AISAYA 30:15-22

AISAYA 30:15-22 YCE

Nítorí OLUWA Ọlọrun, Ẹni Mímọ́ Israẹli ní: “Bí ẹ bá yipada, tí ẹ sì farabalẹ̀, ẹ óo rí ìgbàlà; bí ẹ bá dákẹ́ jẹ́ẹ́ tí ẹ sì gbẹ́kẹ̀lé Ọlọrun, ẹ óo lágbára. Ṣugbọn ẹ kọ̀. Ẹ sọ pé ó tì o, ẹ̀yin óo gun ẹṣin sálọ ni. Nítorí náà sísá ni ẹ óo sálọ. Ẹ sọ pé ẹṣin tí ó lè sáré ni ẹ óo gùn. Nítorí náà àwọn tí yóo máa le yín, wọn óo lè sáré gan-an ni. Ẹgbẹrun ninu yín yóo sá fún ẹyọ ọ̀tá yín kan, gbogbo yín yóo sì sá fún ẹyọ eniyan marun-un títí tí àwọn tí yóo kú ninu yín yóo fi dàbí igi àsíá lórí òkè. Wọn óo dàbí àsíá ati àmì lórí òkè.” Nítorí náà OLUWA ń dúró dè yín, ó ti ṣetán láti ṣàánú yín. Yóo dìde, yóo sì ràn yín lọ́wọ́. Nítorí Ọlọrun Olódodo ni OLUWA. Ẹ̀yin ará Sioni tí ẹ̀ ń gbé Jerusalẹmu, ẹ kò ní sọkún mọ́. OLUWA yóo ṣàánú yín nígbà tí ẹ bá ké pè é, yóo sì da yín lóhùn nígbà tí ó bá gbọ́ igbe yín. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé OLUWA yóo jẹ́ kí ẹ ní ọpọlọpọ ìṣòro, yóo sì jẹ́ kí ẹ ṣe ọpọlọpọ wahala, sibẹsibẹ olùkọ́ yín kò ní farapamọ́ fun yín mọ́, ṣugbọn ẹ óo máa fi ojú yín rí i. Bí ẹ bá fẹ́ yapa sí apá ọ̀tún tabi apá òsì, ẹ óo máa gbọ́ ohùn kan lẹ́yìn yín tí yóo máa wí pé, “Ọ̀nà nìyí, ibí ni kí ẹ gbà.” Àwọn oriṣa tí ẹ yọ́ fadaka bò, ati àwọn ère tí ẹ yọ́ wúrà bò yóo di nǹkan èérí lójú yín. Ẹ óo kọ̀ wọ́n sílẹ̀ bí nǹkan aláìmọ́. Ẹ óo sì wí fún wọn pé, “Ẹ pòórá!”