Isa 27:2-6
Isa 27:2-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
Li ọjọ na ẹ kọrin si i, Ajàra ọti-waini pipọ́n. Emi Oluwa li o ṣọ ọ: emi o bù omi wọ́n ọ nigbakugba: ki ẹnikẹni má ba bà a jẹ, emi o ṣọ ọ ti oru ti ọsan. Irunú kò si ninu mi: tani le doju pantiri ẹlẹgun ati ẹgun kọ mi li ogun jijà? emi iba là wọn kọja, emi iba fi wọn jona pọ̀ ṣọ̀kan. Tabi jẹ ki o di agbara mi mu, ki o ba le ba mi lajà; yio si ba mi lajà. Yio mu ki awọn ti o ti Jakobu wá ta gbòngbo: Israeli yio tanna yio si rudi, yio si fi eso kún oju gbogbo aiye.
Isa 27:2-6 Yoruba Bible (YCE)
Ní ọjọ́ náà, OLUWA yóo kọrin nípa ọgbà àjàrà dáradára kan pé, “Èmi OLUWA ni olùṣọ́ rẹ̀, lásìkò, lásìkò ni mò ń bomi rin ín; tọ̀sán-tòru ni mò ń ṣọ́ ọ kí ẹnìkan má baà bà á jẹ́. Inú kò bí mi, ǹ bá rí ẹ̀gún ati pàǹtí ninu rẹ̀, ǹ bá gbógun tì wọ́n, ǹ bá jó gbogbo wọn níná papọ̀. Ṣugbọn bí wọn bá fi mí ṣe ààbò, kí wọn wá kí á parí ìjà láàrin ara wa; kí wọn wá kí á parí ìjà láàrin ara wa.” Ní ọjọ́ iwájú Jakọbu yóo ta gbòǹgbò, Israẹli yóo tanná, yóo rúwé, yóo so, èso rẹ̀ yóo sì kún gbogbo ayé.
Isa 27:2-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní ọjọ́ náà “Kọrin nípa ọgbà àjàrà eléso kan. Èmi OLúWA ń bojútó o, Èmi ó bomirin ín láti ìgbàdégbà. Èmi ó ṣọ́ ọ tọ̀sán tòru kí ẹnikẹ́ni má ba à pa á lára. Inú kò bí mi. Bí ẹ̀gún àti ẹ̀wọ̀n bá dojú ìjà kọ mí! Èmi yóò dìde sí wọn ní ogun; Èmi yóò sì dáná sun gbogbo wọn. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, jẹ́ kí wọn wá sọ́dọ̀ mi fún ààbò; jẹ́ kí wọ́n wá àlàáfíà pẹ̀lú mi, bẹ́ẹ̀ ni, jẹ́ kí wọn wá àlàáfíà pẹ̀lú mi.” Ní ọjọ́ iwájú Jakọbu yóò ta gbòǹgbò, Israẹli yóò tanná yóò sì rudi èso rẹ̀ yóò sì kún gbogbo ayé.