Isa 40:1-5
Isa 40:1-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹ tù enia mi ninu, ẹ tù wọn ninu, ni Ọlọrun nyin wi. Ẹ sọ ọ̀rọ ìtunu fun Jerusalemu, ki ẹ si ké si i pe, ogun jijà rẹ tán, pe, a dari aiṣedẽde rẹ jì: nitoripe o ti gbà nigba meji lati ọwọ́ Oluwa wá fun ẹ̀ṣẹ rẹ̀ gbogbo. Ohùn ẹniti nkigbe ni ijù, ẹ tún ọ̀na Oluwa ṣe, ṣe opópo titọ́ ni aginjù fun Ọlọrun wa. Gbogbo afonifoji ni a o gbe soke, gbogbo òke-nla ati òke kékèké ni a o si rẹ̀ silẹ: wiwọ́ ni a o si ṣe ni titọ́, ati ọ̀na pàlapala ni a o sọ di titẹ́ju: A o si fi ogo Oluwa hàn, gbogbo ẹran-ara ni yio jùmọ ri i: nitori ẹnu Oluwa li o sọ ọ.
Isa 40:1-5 Yoruba Bible (YCE)
Ọlọrun yín ní, “Ẹ tù wọ́n ninu, ẹ tu àwọn eniyan mi ninu. Ẹ bá Jerusalẹmu sọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ ẹ ké sí i pé, ogun jíjà rẹ̀ ti parí, a ti dárí àìṣedéédé rẹ̀ jì í. OLUWA ti jẹ ẹ́ níyà ní ìlọ́po meji nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.” Ẹ gbọ́ ohùn akéde kan tí ń wí pé, “Ẹ tún ọ̀nà OLUWA ṣe ninu aginjù, ẹ la òpópónà títọ́ fún Ọlọrun wa ninu aṣálẹ̀. Gbogbo àfonífojì ni a óo ru sókè, a óo sì sọ àwọn òkè ńlá ati òkè kéékèèké di pẹ̀tẹ́lẹ̀: Gbogbo ọ̀nà tí ó wọ́ ni yóo di títọ́, ọ̀nà gbágun-gbàgun yóo sì di títẹ́jú. Ògo OLUWA yóo farahàn, gbogbo eniyan yóo sì jọ fojú rí i. OLUWA ni ó fi ẹnu ara rẹ̀ sọ bẹ́ẹ̀.”
Isa 40:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹ tù ú nínú, ẹ tu ènìyàn mi nínú, ni Ọlọ́run yín wí. Sọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ fún Jerusalẹmu kí o sì kéde fún un pé iṣẹ́ àṣekára rẹ̀ ti parí, pé à ti san gbèsè ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, pé ó ti rí i gbà láti ọwọ́ OLúWA ìlọ́po méjì fún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Ohùn ẹni tí ń kígbe ní ijù: “Ẹ tún ọ̀nà OLúWA ṣe, ṣe òpópó tí ó tọ́ ní aginjù fún Ọlọ́run wa. Gbogbo Àfonífojì ni a ó gbé sókè, gbogbo òkè ńlá àti òkè kékeré ni yóò di pẹ̀tẹ́lẹ̀; wíwọ́ ni a ó sọ di títọ́ àti ọ̀nà pálapàla ni a óò sọ di títẹ́jú pẹrẹsẹ, Ògo OLúWA yóò sì di mí mọ̀ gbogbo ènìyàn lápapọ̀ ni yóò sì rí i. Nítorí ẹnu OLúWA ni ó ti sọ ọ́.”