Isa 30:1-15

Isa 30:1-15 Bibeli Mimọ (YBCV)

OLUWA wipe, egbé ni fun awọn ọlọ̀tẹ ọmọ, ti nwọn gbà ìmọ, ṣugbọn kì iṣe ati ọdọ mi; ti nwọn si mulẹ, ṣugbọn kì iṣe nipa ẹmi mi, ki nwọn ba le fi ẹ̀ṣẹ kún ẹ̀ṣẹ: Ti nwọn nrìn lọ si Egipti, ṣugbọn ti nwọn kò bere li ẹnu mi; lati mu ara wọn le nipa agbara Farao, ati lati gbẹkẹle ojiji Egipti! Nitorina ni agbara Farao yio ṣe jẹ itiju nyin, ati igbẹkẹle ojiji Egipti yio jẹ idãmu nyin. Nitori awọn olori rẹ̀ wá ni Soani, awọn ikọ̀ rẹ̀ de Hanesi. Oju awọn enia kan ti kò li ère fun wọn tilẹ tì wọn, ti kò le ṣe iranwọ, tabi anfani, bikoṣe itiju ati ẹ̀gan pẹlu. Ọ̀rọ-ìmọ niti awọn ẹranko gusu: sinu ilẹ wahala on àrodun, nibiti akọ ati abo kiniun ti wá, pamọlẹ ati ejò-ina ti nfò, nwọn o rù ọrọ̀ wọn li ejika awọn ọmọ kẹtẹkẹtẹ, ati iṣura wọn lori iké awọn ràkumi, sọdọ awọn enia kan ti kò li ère. Egipti yio ṣe iranwọ lasan, kò si ni lari: nitorina ni mo ṣe kigbe pè e ni, Rahabu ti o joko jẹ. Nisisiyi lọ, kọ ọ niwaju wọn si walã kan, si kọ ọ sinu iwe kan, ki o le jẹ fun igbà ti mbọ lai ati lailai: Pe, ọlọ̀tẹ enia ni awọn wọnyi, awọn ọmọ eké, awọn ọmọ ti kò fẹ igbọ́ ofin Oluwa: Ti nwọn wi fun awọn ariran pe, Máṣe riran; ati fun awọn wolĩ pe, Má sọtẹlẹ ohun ti o tọ́ fun wa, sọ nkan didùn fun wa, sọ asọtẹlẹ̀ itanjẹ. Kuro li ọna na, yẹ̀ kuro ni ipa na, mu ki Ẹni-Mimọ Israeli ki o dẹkun kuro niwaju wa. Nitorina bayi li Ẹni-Mimọ Israeli wi, Nitoriti ẹnyin gàn ọ̀rọ yi, ti ẹnyin si gbẹkẹle ininilara on ìyapa, ti ẹnyin si gbe ara nyin lé e; Nitorina ni aiṣedede yi yio ri si nyin bi odi yiya ti o mura ati ṣubu, ti o tiri sode lara ogiri giga, eyiti wiwó rẹ̀ de lojijì, lojukanna. Yio si fọ́ ọ bi fifọ́ ohun-èlo amọ̀ ti a fọ́ tútu; ti a kò dasi: tobẹ̃ ti a kì yio ri apãdi kan ninu ẹfọ́ rẹ̀ lati fi fọ̀n iná li oju ãro, tabi lati fi bù omi ninu ikũdu. Nitori bayi ni Oluwa Jehofah, Ẹni-Mimọ Israeli wi; Ninu pipada on sisimi li a o fi gbà nyin là; ninu didakẹjẹ ati gbigbẹkẹle li agbara nyin wà; ṣugbọn ẹnyin kò fẹ.

