipa ti wọn kò ti mọ̀; emi o sọ okùnkun di imọlẹ niwaju wọn, ati ohun wiwọ́ di titọ. Nkan wọnyi li emi o ṣe fun wọn, emi kì yio si kọ̀ wọn silẹ. A o dá awọn ti o gbẹkẹle ere gbigbẹ́ padà, a o doju tì wọn gidigidi, awọn ti nwi fun ere didà pe, Ẹnyin ni ọlọrun wa.