Isa 40:6-8
Isa 40:6-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ohùn na wipe, Kigbe. On si wipe, Igbe kini emi o ke? Gbogbo ẹran-ara ni koriko, gbogbo ogo rẹ̀ si dabi ìtànná igbẹ́: Koriko nrọ, ìtànná eweko nrẹ̀: nitoripe ẹmi Oluwa ti fẹ́ lù u: dajudaju koriko ni enia. Koriko nrọ, ìtànná nrẹ̀: ṣugbọn ọ̀rọ Ọlọrun wa yio duro lailai.
Isa 40:6-8 Yoruba Bible (YCE)
Mo gbọ́ ohùn kan tí ń wí pé, “Kígbe!” Mo bá bèèrè pé, “Igbe kí ni kí n ké?” Ó ní, “Kígbe pé, koríko ṣá ni gbogbo eniyan, gbogbo ẹwà sì dàbí òdòdó inú pápá. Koríko a máa rọ, òdòdó a sì máa rẹ̀ nígbà tí OLUWA bá fẹ́ afẹ́fẹ́ lù ú. Dájúdájú koríko ni eniyan. Koríko a máa rọ, òdòdó a sì máa rẹ̀; ṣugbọn ọ̀rọ̀ Ọlọrun wa dúró títí lae.”
Isa 40:6-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ohùn kan wí pé, “Kígbe sókè.” Èmi sì sọ pé, “Igbe kí ni èmi ó ké?” “Gbogbo ènìyàn dàbí i koríko, àti gbogbo ògo wọn dàbí ìtànná igbó. Koríko ń rọ ìtànná sì ń rẹ̀, nítorí èémí OLúWA ń fẹ́ lù wọ́n. Nítòótọ́ koríko ni àwọn ènìyàn. Koríko ń rọ ìtànná sì ń rẹ̀, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wa dúró títí láé.”