Isaiah 30:1-15

Isaiah 30:1-15 YCB

“Ègbé ni àwọn ọmọ fún orílẹ̀-èdè alágídí,” ni OLúWA wí, “Fún àwọn tí ó gbé ètò jáde tí kì í ṣe tèmi, tí wọ́n ń gbìmọ̀ pọ̀, ṣùgbọ́n kì í ṣe nípa Ẹ̀mí mi, tí wọ́n ń dá ẹ̀ṣẹ̀ lórí ẹ̀ṣẹ̀; tí wọ́n lọ sí Ejibiti láìṣe fún mi, tí ó ń wá ìrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ Farao fún ààbò, sí òjìji Ejibiti fún ibi ìsádi. Ṣùgbọ́n ààbò Farao yóò jásí ìtìjú fún un yín, òjìji Ejibiti yóò mú àbùkù bá a yín. Bí àwọn olórí rẹ tilẹ̀ wà ní Ṣoani, tí àwọn ikọ̀ wọn sì ti dé sí Hanisi, gbogbo wọn ni a ó dójútì, nítorí àwọn ènìyàn kan tí kò wúlò fún wọn, tí kò mú ìrànlọ́wọ́ tàbí àǹfààní wá, bí kò ṣe àbùkù àti ìdójúti ni.” Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ sí àwọn ẹranko tí ó wà ní gúúsù: Láàrín ilẹ̀ ìnira àti ìpọ́njú, ti kìnnìún àti abo kìnnìún ti paramọ́lẹ̀ àti ejò olóró, àwọn ikọ̀ náà kó ẹrù àti ọrọ̀ wọn lẹ́yìn àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àwọn ohun ìní wọn ní orí àwọn ìbákasẹ, sí orílẹ̀-èdè aláìlérè, sí Ejibiti tí ìrànlọ́wọ́ rẹ̀ kò wúlò rárá. Nítorí náà mo pè é ní Rahabu aláìlẹ́ṣẹ̀ nǹkan kan. Lọ nísinsin yìí, kí o sì kọ ọ́ sí ara wàláà fún wọn, tẹ̀ ẹ́ sí ara ìwé kíká, pé fún àwọn ọjọ́ tí ó ń bọ̀ kí ó sì lè jẹ́ ẹ̀rí ayérayé. Àwọn wọ̀nyí jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ ènìyàn àti ẹlẹ́tanu ọmọ, àwọn ọmọ tí wọn kò ṣetán láti tẹ́tí sí ìtọ́ni OLúWA. Wọ́n sọ fún àwọn aríran pé, “Ẹ má ṣe rí ìran mọ́!” Àti fún àwọn wòlíì, “Ẹ má ṣe fi ìran ohun tí ó tọ́ hàn wá mọ́! Ẹ sọ ohun tí ó tura fún wa, ẹ sàsọtẹ́lẹ̀ ẹ̀tàn. Ẹ fi ọ̀nà yìí sílẹ̀, ẹ kúrò ní ọ̀nà yìí ẹ dẹ́kun à ń dojú ìjà kọ wá pẹ̀lú Ẹni Mímọ́ Israẹli!” Nítorí náà, èyí ni ohun tí Ẹni Mímọ́ Israẹli wí: “Nítorí pé ẹ ti kọ ọ̀rọ̀ yìí sílẹ̀, ẹ gbára lé ìnilára kí ẹ sì gbẹ́kẹ̀lé ẹ̀tàn, ẹ̀ṣẹ̀ yìí yóò rí fún ọ gẹ́gẹ́ bí ògiri gíga, tí ó sán tí ó sì fì tí ó sì wó lójijì, àti ní ìṣẹ́jú kan. Yóò sì fọ́ ọ sí wẹ́wẹ́ bí àpáàdì tí a fọ́ pátápátá àti pé a kò ní rí ẹ̀rún kan nínú àfọ́kù rẹ̀, fún mímú èédú kúrò nínú ààrò tàbí gbígbọ́n omi jáde kúrò nínú àmù.” Èyí ni ohun tí OLúWA Olódùmarè, Ẹni Mímọ́ ti Israẹli wí: “Nínú ìrònúpìwàdà àti ìsinmi ni ìgbàlà rẹ wà, ní ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé ni agbára rẹ wà, ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò ní ọ̀kankan nínú wọn.