Isa 40:1-11

Isa 40:1-11 Bibeli Mimọ (YBCV)

Ẹ tù enia mi ninu, ẹ tù wọn ninu, ni Ọlọrun nyin wi. Ẹ sọ ọ̀rọ ìtunu fun Jerusalemu, ki ẹ si ké si i pe, ogun jijà rẹ tán, pe, a dari aiṣedẽde rẹ jì: nitoripe o ti gbà nigba meji lati ọwọ́ Oluwa wá fun ẹ̀ṣẹ rẹ̀ gbogbo. Ohùn ẹniti nkigbe ni ijù, ẹ tún ọ̀na Oluwa ṣe, ṣe opópo titọ́ ni aginjù fun Ọlọrun wa. Gbogbo afonifoji ni a o gbe soke, gbogbo òke-nla ati òke kékèké ni a o si rẹ̀ silẹ: wiwọ́ ni a o si ṣe ni titọ́, ati ọ̀na pàlapala ni a o sọ di titẹ́ju: A o si fi ogo Oluwa hàn, gbogbo ẹran-ara ni yio jùmọ ri i: nitori ẹnu Oluwa li o sọ ọ. Ohùn na wipe, Kigbe. On si wipe, Igbe kini emi o ke? Gbogbo ẹran-ara ni koriko, gbogbo ogo rẹ̀ si dabi ìtànná igbẹ́: Koriko nrọ, ìtànná eweko nrẹ̀: nitoripe ẹmi Oluwa ti fẹ́ lù u: dajudaju koriko ni enia. Koriko nrọ, ìtànná nrẹ̀: ṣugbọn ọ̀rọ Ọlọrun wa yio duro lailai. Iwọ onihinrere Sioni, gùn òke giga lọ: Iwọ onihin-rere Jerusalemu, gbé ohùn rẹ soke pẹlu agbara; gbé e soke, má bẹ̀ru; wi fun awọn ilu Juda pe, Ẹ wò Ọlọrun nyin! Kiyesi i, Oluwa Jehofah yio wá ninu agbara, apá rẹ̀ yio ṣe akoso fun u: kiyesi i, ère rẹ̀ wà pẹlu rẹ̀, ẹ̀san rẹ̀ si mbẹ niwaju rẹ̀. On o bọ́ ọwọ-ẹran rẹ̀ bi oluṣọ-agùtan: yio si fi apá rẹ̀ ko awọn ọdọ-agùtan, yio si kó wọn si aiya rẹ̀, yio si rọra dà awọn ti o loyun.

Isa 40:1-11 Yoruba Bible (YCE)

Ọlọrun yín ní, “Ẹ tù wọ́n ninu, ẹ tu àwọn eniyan mi ninu. Ẹ bá Jerusalẹmu sọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ ẹ ké sí i pé, ogun jíjà rẹ̀ ti parí, a ti dárí àìṣedéédé rẹ̀ jì í. OLUWA ti jẹ ẹ́ níyà ní ìlọ́po meji nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.” Ẹ gbọ́ ohùn akéde kan tí ń wí pé, “Ẹ tún ọ̀nà OLUWA ṣe ninu aginjù, ẹ la òpópónà títọ́ fún Ọlọrun wa ninu aṣálẹ̀. Gbogbo àfonífojì ni a óo ru sókè, a óo sì sọ àwọn òkè ńlá ati òkè kéékèèké di pẹ̀tẹ́lẹ̀: Gbogbo ọ̀nà tí ó wọ́ ni yóo di títọ́, ọ̀nà gbágun-gbàgun yóo sì di títẹ́jú. Ògo OLUWA yóo farahàn, gbogbo eniyan yóo sì jọ fojú rí i. OLUWA ni ó fi ẹnu ara rẹ̀ sọ bẹ́ẹ̀.” Mo gbọ́ ohùn kan tí ń wí pé, “Kígbe!” Mo bá bèèrè pé, “Igbe kí ni kí n ké?” Ó ní, “Kígbe pé, koríko ṣá ni gbogbo eniyan, gbogbo ẹwà sì dàbí òdòdó inú pápá. Koríko a máa rọ, òdòdó a sì máa rẹ̀ nígbà tí OLUWA bá fẹ́ afẹ́fẹ́ lù ú. Dájúdájú koríko ni eniyan. Koríko a máa rọ, òdòdó a sì máa rẹ̀; ṣugbọn ọ̀rọ̀ Ọlọrun wa dúró títí lae.” Gun orí òkè gíga lọ, ìwọ Sioni, kí o máa kéde ìyìn rere. Gbé ohùn rẹ sókè pẹlu agbára Jerusalẹmu, ìwọ tí ò ń kéde ìyìn rere ké sókè má ṣe bẹ̀rù; sọ fún àwọn ìlú Juda pé, “Ẹ wo Ọlọrun yín.” Ẹ wò ó! OLUWA Ọlọrun ń bọ̀ pẹlu agbára ipá rẹ̀ ni yóo fi máa ṣe àkóso. Ẹ wò ó! Èrè rẹ̀ ń bẹ lọ́wọ́ rẹ̀, ẹ̀san rẹ̀ sì ń bẹ níwájú rẹ̀. Yóo bọ́ agbo ẹran bí olùṣọ́-aguntan. Yóo kó àwọn ọ̀dọ́ aguntan jọ sí apá rẹ̀, yóo gbé wọn mọ́ àyà rẹ̀. Yóo sì máa fi sùúrù da àwọn tí wọn lọ́mọ lẹ́yìn láàrin wọn.