Isa 30:1-15 Yoruba Bible (YCE)

OLUWA ní: “Àwọn ọmọ aláìgbọràn gbé. Àwọn tí wọn ń dá àbá tí ó yàtọ̀ sí tèmi, tí wọn ń kó ẹgbẹ́ jọ, ṣugbọn tí kìí ṣe nípa ẹ̀mí mi; kí wọ́n lè máa dá ẹ̀ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀. Wọ́n múra, wọ́n gbọ̀nà Ijipti láì bèèrè ìmọ̀ràn lọ́dọ̀ mi. Wọ́n lọ sápamọ́ sí abẹ́ ààbò Farao, wọ́n lọ wá ààbò ní Ijipti. Nítorí náà, ààbò Farao yóo di ìtìjú fún wọn, ibi ìpamọ́ abẹ́ Ijipti yóo di ìrẹ̀sílẹ̀ fún wọn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn olórí wọn ti lọ sí Soani, tí àwọn ikọ̀ wọn sì ti dé Hanesi. Ojú yóo tì wọ́n, nítorí wọn ń wá ìrànlọ́wọ́ lọ sọ́dọ̀ àwọn tí kò lè ràn wọ́n lọ́wọ́. Wọn kò lè rí ìrànwọ́ tabi anfaani kankan níbẹ̀, bíkòṣe ìtìjú ati ẹ̀gàn.” Àsọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn ẹranko ilẹ̀ Nẹgẹbu nìyí: “Wọ́n di àwọn nǹkan ìní wọn sí ẹ̀yìn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, wọ́n sì di ìṣúra wọn sí ẹ̀yìn ràkúnmí. Wọ́n ń la ilẹ̀ ìṣòro ati wahala kọjá. Ilẹ̀ àwọn akọ kinniun ati abo kinniun, ilẹ̀ paramọ́lẹ̀ ati ejò amúbíiná tí ń fò. Wọ́n ń lọ sọ́dọ̀ àwọn eniyan tí kò lè ṣe wọ́n ní anfaani. Nítorí ìmúlẹ̀mófo ni ìrànwọ́ Ijipti. Nítorí náà ni mo ṣe pè é ní, ‘Rahabu tí ń jókòó lásán.’ ” Nisinsinyii lọ kọ ọ́ sílẹ̀ níwájú wọn, kí o sì kọ ọ́ sinu ìwé, kí ó lè wà títí di ẹ̀yìn ọ̀la, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí títí lae; nítorí aláìgbọràn eniyan ni wọ́n, Òpùrọ́ ọmọ tí kìí fẹ́ gbọ́ ìtọ́ni OLUWA. Wọ́n á máa sọ fún àwọn aríran pé, “Ẹ má ríran mọ.” Wọ́n á sì máa sọ fún àwọn wolii pé, “Ẹ má sọ àsọtẹ́lẹ̀ òtítọ́ fún wa mọ́, ọ̀rọ̀ dídùn ni kí ẹ máa sọ fún wa, kí ẹ sì máa sọ àsọtẹ́lẹ̀ ẹ̀tàn fún wa. Ẹ fi ojú ọ̀nà sílẹ̀, ẹ yà kúrò lójú ọ̀nà, ẹ má sọ nípa Ẹni Mímọ́ Israẹli fún wa mọ́.” Nítorí náà, Ẹni Mímọ́ Israẹli ní: “Nítorí pé ẹ kẹ́gàn ọ̀rọ̀ yìí, ẹ gbẹ́kẹ̀lé ìninilára ati ẹ̀tàn, ẹ sì gbára lé wọn, nítorí náà, ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹ̀ ń dá yìí; yóo dàbí ògiri gíga tí ó là, tí ó sì fẹ́ wó; lójijì ni yóo wó lulẹ̀ lẹ́ẹ̀kanṣoṣo. Wíwó rẹ̀ yóo dàbí ìgbà tí eniyan la ìkòkò mọ́lẹ̀, tí ó fọ́ yángá-yángá, tóbẹ́ẹ̀ tí eniyan kò rí àpáàdì kan mú jáde ninu rẹ̀, tí a lè fi fọn iná ninu ààrò, tabi èkúfọ́, tí a lè fi bu omi ninu odò.” Nítorí OLUWA Ọlọrun, Ẹni Mímọ́ Israẹli ní: “Bí ẹ bá yipada, tí ẹ sì farabalẹ̀, ẹ óo rí ìgbàlà; bí ẹ bá dákẹ́ jẹ́ẹ́ tí ẹ sì gbẹ́kẹ̀lé Ọlọrun, ẹ óo lágbára. Ṣugbọn ẹ kọ̀.

