Isa 30:15-22

Isa 30:15-22 Yoruba Bible (YCE)

Nítorí OLUWA Ọlọrun, Ẹni Mímọ́ Israẹli ní: “Bí ẹ bá yipada, tí ẹ sì farabalẹ̀, ẹ óo rí ìgbàlà; bí ẹ bá dákẹ́ jẹ́ẹ́ tí ẹ sì gbẹ́kẹ̀lé Ọlọrun, ẹ óo lágbára. Ṣugbọn ẹ kọ̀. Ẹ sọ pé ó tì o, ẹ̀yin óo gun ẹṣin sálọ ni. Nítorí náà sísá ni ẹ óo sálọ. Ẹ sọ pé ẹṣin tí ó lè sáré ni ẹ óo gùn. Nítorí náà àwọn tí yóo máa le yín, wọn óo lè sáré gan-an ni. Ẹgbẹrun ninu yín yóo sá fún ẹyọ ọ̀tá yín kan, gbogbo yín yóo sì sá fún ẹyọ eniyan marun-un títí tí àwọn tí yóo kú ninu yín yóo fi dàbí igi àsíá lórí òkè. Wọn óo dàbí àsíá ati àmì lórí òkè.” Nítorí náà OLUWA ń dúró dè yín, ó ti ṣetán láti ṣàánú yín. Yóo dìde, yóo sì ràn yín lọ́wọ́. Nítorí Ọlọrun Olódodo ni OLUWA. Ẹ̀yin ará Sioni tí ẹ̀ ń gbé Jerusalẹmu, ẹ kò ní sọkún mọ́. OLUWA yóo ṣàánú yín nígbà tí ẹ bá ké pè é, yóo sì da yín lóhùn nígbà tí ó bá gbọ́ igbe yín. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé OLUWA yóo jẹ́ kí ẹ ní ọpọlọpọ ìṣòro, yóo sì jẹ́ kí ẹ ṣe ọpọlọpọ wahala, sibẹsibẹ olùkọ́ yín kò ní farapamọ́ fun yín mọ́, ṣugbọn ẹ óo máa fi ojú yín rí i. Bí ẹ bá fẹ́ yapa sí apá ọ̀tún tabi apá òsì, ẹ óo máa gbọ́ ohùn kan lẹ́yìn yín tí yóo máa wí pé, “Ọ̀nà nìyí, ibí ni kí ẹ gbà.” Àwọn oriṣa tí ẹ yọ́ fadaka bò, ati àwọn ère tí ẹ yọ́ wúrà bò yóo di nǹkan èérí lójú yín. Ẹ óo kọ̀ wọ́n sílẹ̀ bí nǹkan aláìmọ́. Ẹ óo sì wí fún wọn pé, “Ẹ pòórá!”

Isa 30:15-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Èyí ni ohun tí OLúWA Olódùmarè, Ẹni Mímọ́ ti Israẹli wí: “Nínú ìrònúpìwàdà àti ìsinmi ni ìgbàlà rẹ wà, ní ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé ni agbára rẹ wà, ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò ní ọ̀kankan nínú wọn. Ẹ̀yin wí pé, ‘bẹ́ẹ̀ kọ́, àwa yóò sálọ lórí ẹṣin.’ Nítorí náà ẹ̀yin yóò sá! Ẹ̀yin wí pé, ‘Àwa yóò gun àwọn ẹṣin tí ó yára lọ.’ Nítorí náà àwọn tí ń lé e yín yóò yára! Ẹgbẹ̀rún yóò sá nípa ìdẹ́rùbà ẹnìkan; nípa ìdẹ́rùbà ẹni márùn-ún gbogbo yín lẹ ó sálọ, títí a ó fi yín sílẹ̀ àti gẹ́gẹ́ bí igi àsíá ní orí òkè, gẹ́gẹ́ bí àsíá lórí òkè.” Síbẹ̀síbẹ̀ OLúWA sì fẹ́ ṣíjú àánú wò ọ́; ó dìde láti ṣàánú fún ọ. Nítorí OLúWA jẹ́ Ọlọ́run ìdájọ́. Ìbùkún ni fún gbogbo àwọn tí ó dúró dè é! Ẹ̀yin ènìyàn Sioni, tí ń gbé ní Jerusalẹmu, ìwọ kì yóò sọkún mọ́. Báwo ni àánú rẹ̀ yóò ti pọ̀ tó nígbà tí ìwọ bá kígbe fún ìrànlọ́wọ́! Bí ó bá ti gbọ́, òun yóò dá ọ lóhùn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Olúwa fún ọ ní àkàrà ìyà àti omi ìpọ́njú, àwọn olùkọ́ rẹ kì yóò fi ara sin mọ́; pẹ̀lú ojú rẹ ni ìwọ ó rí wọn. Bí o bá yí sápá ọ̀tún tàbí apá òsì, etí rẹ yóò máa gbọ́ ohùn kan lẹ́yìn rẹ, wí pé, “Ọ̀nà nìyìí, máa rìn nínú rẹ̀.” Lẹ́yìn náà ni ẹ ó ba àwọn ère yín jẹ́ àwọn tí ẹ fi fàdákà bò àti àwọn ère tí ẹ fi wúrà bò pẹ̀lú, ẹ ó sọ wọ́n nù bí aṣọ tí obìnrin fi ṣe nǹkan oṣù ẹ ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ kúrò níbí!”