Isa 40:26-31
Isa 40:26-31 Bibeli Mimọ (YBCV)
Gbe oju nyin soke sibi giga, ki ẹ si wò, tali o dá nkan wọnyi, ti nmu ogun wọn jade wá ni iye: o npè gbogbo wọn li orukọ nipa titobi ipá rẹ̀, nitoripe on le ni ipá; kò si ọkan ti o kù. Ẽṣe ti iwọ fi nwi, Iwọ Jakobu, ti iwọ si nsọ, Iwọ Israeli pe, Ọ̀na mi pamọ kuro lọdọ Oluwa, idajọ mi si rekọja kuro lọdọ Ọlọrun mi? Iwọ kò ti imọ? iwọ kò ti igbọ́ pe, Ọlọrun aiyeraiye, Oluwa, Ẹlẹda gbogbo ipẹkun aiye, kì iṣãrẹ̀, bẹ̃ni ãrẹ̀ kì imu u? kò si awari oye rẹ̀. O nfi agbara fun alãrẹ̀; o si fi agbara kún awọn ti kò ni ipá. Ani ãrẹ̀ yio mu awọn ọdọmọde, yio si rẹ̀ wọn, ati awọn ọdọmọkunrin yio tilẹ ṣubu patapata: Ṣugbọn awọn ti o ba duro de Oluwa yio tun agbara wọn ṣe; nwọn o fi iyẹ́ gùn oke bi idì; nwọn o sare, kì yio si rẹ̀ wọn; nwọn o rìn, ãrẹ̀ kì yio si mu wọn.
Isa 40:26-31 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ gbójú sókè kí ẹ wo ojú ọ̀run, ta ni ó dá àwọn nǹkan tí ẹ rí wọnyi? Ẹni tí ó kó àwọn ìràwọ̀ sójú ọ̀run bí ọmọ ogun, tí ó ń pè wọ́n jáde lọ́kọ̀ọ̀kan, tí ó sì mọ olukuluku mọ́ orúkọ rẹ̀. Nítorí bí ipá rẹ̀ ti tó, ati bí agbára rẹ̀ ti pọ̀ tó, ẹyọ ọ̀kan ninu wọn kò di àwátì. Kí ló dé, Jakọbu, tí o fi ń rojọ́? Kí ló ṣe ọ́, Israẹli, tí o fi ń sọ pé, “OLUWA kò mọ ohun tí ń ṣe mí, Ọlọrun kò sì bìkítà nípa ẹ̀tọ́ mi.” Ṣé o kò tíì mọ̀, o kò sì tíì gbọ́ pé Ọlọrun ayérayé ni OLUWA, Ẹlẹ́dàá gbogbo ayé. Kì í rẹ̀ ẹ́, bẹ́ẹ̀ ni agara kì í dá a. Àwámárìídìí ni òye rẹ̀. A máa fún aláàárẹ̀ ní okun. A sì máa fún ẹni tí kò lágbára ní agbára. Yóo rẹ àwọn ọ̀dọ́ pàápàá, agara óo sì dá wọn, àwọn ọdọmọkunrin yóo tilẹ̀ ṣubú lulẹ̀ patapata. Ṣugbọn àwọn tí ó bá dúró de OLUWA yóo máa gba agbára kún agbára. Wọn óo máa fi ìyẹ́ fò lọ sókè bí ẹyẹ idì. Wọn óo máa sáré, agara kò ní dá wọn; wọn óo máa rìn, kò sì ní rẹ̀ wọ́n.
Isa 40:26-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Gbé ojú rẹ sókè kí o sì wo àwọn ọ̀run: Ta ni ó dá àwọn wọ̀nyí? Ẹni tí ó mú àkójọpọ̀ àwọn ìràwọ̀ jáde wá ní ọ̀kọ̀ọ̀kan tí ó sì pè wọ́n ní orúkọ lọ́kọ̀ọ̀kan. Nítorí agbára ńlá àti ipá rẹ̀, ọ̀kan ṣoṣo nínú wọn kò sọnù. Èéṣe tí o fi sọ, ìwọ Jakọbu àti tí o ṣàròyé, ìwọ Israẹli; “Ọ̀nà mi pamọ́ níwájú OLúWA; ìṣe mi ni a kò kọbi ara sí láti ọwọ́ Ọlọ́run mi”? Ìwọ kò tí ì mọ̀? Ìwọ kò tí ì gbọ́? OLúWA òun ni Ọlọ́run ayérayé, Ẹlẹ́dàá gbogbo ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé. Agara kì yóò da bẹ́ẹ̀ ni kò ní ṣàárẹ̀, àti òye rẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò le ṣe òdínwọ̀n rẹ̀. Ó ń fi agbára fún àwọn aláàárẹ̀ ó sì fi kún agbára àwọn tí agara dá. Àní, ó ń rẹ̀ wọ́n àwọn ọ̀dọ́, wọ́n ń rẹ̀wẹ̀sì, àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin sì ń kọsẹ̀ wọ́n ṣubú; ṣùgbọ́n àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé OLúWA yóò sọ agbára wọn di ọ̀tun. Wọn yóò fìyẹ́ fò lókè bí idì; wọn yóò sáré àárẹ̀ kò ní mú wọn, wọn yóò rìn òòyì kò ní kọ́ wọn.