Isa 30:1-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

“Ègbé ni àwọn ọmọ fún orílẹ̀-èdè alágídí,” ni OLúWA wí, “Fún àwọn tí ó gbé ètò jáde tí kì í ṣe tèmi, tí wọ́n ń gbìmọ̀ pọ̀, ṣùgbọ́n kì í ṣe nípa Ẹ̀mí mi, tí wọ́n ń dá ẹ̀ṣẹ̀ lórí ẹ̀ṣẹ̀; tí wọ́n lọ sí Ejibiti láìṣe fún mi, tí ó ń wá ìrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ Farao fún ààbò, sí òjìji Ejibiti fún ibi ìsádi. Ṣùgbọ́n ààbò Farao yóò jásí ìtìjú fún un yín, òjìji Ejibiti yóò mú àbùkù bá a yín. Bí àwọn olórí rẹ tilẹ̀ wà ní Ṣoani, tí àwọn ikọ̀ wọn sì ti dé sí Hanisi, gbogbo wọn ni a ó dójútì, nítorí àwọn ènìyàn kan tí kò wúlò fún wọn, tí kò mú ìrànlọ́wọ́ tàbí àǹfààní wá, bí kò ṣe àbùkù àti ìdójúti ni.” Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ sí àwọn ẹranko tí ó wà ní gúúsù: Láàrín ilẹ̀ ìnira àti ìpọ́njú, ti kìnnìún àti abo kìnnìún ti paramọ́lẹ̀ àti ejò olóró, àwọn ikọ̀ náà kó ẹrù àti ọrọ̀ wọn lẹ́yìn àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àwọn ohun ìní wọn ní orí àwọn ìbákasẹ, sí orílẹ̀-èdè aláìlérè, sí Ejibiti tí ìrànlọ́wọ́ rẹ̀ kò wúlò rárá. Nítorí náà mo pè é ní Rahabu aláìlẹ́ṣẹ̀ nǹkan kan. Lọ nísinsin yìí, kí o sì kọ ọ́ sí ara wàláà fún wọn, tẹ̀ ẹ́ sí ara ìwé kíká, pé fún àwọn ọjọ́ tí ó ń bọ̀ kí ó sì lè jẹ́ ẹ̀rí ayérayé. Àwọn wọ̀nyí jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ ènìyàn àti ẹlẹ́tanu ọmọ, àwọn ọmọ tí wọn kò ṣetán láti tẹ́tí sí ìtọ́ni OLúWA. Wọ́n sọ fún àwọn aríran pé, “Ẹ má ṣe rí ìran mọ́!” Àti fún àwọn wòlíì, “Ẹ má ṣe fi ìran ohun tí ó tọ́ hàn wá mọ́! Ẹ sọ ohun tí ó tura fún wa, ẹ sàsọtẹ́lẹ̀ ẹ̀tàn. Ẹ fi ọ̀nà yìí sílẹ̀, ẹ kúrò ní ọ̀nà yìí ẹ dẹ́kun à ń dojú ìjà kọ wá pẹ̀lú Ẹni Mímọ́ Israẹli!” Nítorí náà, èyí ni ohun tí Ẹni Mímọ́ Israẹli wí: “Nítorí pé ẹ ti kọ ọ̀rọ̀ yìí sílẹ̀, ẹ gbára lé ìnilára kí ẹ sì gbẹ́kẹ̀lé ẹ̀tàn, ẹ̀ṣẹ̀ yìí yóò rí fún ọ gẹ́gẹ́ bí ògiri gíga, tí ó sán tí ó sì fì tí ó sì wó lójijì, àti ní ìṣẹ́jú kan. Yóò sì fọ́ ọ sí wẹ́wẹ́ bí àpáàdì tí a fọ́ pátápátá àti pé a kò ní rí ẹ̀rún kan nínú àfọ́kù rẹ̀, fún mímú èédú kúrò nínú ààrò tàbí gbígbọ́n omi jáde kúrò nínú àmù.” Èyí ni ohun tí OLúWA Olódùmarè, Ẹni Mímọ́ ti Israẹli wí: “Nínú ìrònúpìwàdà àti ìsinmi ni ìgbàlà rẹ wà, ní ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé ni agbára rẹ wà, ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò ní ọ̀kankan nínú wọn.