Isa 40:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ẹ tù ú nínú, ẹ tu ènìyàn mi nínú, ni Ọlọ́run yín wí. Sọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ fún Jerusalẹmu kí o sì kéde fún un pé iṣẹ́ àṣekára rẹ̀ ti parí, pé à ti san gbèsè ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, pé ó ti rí i gbà láti ọwọ́ OLúWA ìlọ́po méjì fún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Ohùn ẹni tí ń kígbe ní ijù: “Ẹ tún ọ̀nà OLúWA ṣe, ṣe òpópó tí ó tọ́ ní aginjù fún Ọlọ́run wa. Gbogbo Àfonífojì ni a ó gbé sókè, gbogbo òkè ńlá àti òkè kékeré ni yóò di pẹ̀tẹ́lẹ̀; wíwọ́ ni a ó sọ di títọ́ àti ọ̀nà pálapàla ni a óò sọ di títẹ́jú pẹrẹsẹ, Ògo OLúWA yóò sì di mí mọ̀ gbogbo ènìyàn lápapọ̀ ni yóò sì rí i. Nítorí ẹnu OLúWA ni ó ti sọ ọ́.” Ohùn kan wí pé, “Kígbe sókè.” Èmi sì sọ pé, “Igbe kí ni èmi ó ké?” “Gbogbo ènìyàn dàbí i koríko, àti gbogbo ògo wọn dàbí ìtànná igbó. Koríko ń rọ ìtànná sì ń rẹ̀, nítorí èémí OLúWA ń fẹ́ lù wọ́n. Nítòótọ́ koríko ni àwọn ènìyàn. Koríko ń rọ ìtànná sì ń rẹ̀, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wa dúró títí láé.” Ìwọ tí o mú ìyìn ayọ̀ wá sí Sioni, lọ sí orí òkè gíga. Ìwọ tí ó mú ìyìn ayọ̀ wá sí Jerusalẹmu, gbé ohùn rẹ sókè pẹ̀lú ariwo, gbé e sókè, má ṣe bẹ̀rù; sọ fún àwọn ìlú u Juda, “Ọlọ́run rẹ nìyìí!” Wò ó, OLúWA Olódùmarè náà ń bọ̀ wá pẹ̀lú agbára, apá rẹ̀ sì ń jẹ ọba fún un. Wò ó, èrè rẹ̀ sì wà pẹ̀lú rẹ̀, àti ìdápadà rẹ̀ tí ń bá a bọ̀ wá. Ó ń tọ́ àwọn agbo rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́-àgùntàn: Ó kó àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn ní apá rẹ̀. Ó sì gbé wọn súnmọ́ oókan àyà rẹ̀; ó sì fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ darí àwọn tí ó ní.

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa